Àwọn èèyàn kan fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀ ṣáájú ìdìbò 2023 láti gbé ìjọba fìdíhẹẹ́ kalẹ̀ -Tinubu

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Twitter/@officialABAT

Awọn kọlọransin eeyan kan n gbero lati da wahala silẹ lọna ati lee sun eto idibo apapọ ọdun 2023 lorilẹede Naijiria siwaju.

Oludije fun ipo aarẹ lorilẹede Naijiria labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu All Progressive congress, APC Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lo sọ bẹẹ lasiko to n polongo ibo fun ara rẹ ni ilu Ado Ekiti.

Bọla Tinubu ni ko si ba meji fun igbesẹ naa ju pe awọn eeyan naa n fẹ gbe eto iṣejọba fidihẹẹ kalẹ lẹyin ti saa iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari ba pari lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun ọdun 2023.

Tinubu ni ọgbọn ati da wahala silẹ ni ọwọngogo epo ati inira ọwọngogo owo Naira

Aarẹ Buhari ati Bọla Tinubu n juwọ si awọn ololufẹ ẹgbẹ oṣelu APC nibi ipade ipolongo ibo kan

Oríṣun àwòrán, Twitter/@officialABAT

“Wọn fẹ sun yin kan ogiri lati lee bẹrẹ ina wahala, ki wọn le pagidina eto idibo ki wọn si lee sun un siwaju, lati lee fi ọgbọn ẹwẹ gbe iṣejọba fidihẹẹ kalẹ, ọgbọn wọn niyii. Ṣugbọn eyi yoo lẹyin fun wọn nitori pe a ti gbọn.

Oludije fun ẹgbẹ oṣelu APC naa ko darukọ awọn to wa nidi igbimọ pọ to n fi ẹsun rẹ han faraye yii, amọṣa o rọ gbogbo awọn ọmọ Naijiria lati tako gbogbo igbimọpọ ti ko bofin mu ti awọn kọlọransi naa lee maa hun jọ.

Bakan naa lo rọ awọn oludibo lati rii daju pe wọn gba kaadi idibo wọn.

Ọrọ yii n waye lẹyin nnkan bii ọsẹ kan ti Tinubu yii kan naa ke gbajare sita pe awọn kan fẹ lo ọwọngogo epo ati ayipada owo Naira lati fi yi eto idibo apapọ ọdun 2023 lagbo da sina.

Tinubu atawọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC nibi ipolongo idibo ni Ado Ekiti

Oríṣun àwòrán, Twitter/@officialABAT

Tinubu ti kọkọ sọ lasiko to n ba awọn ololufẹ ẹgbẹ oṣelu APC sọrọ nilu Abẹokuta pe awọn agbẹyinbẹbọjẹ kan n gbero lati pagidina eto idibo apapọ ọdun 2023 lorilẹede Naijiria.

Gẹgẹbi o ṣe sọ, ọwọngogo epo ati ayipada naira eyi to ti mu ọpọ inira ba araalu bayii ko lee di awọn ololufẹ oun lati jade dibo.

“Bo wu yin, ẹ jẹ ki epo wọn, awọn lo mọ ibi ti wọn ko epo pamọ si. Ẹ ko epo pamọ, ẹ ko naira pamọ a maa dibo a dẹ maa wọle. Ẹ lọ yi awọ owo naira pada, ohun ti ẹ fẹ ko ṣẹlẹ ko ni ṣẹlẹ, A maa wọle.”