Mi ò bẹ̀rù àwọn àgbààgbà Árèwá kankan - El-Rufai

Oríṣun àwòrán, Others
Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Nasir El-Rufai ti ní òun kò bẹ̀rù àwọn àgbààgbà ẹkùn árèwá kankan nítorí gbogbo ipá òun ni òun máa sà láti ri dájú pé ipò Ààrẹ Nàìjíríà bọ́ sí ẹkùn gúúsù níbi ètò ìdìbò tó ń bọ̀.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tí El-Rufai ṣe pẹ̀lú BBC Hausa, ó ní gbogbo nǹkan tí àwọn kan n ṣe láti fi ri pé àwọn fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò náà ni kò ní wá sí ìmúṣẹ.
El-Rufai ní ó ti hàn dájú pé àwọn ti jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò náà àti pé àwọn kò ní kò àárẹ̀ ọkàn lórí ìgbìyànjú àwọn.
Ó ní àwọn máa fi hàn wọ́n wí pé àwọn ènìyàn ẹkùn árèwá kìí ṣe òpònú àti pé gbogbo nǹkan tó bá gbà ni àwọn máa fun láti ṣẹ́gun ogún tó wà níwájú àwọn.
Ó tẹ̀síwájú pé tí àwọn bá ń sọ̀rọ̀ àwọn àgbààgbà ẹkùn árèwá, ọ̀kan lára wọn ni òun náà jẹ́ nítorí òun kìí ṣe ọmọdé mọ́ nídìí òṣèlú.
Gomìnà Kaduna náà ní àwọn gómìnà gan ni adarí ìpínlẹ̀ àwọn nítorí náà àwọn gan náà ni àgbààgbà ìpínlẹ̀ àwọn.
"Lẹ́yìn tí a bọ́ sípò tán, àwọn kan gba ìjọba mọ́ wa lọ́wọ́ láti máa lò ó fún ara, tí wọ́n sì fi ń ṣe àkóbá fún ẹgbẹ́, tí wọ́n sì ń tan Ààrẹ."
Bákan náà ló pe àwọn tó wà nídìí àyípadà owó Nàìjíríà níjà láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé kìí ṣe nítorí láti lè jẹ́ kí olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú APC fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò ni wọ́n ṣe gbé ìgbésẹ̀ náà kalẹ̀.
"Gbogbo àwọn tó wà nídìí ìgbésẹ̀ yìí ni kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ wa, àwa ni a jà láti gbé ẹgbẹ́ APC kalẹ̀, ta sì wọlé ìbò láti gba ìjọba."
"Lẹ́yìn tí a bọ́ sípò tán, àwọn kan gba ìjọba mọ́ wa lọ́wọ́ láti máa lò ó fún ara, tí wọ́n sì fi ń ṣe àkóbá fún ẹgbẹ́, tí wọ́n sì ń tan Ààrẹ."
El-Rufai fi kun pé tí kìí bá ṣe ọgbọ́n láti jẹ́ kí ẹgbẹ́ àwọn fìdí rẹmi, ó ṣe jẹ́ àsìkò yìí láti ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn, tí ètò ìdìbò ń bọ̀ lọ́nà ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rántí láti mú àyípadà bá owó.
Ó ní ọ̀wọ́n gógó epo bẹntiróòlù náà jẹ́ ohun tí àwọn kan n ṣe láti mú ayé nira fún àwọn ènìyàn Nàìjíríà kí wọ́n má bá a dìbò fún APC.
Bákan náà ló tún ṣe àfọ̀mọ́ rẹ̀ pé lòdì sí ìròyìn tí àwọn kan ń gbé kiri pé igbákejì Ààrẹ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo ni òun ń bá wí.
Ó tún sọ wí pé irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni pé olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP ìyẹn Atiku Abubakar ni Ààrẹ Muhammadu Buhari ń ṣe àtìlẹyìn fún nítorí Ààrẹ kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ rárá.
El-Rufai ní nígbà tí àwọn bá wà ní ọ́fíìsì Ààrẹ láti bá a sọ̀rọ̀, ní kété tí àwọn bá ti kúrò ní ọ́fíìsì rẹ̀ ni àwọn mìíràn yóò ti lọ kó nǹkan sí Ààrẹ lórí.
Ó ní gbogbo àwọn ènìyàn yìí ni òun mọ́ àti pé tí àsìkò bá tó gbogbo wọn ni òun máa dárúkọ.















