Ọwọ́ tẹ pásítọ̀ tó gbé obituary ara rẹ̀ jáde nitori gbèṣè mílíọ́nù mẹ́ta náírà tó jẹ

Oríṣun àwòrán, Others
Aṣiri pasitọ kan ti tu ni ilu Ondo lẹyin to fi iroyin oku ara rẹ lede nitori gbese to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ile ijọsin rẹ.
Pasitọ Paul Oyewole lo n koju ẹsun irọ pe oun ti ku niwaju ileẹjọ magisreti ni ilu Ondo.
Ileẹjọ ni Oyewọle fi iroyin iku ara rẹ sita lori ẹrọ ayelujara lẹyin to fi bank alert ayederu ranṣẹ si ẹni to jẹ ni gbese, iyen Boyede Emmanuel.
Awọn ẹsun ti wọn fi kan pasitọ Oyewole
Oyewọle ni wọn fi ẹsun alọnilọwọgba lati gba owo lẹyin to ya miliọnu mẹta naira lọwọni oun a da pada laaarin ọjọ meje.
Ẹsun miran ti wọn fi kan an ni pe o fi ayederu iroyin lede pe oun ti ku to si wa laaye lori Whatsapp.
Lẹyin naa ni Oyewole lọ dunkoko mọ ẹni to jẹ ni owo pe oun yoo bọ ara oun si iwowo to si ṣe bẹẹ niwaju ile ẹni to jẹ ni gbese
Oṣu Kọkanla, ọdun 2021 si oṣu Karun un , ọdun 2022 lo hu iwa aitọ yii.
Amọ lasiko igbẹjọ ni Pasitọ ni oun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun.
Adajọ ti sun igbẹjọ siwaju di Ọjọ Kẹtala, Oṣu Keji, ọdun 2023.
Bakan naa lo gba beeli rẹ pẹlu miliọnu kan naira ati oniduro meji pẹlu iye owo naa.












