FBI tú ilé Ààrẹ Joe Biden wò fún àwọn ìwé ‘classified documents’ ìjọba

Aarẹ Joe Biden

Awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ FBI lorilẹede Amẹrika ti ya bo ile aarẹ orilẹede naa, Joe Biden to wa ni Rehoboth ni Delaware gẹgẹ bi ara iwadii ti wọn n ṣe lori awọn iwe ijọba kan.

Ninu atẹjade kan ti agbẹjọro rẹ fi sita, aarẹ Biden funrarẹ mọ si igbesẹ ati tu ile rẹ wo yẹbẹyẹbẹ

gẹgẹbi ara eto iwadii si ọrọ nla kan to nii ṣe pẹlu awọn iwadii lori awọn iwe “majẹ keti keji gbọ” kan ti oyinbo n pe ni ‘classified documents’

Ajọ agbofinro FBI ko tii sọrọ lori ọrọ naa.

Ajumọfẹnukosi ni igbesẹ naa laarin aarẹ ati ajọ FBI nitori naa ko nilo iwe aṣẹ ofin lati yẹ ile naa wo.

Amofin Bob Bauer to jẹ agbẹjọro fun Aarẹ Joe Biden ti ilẹ Amẹrika sọ pe awọn agbofinro FBI tu ile na yẹbẹyẹbẹ

lai fi to Aarẹ ṣaaju pe akoko bayii lawọn n bọ nitori ki awo ọrọ ma baa lu si ọwọ aarẹ naa.

Ayẹwo yii jẹ ọkan lara igbesẹ iwadii to n waye kaakiri awọn ibudo kaaakiri lẹyin ti wọn ri awọn iwe ijọba kan ti ko yẹ ko lu sita ni ibudo Penn Biden Center, ni ilu Washinghton DC loṣu kọkanla ọdun to kọja.

Ọwọ awọn agbofinro FBI tẹ awọn iwe ijọba miran lawọn ile aarẹ Biden miran to wa ni Wilmington, Delaware lasiko ti wọn fi yẹ ibẹ wo loṣu kejila ọdun to kọja ati oṣu kini ọdun yii.

Ko ti han si ita iye awọn iwe yii ti wọn ri nibẹ bi o tilẹ jẹ wi pe iye awọn iwe ijọba ti wọn ri loṣu kini nikan le ni mejila.

Aarẹ Biden ni ohun gbogbo to yẹ ni ṣiṣe lawọn oṣiṣẹ oun ṣe nipa pipe akiyesi awọn agbofinro ni kiakia, wọn si n fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro lori iwadii naa.

FBI ka iwe ijọba "Classified documents" mọ ile Aarẹ Trump ati igbakeji rẹ Mike Pence pẹlu

Aarẹ Biden ni ile rẹ ni Dalware

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣaaju asiko yii, awuyewuye riri awọn iwe ijọba ti ko yẹ ko lu si igboro nibi ti ko yẹ lo n kun aarẹ ana, Donald Trump ati igbakeji rẹ Mike Pence pẹlu.

Ile Igbakeji aarẹ Pence to wa ni Carmel ni Indiana ni wọn ti ri awọn iwe ijọba kan ti wọn kọ akọle “Classified” si lara gẹ bi iwe lẹta kan ti agbẹjọro fun Pence kọ ranṣẹ ibudo iko iwe iranti si.

Nigba ti awọn agbofinro FBI tu ile aarẹ Trump to wa ni Mar-a-Lago Estate ni Florida wo loṣu kẹjọ, ọdun 2022,

oniruru apoti ati iwe ijọba to to ẹgbẹrun mọkanla ni wọn ri ninu eyi ti ọgọrun ninu wọn ti jẹ iwe ijọba ti ojukoju ko gbọdọ ri.