Tinubu kòò le dí èmi lọ́wọ́ láti jáwé olúborí ìbò Ààrẹ Nàìjíríà- Atiku

Aworan
Àkọlé fídíò, Àmọ́ ni Tinubu kìí ṣe ẹran tó le dí èmi lọ́wọ́ láti jáwé olúborí ìbò Ààrẹ Nàìjíríà- Atiku

Olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, Alhaji Atiku Abubakar ti ní òun kò bẹ̀rù olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu.

Atiku nígbà tó ń kópa nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú BBC Hausa ní òun kò bẹ̀rù láti kojú olóṣèlú kankan ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun mọ̀ pé Tinubu kìí ṣe ẹran rírọ̀ síbẹ̀ òun gbà pé kò lè dí òun lọ́wọ́ láti jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà.

Atiku Abubakar tún sọ wí pé àwọn olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú NNPP àti Labour Party kò lè ní ipa lórí ìbò òun àti pé àwọn ti ń ní àjọṣepọ̀ àti àjọ sọ láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn.

Atiku Abubakar ati Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Collage

Àwọn nǹkan márùn-ún tí Atiku máa gbájúmọ́

Olùdíje sípò Ààrẹ náà ní bí òun bá rí ìbò àwọn ọmọ Nàìjíríà, tí òun wọlé ipò Ààrẹ Nàìjíríà, àwọn nǹkan márùn-ún ni òun máa gbájúmọ́ láti ṣe iṣẹ́ lé lórí.

Àwọn nǹkan náà ni ètò ààbò, ìṣọ̀kan Nàìjíríà, ètò ọrọ̀ ajé, ètò ẹ̀kọ́ àti ètò ìlera.

Ètò ààbò

Nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè lórí bí ètò ààbò yóò ṣe padà sípò ní orílẹ̀ èdè yìí pàápàá lórí àwọn tó ń jí ènìyàn gbé, Atiku ní òun máa gba àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò si.

Bákan náà ló ní gbogbo ìgbà ni ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yóò máa wáyé fún àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò àti ìpèsè àwọn ohun ìjà ìgbàlódé fún wọn.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní òun máa gba ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láàyè pẹ̀lú ìlérí pé àwọn gómìnà kò ní máa lò wọ́n fún àwọn ìwà kò tọ́ ní àwùjọ.

Ètò ọrọ̀ ajé

Atiku Abubakar ní òun máa mú àtúnjí bá ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà nípa pípe àwọn olùdókoòwò wá sí Nàìjíríà láti ilẹ̀ òkèrè láti wá dókóowò ní orílẹ̀ èdè yìí kí wọ́n le mú ìdàgbàsókè bá Nàìjíríà.

Bákan náà ló ní àwọn máa jíròrò pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ Nàìjíríà lówó láti ní àjọsọ lórí bí wọ́n ṣe máa dá owó náà padà fún Nàìjíríà.

Ètò ẹ̀kọ́

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ọ̀nà tí yóò gbà mú ìgbéga ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà, igbákejì Ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí náà ní mílíọ̀nù méjìlá àwọn ọmọdé ni kò máa lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà.

Ó ní ìwádìí fi hàn pé ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀ àti ìjọba ìbílẹ̀ ni kò máa lo owó tó ń wá láti ọ̀dọ̀ ìjọba àpapọ̀ sí ọ̀nà tó tọ́ láti fi mú àgbéga bá ètò ẹ̀kọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀.

Lórí ọ̀rọ̀ ASUU, Atiku ní òun máa ní àjọsọ pẹ̀lú àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì pẹ̀lú ìrírí òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ní ilé ẹ̀kọ́ gíga láti bí ogún ọdún sẹ́yìn láti mọ ọ̀nà tí wọn yóò gbà láti fi mú ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà gòkè àgbà.

Ó ní ìjọba yóò máa pèsè ẹ̀yáwó fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti fi máa san owó ilé ẹ̀kọ́ èyí tí wọ́n á máa dá padà lẹ́yìn tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́yìn ètò ẹ̀kọ́ wọn.

Ìlera

Atiku ní nígbà tí àwọn gbapò ìjọba lọ́dún 1999, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kojú ìṣòro irú èyí tí wọ́n ń kojú lọ́wọ́ yìí ìyẹn bí àwọn dókítà ṣe ń fi orílẹ̀ èdè yìí sílẹ̀ láti lọ ṣiṣẹ́ nílẹ̀ òkèrè.

Ó ní nǹkan tí àwọn ṣe nígbà náà ni láti ṣàgbéyẹ̀wò owó oṣù àwọn dókítà náà àti ọ̀nà tí àwọn fi lè mú iṣẹ́ wọn rọrùn si.

Ó ní ìrírí òun nígbà náà ni òun máa ṣàmúlò tí òun bá di Ààrẹ láti le fi pe gbogbo àwọn dókítà tó ti sá kúrò ní Nàìjíríà padà sílé.

Àwọn gómìnà G-5 kò lè dí mi lọ́wọ́

Lórí ọ̀rọ̀ àwọn gómìnà márùn-ún tó ń fapá jánú lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP ìyẹn àwọn gómìnà G-5, Atiku ní àwọn ń báwọn jíròrò láti fòpin sí aáwọ̀ tó wà láàárín àwọn.

Ó ní òun mọ̀ wí pé àwọn gómìnà ọ̀hún kò lè dí jíjáwé olúborí òun lọ́wọ́ nítorí àwọn kò lè sọ wí pé ibì kan báyìí ni wọ́n dúró.

Bákan náà ló ní ètò ìdìbò tó ń bọ̀ yìí kìí ṣe èyí tí àwọn gómìnà ti le máa là lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́.

Bí mi kò bá fi lè jáwé olúborí, ohun tí màá ṣe nìyí - Atiku Abubakar

Atiku

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Lóòtọ́ ni mo ń jà fún kí a máà tó ipò ààrẹ tẹ́lẹ̀ àmọ́... - Atiku

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ko si ẹgbẹ́ òṣèlú míì lẹ́yìn PDP ati APC'

Ṣáájú idibo ọdun 2005 ni Alhaji Atiku ti máa n pe fun kí agbara iṣejoba Naijiria lọ kari awọn ẹ̀yà Naijiria amọ nibayii òun gaan lo n gbero láti gba ijọba lọwọ ara iha Ariwa mii bii tirẹ. Atọkun BBC bii léèrè nípa èyí.

Esi to fi dahun ni pé: "oju ẹgbẹ́ kan la fi n wo ó".

Ó ṣàlàyé pe ẹgbẹ́ òṣèlú meji péré ni Naijiria ni, APC àti PDP, o ni ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ko tii du ipo Ààrẹ ri ati pe ẹgbẹ́ ọhun ko ni ààtò.

"Awọn ọmọ Naijiria lo ọpọlọ tiinrin fi ronú ti wọn si lọ gbogbo ẹ papọ, ni wọn ṣe ni iha Ariwa ni agbara Ààrẹ fì si ju latigba taa ti bẹrẹ ìjọba awaarawa. Èrò òdì gbáà lè lèyí".

Lori ìlera rẹ, Atiku Abubakar fesi pe kokoko lara ọta le o si ni niwọn ìgbà ti ohun èlò ìlera ti oun nilo ba ti wa lorileede Naijiria, òun ko ni tẹ ọkọ baalu leti lọ orileede mii fún ìlera amọ bi ko ba si, òun yóò fo lọ oke okun o.

Oludije ipo Ààrẹ ni ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party(PDP) ni oun ti ṣe tán lati di Ààrẹ Naijiria fun igba pipẹ nitoripe oun ni oye ìṣòro to n koju orileede yii.

O ni oun n p'eto lati fi orílẹ̀èdè to dara silẹ fun awọn ọmọ Naijiria àtàwọn ọmọ oun.

Ninu iforowanilẹnu ti Atiku ṣe pẹlu BBC lo ti jẹ ko di mimọ pe kii ṣe pe oun n mú un ni dandan lati di Ààrẹ lodi si oun ti awọn eeyan n ro.

Ó ni oun yoo gba kadara oun lai fi ti ti abajade idibo ọjọ kẹ́ẹdọgbọn oṣù Keji.

"Mo ni ọmọ pupọ, mo si tọ wọn dagba daadaa, wọn lọ lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ to dara ju ni Naijiria ati lẹyin odi.

Gẹgẹ bi mo ṣe máa n sọ fun wọn ni gbogbo igba, emi ti gbe aye temi, bi mo ba wa ko wọn pada wale, iru orileede wo ni mo fẹ́ fi silẹ fun wọn.

"Kii ṣe fawọn ọmọ temi nikan ṣùgbọ́n fun iran ọjọ iwaju ".

Atiku ni ero yii to gba ọkan oun kan naa lo wa lọkan gbogbo obi ni Naijiria, "iru orileede wo wa ni mo fẹ́ fi silẹ fun awọn ọmọ?".

O ni eyi wa lara idi ti oun fi pinu lati gbe apoti ibo fun ipo Ààrẹ Naijiria.

Bi oludije mii ba na ọ mọ́lẹ̀, ki ni wàá ṣe?

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Nigba ti wọn bere ọrọ yii lọwọ Atiku, o ni "maa gba a, kadara mi ni, maa fi ọkan kan gba a bẹẹ.

Emi kọ ni ẹni àkọ́kọ́ ti ko jawe olubori, emi si kọ ni yoo jẹ ẹni ìkẹyìn", o fi kun un.