Gbas-gbos bẹ̀rẹ̀ láàrín APC àti PDP lórí bí àwọn kan ṣe sọ ọkọ̀ Ààrẹ lókùta ní Kano

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP ti bẹrẹ si n sọko ọrọ si ara wọn bayii lẹyin ti Aarẹ Muhammadu Buhari ṣabẹwo siluu Kano.

Eyii lo n waye latari awọn fidio ati aworan to gba ori ayelujara, ninu eyii ti iroyin ti sọ pe awọn araalu n sọko si baalu to gbe Aarẹ Muhammadu Buhari lọ si ipinlẹ naa.

Amọ ẹgbẹ oṣelu APC ti kọ iroyin ọhun, wọn ni ẹgbẹ oṣelu PDP lo wa nidi iṣẹlẹ naa ati bi iroyin nipa rẹ ṣe gbode.

Wọn ni ẹgbẹ oṣelu PDP lo n pin iroyin ẹlẹjẹ naa kiri lati ba orukọ Aarẹ loju awọn araalu.

Ṣaaju ni agbẹnusọ ikọ iponmlogo ẹgbẹ oṣelu PDP, Dino Melaye ti kọkọ sọ ninu fidio kan pe awọn ọdọ kọlu ikọ Aarẹ Muhammadu Buhari lasiko abẹwo rẹ si Kano.

Bẹẹ naa ni PDP tun sọ ninu atẹjade kan pe awọn bu ẹnu atẹ lu ikọlu naa.

Akọwe agba PDP, Debo Ologunagba sọ pe ikọlu ọhun ko ṣẹyin akitiyan lati yẹpẹrẹ ipo Aarẹ ati lati da omi alaafia Naijiria ru ṣaaju ibo oṣu Keji.

Atẹjade naa fi kun pe “Ohun to jẹ iyalẹnu ni bi oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC ṣe n gbiyanju lati tabuku Aarẹ Buhari lasiko to n ba iṣẹ rẹ lọ.”

Ki ni APC sọ?

Ẹwẹ, nigba ti APC yoo fesi pada lati ẹnu Bayo Onanuga, to jẹ adari awọn agbẹnusọ ikọ ipolongo Bola Tinubu, o ni PDP n gbiyanuu lati dojuti Aarẹ ni.

Atẹjade ọhun ni “Gẹgẹ bii PDP ṣe n gbe iroyin ẹlẹjẹ nipa oludije sipo Aarẹ APC lati da wahala silẹ, a gbagbọ pe PDP mọọmọ gbimọ lati dojuti Aarẹ Buhari lasiko abẹwo rẹ si ipinlẹ Kano lọna ati da ẹbi iṣẹlẹ naa le gomina Abdulahi Ganduje lori.”

Lẹyin naa ni wọn ni ki awọn araalu maṣẹ maa naani ohunkohun to ba n jade lati ọdọ PDP.