Ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìyá àgbà, ẹni ọdún 65 tí wọ́n fi ipá bá lòpọ̀

Oríṣun àwòrán, Twitter
Awọn adigunjale kan ni wọn fi ẹsun kan pe wọn sẹkọlu si ile iya agbalagba kan ninu ile rẹ, ti wọn si fi ipa ba lopọ lẹyin ti wọn ji nkan ini rẹ.
Ilu Kaduna ni agbegbe Millenium City ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Iya agba naa ni ọmọ rẹ se apejuwe gẹgẹ bi oṣiṣẹ fẹyinti ni ipinlẹ Kadunna naa.
Ọmọ rẹ ni sadede ni iya agba fi atẹjiṣẹ pajawiri ranṣẹ si oun pe awọn kan n gbiyanju lati wọ inu ile rẹ ni nkan bi aago mẹjọ alẹ ni Ọjọ Isinmi.
''Mo ke gbajare si Ọlọpaa lati doola ẹmi iya mi ti awọn adigunjale ṣekọlu si''
Ọmọ iya agba ti ko si nile lasiko ti iṣẹlẹ naa waye lo ke gbajare lori Twitter pe ki ileeṣẹ ọlọpaa ni Nigeria jọwọ doola ẹmi iya ohun.
‘’Iya mi ṣẹṣẹ pe mi tan ni isinyii ni pe awọn kan n tiraka lati wọ inu ile rẹ’’
‘’Agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye ni KekeB, to sunmọ agbegbe millenium City ni Kaduna. Maami o gbe ipe rẹ mọ amọ ko si ọlọpaa kankan.
‘’Ẹyin eniyan ẹ ba mi kesi ẹni ti yoo le ran mi lọwọ lati da abo bo iya mi lọwọ ewu’’.
Amọ arakunrin naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ko dahun si igbe rẹ, ti awọn ole si wọle ja iya oun ni ole ara ati ẹru rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
‘’Iya mi ni awọn adigunjale ọhun fi ipa ba oun lopọ lọpọ igba’’

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ninu ọrọ rẹ, ọmọ iya agbalagba naa ni lẹyin ti oun ke gbajare lori Twitter ti ko si ẹni to da oun lohun, lẹyin naa lo wa tun fi atẹjade miran jade wi pe wọn ti fi ipa ba iya oun lọpọ igba lasiko ikọlu naa.
‘’Nigba ti ẹyin n sun daradara lalẹ, mi o mọ bi awọn eniyan ṣe buru jai bayii, ti wọn si jawọ ile onile, wọn ji awọn ohun ini rẹ, wọn si tun fi ipa ba lopọ.
Iru awọn ọbayejẹ wo lo n fi ipa ba ẹni ọdun marundinlaadọrin lọpọ? Gbogbo awọn to ṣe iṣẹ ibi yii ko ni mọ isinmi.’’
Nibayii, iya agba ọhun wa ni ile iwosan nibi to ti n gba itọju.
Ninu ọkọ rẹ SP Mohammed to jẹ agbẹnusọ fun kọmisọnna ọlọpaa ni Kaduna ni lootọ ni iṣẹlẹ naa waye, ti wọn si ran awọn eniyan lọ sibẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ṣi n ṣewadii iṣẹlẹ naa lọwọ ti awọn yoo si fi idi otitọ mulẹ ni aipẹ.
Amọ wọn ni kiakia ti wọn ta wọn lolobo nipa iṣẹlẹ obinrin naa ni awọn oṣiṣẹ ẹsọ alaabo ti tuyaya lọ si ibẹ.’’












