Ọ̀gá àgbà CBN yọjú sílé aṣòfin lórí owó naira tuntun, ohun tó bá bọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, @yabaleftonline
Gomina banki apapọ Naijiria, CBN, Godwin Emefiele ti sọ pe awọn ile ifowopamọ yoo tẹsiwaju lati maa gba owo naira atijọ lẹyin gbedeke iye ọjọ ti wọn kede ṣaaju.
Ṣaaju ni CBN ti kọkọ ṣa afikun gbedeke ti awọn araalu gbọdọ lọ paarọ owo atijọ si tuntun, lẹyin ti awọn araalu fariga latari iṣoro ti wọn dojukọ lati paarọ owo naa.
Amọ lasiko to yọju siwaju ile aṣojuṣofin lori ọrọ naa, gomina banki ọhun sọ pe awọn yoo ṣi maa gba owo atijọ ti akoko ti wọn kede lati paarọ owo ọhun ba ti kọja.
O ni bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan ko le maa na owo naa lawujọ mọ, CBN yoo ṣi maa gba owo naa.
O ṣalaye fun awọ aṣofin naa pe oun tẹkọ leti lọ si oke okun ni ko jẹ ki oun kọkọ yọju si wọn lasiko ti wọn kọkọ kọwe pe oun.
Lẹyin naa lo rọ awọn aṣofin naa ki wọn gba ofin naira tuntun ọhun laaye lati mulẹ.
Nigba to n sọrọ lori eredi ti wọn ṣe tẹ owo tuntun, o ni ohun ti CBN n ṣe wa ni ibamu pẹlu bi aye ṣe n yi.
O fi kun pe iye owo to wa nigboro ko si ni ikawọ banki naa.
Emefiele tun ṣalaye pe wọn ko fẹ ki oloriojori maa gba owo to pọ ju lo jẹ ki wọn fi gbedeke le iye owo ti eeyan le gba lori ẹrọ ATM lojumọ kan.
O fi kun pe awọn mọ pe ilana tuntun lori gbedeke iye ti eeyan le gba lojumọ yoo pa awọn eeyan kan lara, amọ wọn ṣe ofin naa pẹlu erongba rere fun awọn araalu.
Ati ilana tuntun ọhun pe yoo ran ijọba lọwọ lati koju iṣoro ato abo.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
CBN kò gbé ìgbésẹ̀ bí o ti yẹ lórí pàṣípààrọ̀ owó nàira- Ẹgbẹ́ Oṣèlú SDP àti YPP

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn oludije sipo ipo Aarẹ labẹ ẹgbẹ oselu Young Progressives Party (YPP), Malik Ado-Ibrahim ati akẹgbẹ rẹ lati ẹgbẹ Social Democratic Party, Adewole Adebayo ti fohun sita.
Wọn ti bu ẹnu atẹ lu banki apapọ orilẹ-ede yii Central Bank of Nigeria (CBN) ati ijoba apapo lori eto atunto naira.
Nigba ti wọn n sọrọ lori atunto ati igbe jade owo tuntun ti banki apapọ ṣẹ gbẹ jade,
wọn ni iyalẹnu lo jẹ nitori Aarẹ Muhammadu Buhari ati Gomina CBN, Godwin Emefiele kuna lati jẹ ki Minisita fun Isuna ati ọrọ aje Orilẹ-ede yii , Zainab Ahmed mo nipa awọn ilana ati igbesẹ ti owo naira tuntun gba jade.
Wọn ni lati igba ti ọrọ owo tuntun ti bere o dabi ẹni pe adehun laarin gomina banki apapọ ati aarẹ Muhammadu Buhari nikan ni o mo n nipa igbesẹ naa, Nibo ni minisita naa wa.
Malik Ado-Ibrahim ṣe apejuwe eto ati ilana owo naira tuntun gẹgẹ bi imọran ti o.
Sugbọn ijọba apapọ ati banki apapọ ko mojuto bii owo naa yoo ṣe tan kalẹ,
oludije SDP sọ pe ko si eto ijọba kankan ti yoo mu ki paṣipaarọ owo naira tuntun ati ti atijọ ṣe dara dara.
Adebayo ni Gomina banki apapọ kuna lati jẹ ki igbimọ to ṣamojuto banki apapọ ṣe iṣẹ rẹ ti o si gbe gbogbo awọn aba rẹ to Aarẹ Buhari lọọ lai gba aṣẹ lọwọ awọn igbimọ baanki naa.
Oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu SDP fi kun un pe banki apapọ fẹẹ dabi igun ẹgbẹ oṣelu fun ijọba eyi ti ko ye dun idagbasoke orilẹede yii ati ipo gomina banki apapọ.















