Sunday Igboho àti Simon Ekpa késí àjọ àgbáyé láti dẹ́kun ìjọba Naijiria látàrí ikú àwọn ajìjàgbara

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, @simon_ekpa

Ẹgbẹ ajijagbara ilẹ Yoruba ati ilẹ Igbo ti ke si ajọ agbaye lati fa ijọba Naijiira leti ko jawọ ninu fifi ẹmi araalu ṣofo.

Ninu atẹjade kan ti ajijagbara Yoruba Nation, Sunday Adeyemo Igboho ati ajijagbara Biafra, Simon Ekpa, fi ṣọwọ so awọn akọroyin ni wọn ti fi ọrọ naa lede.

Gẹgẹ bii ohun ti awọn mejeji sọ ninu atẹjade ọhun, ogunlọgọ eeyan ni ileeṣẹ ọmọ Naijiria ti ṣekupa latari pe wọn n pe fun ominira ilẹ wọn.

“Eeyan 29,000 ni ijọba ti pa nilẹ Yoruba”

Igboho ati Ekpa sọ pe ijọba n pa awọn eeyan ti ko ṣẹ nitori pe wọn n fẹ ominira ilẹ wọn.

Atẹjade ọhun ni “A fẹ sọ niwaju gbogbo agbaye pe ojojumọ ni ijọba Naijiria n ṣekupa awọn ọmọ ilẹ Yoruba ati Biafra.”

“Ko din ni ẹgbẹrun mọkandinlọgbọn alaiṣẹ ọmọ Yoruba ti wọn ti ṣekupa, nigba ti nnkan bii miliọnu kan abọ o le eeyan ti salọ silẹ Benin Republic.”

“Ni Biafra, nnkan bii ẹgbẹrun marundinlaadọta eeyan ni wọn ti pa, ẹgbẹrun mẹwaa di awati, ẹgbẹrun meje wa ni atimọle lọna aitọ nigba ti miliọnu mẹta di alairilegbe.”

Wọn fi kun pe awọn ko ni gba ki ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria maa pa awọn eeyan wọn ni ipakupa lai nidi mọ.

Igboho ati Ekpa tun ke si awọn orilẹ-ede bii Amẹrika, UK, France, Germany, Russia, China atawọn orilẹ-ede mii to lẹnu lagbaye lati da si ọrọ naa ki wọn si dẹkun ijọba Naijiria.

Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, ẹtọ araalu ni lati pe fun iyapa, ko si yẹ ki awọn ọmọ ogun to yẹ ko daabo bo awọn maa pa awọn ni ipakupa.

“A fẹ ki ajọ agbaye da si ọrọ Naiiria bo ṣe da si ọrọ Sudan atawọn ilẹ mii”

Wọn sọ siwaju si pe ohun to dara ni bi ajọ agbaye ṣe da si ifẹmiṣofo to waye ṣaaju ni orilẹ-ede Sudan ati orilẹ-ede mii.

Atẹjade naa ni “Ohun to daa ni ajọ agbaye lasiko ti wọn da si ọrọ Sudan.”

“Irufẹ ohun to waye ni Sudan ati Yugoslavia naa ti ṣelẹ ni Naijiria bayii, ko si yẹ ajọ agbaye dakẹ.”

Wọn pari atẹjade naa pe ọrọ naa le buru ju bo ṣe wa lọ ti ajọ agbaye ko ba tete ke pe ijọba Naijriia ko ti ọwọ ọmọ rẹ bọ aṣọ.