Ìjọba ti apá kan Lagos- Ibadan expressway fún ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá

Frederic Oladeinde

Oríṣun àwòrán, Others

Ǹjẹ́ ẹtì gbò nipa àtúnṣe òpópónà Eko sì Ibadan yóò gbá ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá-Ìjọba Àpapọ̀.

Ijọba ipinlẹ Eko ti sọ pe awọn yoo dari irin ọkọ lati Tollgate atijọ si apa kan Berger ni opopona ilu eko si Ibadan fun ọsẹ mẹwaa.

Igbesẹ naa yoo bẹrẹ loni ti yoo si pari lẹyin ọṣẹ mewaa.

Dokita Frederic Ọladeinde, Komiṣọnna fun eto irinna nipinlẹ Eko, lo fi iroyin naa lede ninu atẹjade ti o ṣe.

Atẹjade naa fi han pe eto lati dari irinajo awọn ọkọ irina ni ko sẹyin atunṣe ti ijọba apapọ n se lọwọlọwọ loju ọna naa.

Komisonna fun eto irina nipinlẹ Eko ni iṣẹ atunṣe opopona Eko si Ibadan yoo ma ṣẹlẹ ni ipele ti won o si fi aaye silẹ to legba ọkọ meji lekan soso silẹ ki o le mu adikun ba sunkere fakere ọkọ irinna ni opopona naa.

Àwọn ọ̀nà mìíràn tóó lè gbà lásìkò àtúnṣe marosẹ Eko si Ibadan

Oladeinde tun so siwaju si wi pe

-U-turn to wa ni iwaju ile iṣe pajawiri nipinlẹ Eko

-yoo si wa ni titipa fun igba die ti awọn onimoto ti o n gba opopona naa ni won yoo dari si U-turn to wa ni Toll Gate atijo lati yii si ibikibi ti wọn n lo.

Bakan naa lo tun tenumo pe awon oko ajagbe ni wọn yoo dari si Ojota Interchange,

nigba ti ona opopona CMD loju ọna marose ni wọn yoo dari si ibi ti wọn ti n wọle legbe afara FMW

Kọmiṣọnna tun tọka si pe ọna ti o gba opopona marosẹ ile-iwe Caleb International yoo wa ni titipa fun igba diẹ,

o fi kun pe opopona CMD ni awọn ọkọ ayọkẹlẹ ti o n lo si Ibadan yoo gba.

O rọ awọn ti o n lo opopona marosẹ naa lati maṣe duro si awọn oju ọna kí ó máa bá ṣe idaduro fun awọn ti wọn n lọ opopona naa.

Oladeinde tun ṣe idaniloju pe awọn ami itọnisọna yoo wa ni awọn agbegbe ti iṣẹ opopona naa ti n waye lati dari awọn awakọ.