Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Bola Tinubu tọ fẹ́ di Ààrẹ Naijiria

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, @officialABAT

Bola Ahmed Tinubu, to jẹ ẹni aadọrin ọdun ni ọpọ gbagbọ pe oun lo tun ilu Eko ṣe, ti ipinlẹ naa fi di eyii to ni ọrọ aje nla.

Gẹgẹ bii oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Tinubu n koju atako lati inu awọn ẹgbẹ oṣelu mii bii PDP ati LP.

Gẹgẹ bii ẹni to ti sa kuro ni Naijiria ri lọ silẹ okeere lasiko iṣejọba Abacha, ami idanimọ rẹ, eyii to maa n wa ni gbogbo fila rẹ ni ti ṣẹkẹṣẹkeẹ to ti ja, eyii to farajọ nọmba ‘8.’

Tinubu kẹkọọ gboye ninu eto iṣiro, o si ti fi akoko igba kan jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ to n wa epo rọbi, iyẹn Mobil.

Ni bayii to n dije du ipo Aarẹ, Tinubu ti ri ipo naa gẹgẹ bii ẹtọ rẹ ati ere lẹyin iṣẹ to ti ṣe lati gbe awọn eeyan kan dide ninu oṣelu Naijiria.

Eredi ree to fi sọ niluu Abeoku lọdun to kọja pe “ Emi lokan.”

Lootọ ni Tinubu ni ọpọ iriri ninu eto oṣelu, eyii si jẹ ọkan lara awọn koko ti awọn ololufẹ rẹ fi n polongo ibo fun un.

Ti gomina ipinlẹ Eko nigba kan ri naa ba jawe olubori, lara awọn nnkan ti yoo dojukọ gẹgẹ bii Aarẹ ni iṣoro eto abo, airiṣẹ ṣe laarin awọn ọdọ ati iṣọkan Naijiria to n mi lẹsẹ.

Amọ awọn ipenija wọnyii ko mi Tinubu laya, gẹgẹ bo ṣe maa n sọ pe oun ni iriri to dantọ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Eko laarin ọdun 1999 si 2007.

Lasiko iṣejọba rẹ bii gomina Eko, o ṣe afikun lọpọlọpo si iye owo ti ipinlẹ naa n pa wọle laarin oṣu kan, o si gbiyanju lati din sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ oju popo ku.

Lagos

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn Esun ti wọn ti fi kan Tinubu?

Ṣugbọn lẹyin to ti kuro lori aleefa, ọpọ eeyan lo n sọ pe ilu Eko kii ṣe ‘maga city’ bi awọn alatilẹyin rẹ ṣe n sọ nitori awọn nnkan ti ko si nibẹ, to fi mọ awọn inira ti ọpọ olugbe ipinlẹ naa n lakọja lojojumọ.

Yatọ si eyii, ọpọ eeyan lo fẹsun kan Tinubu pe oṣooṣu lo n gba obitibiti owo lọwọ ijọba ipinlẹ ọhun, amọ o ti sọ pe irọ nla ni ẹsun yii.

Gbobgo awọn to ti jẹ gomina lẹyin Tinubu lo jẹ awọn ọmọlẹyin rẹ ninu oṣelu, a tilẹ gbọ pe ẹni to ba kọ lati ṣe ti Tinubu ko ni tọ ipo gomina Eko wo lailai.

Awọn kan tun fẹsun ajẹbanu kan agba oloṣelu ọhun amọ gbogbo ẹṣun naa lo ni kii ṣe ti oun.

Lọdun meji sẹyin, Dapo Apara to jẹ oluṣiro owo nileeṣẹ Alpha-beta fẹsun kan Tinubu pe o n lo ileeṣẹ naa, ti ọpọ gbagbọ pe o lọwọ ninu idasilẹ rẹ, lati ko owo ilu lọ silẹ okeere.

Tinubu ṣe ẹsun yii, koda o gbe ọgbẹni naa lọ silẹ ẹjọ, amọ lẹyinorẹyin, wọn pari ọrọ naa ni itubi inubi.

Ninu eto idibo to kọja, ọkọ ti awọn banki fi n ko owo ‘bullion van’ wọ inu ile Tinubu, eyii ti awọn eeyan sọ pe wọn fi ṣe magomago ninu idibo naa, amọ Tinubu ko sẹ ọrọ naa, o si sọ pe oun ko ji owo ijọba ko, beẹ si ni ki ẹnikẹni to ba ni ẹsun lati fi kan oun gbọdọ mu ẹri to dantọ jade.

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, @officialABAT

Tinubu lori ọrọ Lekki Toll Gate:

Ọpọ awọn ọdọ lo tun maa n naka abuku si Tinubu latari iṣẹlẹ iṣekupani to waye ni iloro Lekki Toll Gate ni ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020.

Ni bayii ti eto idibo gbogbogbo ti sunmọle, ọpọ eeyan lo n sọ pe Tinubu ko gbadun, o si ni lati ṣetọju ara rẹ dipo ko maa du ipo Aarẹ.

Lara awọn to ni irufẹ ero bayii yatọ si ọpọ araalu ni Reno Omokri, Dino Melaye, atawọn eeyan pataki mii ni Naijiria.

Wọn ni ko yẹ ki Naijiria tun ṣe aṣiṣe lati yan Aarẹ ti yoo maa fi gbogbo igba lọ soke okun fun itọju ilera rẹ.

Wayi o, boya Tinubu jawe olubori ninu idibo ọdun yii tabi beẹ kọ, Aarẹ tuntun ti yoo gba ijọba lọwọ Buhari yoo ni ọpọ iṣoro lati tan.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo si gbagbọ pe Naijiria yoo ṣi dara bo tilẹ jẹ pe pupọ ninu wọn lo ti n japa.