Ààwẹ̀ gbígbà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí lé ṣé àkóbá fún kíndìnrín

Aworan

Oríṣun àwòrán, NAFDAC

Ajọ to n mojuto lilo ati tita oogun oloro ni Naijiria, NAFDAC ti kilọ fun awọn ọmọ Naijiria lori aawẹ gbigba fun ọpọlọpọ wakati nitori o le ṣe ọpọlọpọ akoba fun kindinrin lago arawọn.

Amọran yii wa lati ẹnu Ọga agba fun ajọ naa, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja.

Adeyeye ni fifi ebi pa ara ẹni ni pasẹ ounjẹ ati omi fun ọpọ wakati ni o le sokunfa ki kindinrin dẹnu kọlẹ nitori o nilo lati ma ri omi ni orekore lati sisẹ dada lago ara.

O wa gba awọn araalu ni mọran paapa awọn ẹlẹsin ti wọn gba aawẹ ni orekore lati ṣe niwọn ninu gbigba awọn lati dabo bo ẹmi wọn.

Adeyeye tẹsiwaju pe ọpọ eewu lo wa ninu gbigba aawẹ fun ọpọlọpọ wakati sugbọn o rọ wọn lati ma mu omi lorekore lati ṣe itọju kidinrin ati ago arawọn.

“Ẹ gbọdọ jẹ ounjẹ, ki ẹ si mu ọpọlọpọ omi ti yoo mu ki awọn éya ago ara yin se isẹ to yẹ ki wọn ṣe lago ara yii.

“Awọn eeyan kan wa ti wọn yoo gba aawẹ fun ogunjọ tabi ju bẹlọ lia jẹun tabi mu omi. Eyi le lo sokunfa ijamba si kidinrin nitori ko si omi ati ounjẹ ninu ara.

“A ni lati jẹ ki awọn eeyan wa mọ nipa rẹ. A gbọdọ gba aawẹ pẹlu ori pipe, lia jẹbẹ, a yoo ṣe ijamba fun kidinrin wa.”