"Ìjọba Benue ló ní ka kúrò, tí àdó olóró fi pa Fulani 27, tí ọ̀pọ̀ sì farapa"

Olori ẹgbẹ awọn Fulani darandaran nipinlẹ Nasarawa, Mallam Ardo Lawal ti salaye lẹkunrẹrẹ fun BBC nipa bi isẹlẹ ado oloro to mu ẹmi Fulani mẹtadinlọgbọn lọ se waye.
Lasiko to n ba BBC sọrọ, Lawal ni awọn eeyan oun lọ gba maalu wọn lọdọ ijọba ipinlẹ Benue ni ado oloro naa bu.
O ni ijọba ipinlẹ Benue lo pasẹ pe kawọn Fulani darndran kuro lagbegbe ti wọn wa naa, asiko ti wọn si n ko awọn ẹran wọn kuro ni ado oloro bu.
O wa fidi rẹ mulẹ pe lọwọ lọwọ bayii, oku Fulani mẹtadinlọgbọn lo wa lọwọ wọn , ti ọpọ eeyan miran si n gba itọju nile iwosan.

Mo ti ran ikọ lọ lati lọ pẹtu si awọn to le fapa janu lori isẹlẹ yii – Gomina Nasarawa
Wayi o, gomina ipinlẹ Nasarawa, Onimọ ẹrọ Abdullahi Sule ti kede igbesẹ to n gbe lati ri daju pe alaafia jọba lagbegbe ti isẹlẹ naa ti waye.
Sule ni oun lo gbogbo oru mọju lori isẹlẹ yii lati pẹtu si aawọ to le suyọ ni kete ti oun gbọ nipa isẹlẹ naa.
Gomina Sule, ẹni to se ipade awọn akọroyin nilu Lafia tun sisọ loju rẹ pe oun ti gbe ikọ onisẹ dide, ninu eyi ti igbakeji gomina wa.
O ni awọn ikọ naa ti lọ silu Doma lati ri pe wahala kankan ko sẹlẹ lati ipasẹ ado oloro to bu naa.
“Lati oru mọju ni mo ti wa lori isẹlẹ yii, mo n ba olori ileesẹ oloogun atawọn ileesẹ agbofinro miran sọrọ lori isẹlẹ yii.”
Bakan naa ni gomina yi tun fidi rẹ mulẹ pe isẹlẹ ado oloro naa waye lasiko tawọn darandaran n lọ ko maalu wọn nipinlẹ Benue.
Àdó olóró gbẹ̀mí Fulani 27, ọ̀pọ̀ míì farapa yánayàna

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn agbofinro nipinlẹ Nassarawa ti kede pe o kere tan, Fulani mẹtadinlọgbọn ti jade laye nigba ti awọn mii farapa yanayana .
Eyii ko ṣeyin ado oloro kan to bu gbamu ni abule kan to wa ni aala ipinlẹ Nassarawa si Benue.
Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Nasarawa, Maiyaki Muhammed Baba, lo fidi iroyin naa mulẹ fun BBC.
O ni “Nigba ti a o ji laarọ oni ni a gbọ pe awọn kan ju ado oloro, a tun gbọ pe ado oloro kan bu gbamu, ni bayii ọpọ ẹmi lo ti sun, nigba ti ọpọ maalu ti sọnu.”
Baba fi kun pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.
O fi kun pe oun ko le sọ boya oju ofurufu ni wọn ti ju ado oloro naa tabi ṣe ni wọn ri mọlẹ.
Kọmisọna ọhun tẹsiwaju pe “Ni bayii, oku eeyan mẹtadinlọgbọn ni a ti ri, ọpọ awọn mii si ti farapa.”
Abule Doma, ni Nasarawa ni ibugbamu naa ti waye.
Nigba to n sọrọ, adari ẹgbẹ awọn Fulani darandaran, iyẹn Miyetti Allah Kautal Hore ni Nasarawa sọ fun BBC pe lootọ ni ẹmi eeyan mẹtadinlọgbọn ti sọnu.
Lẹyin naa lo ke si ijọba lati ri daju pe iwadii to peye waye lori iṣẹlẹ ibugbamu ọhun.
Ipinlẹ Nasarawa ati Benue wa lara awọn ipinlẹ ti ija ti n waye julọ laarin awọn Fulani darandaran atawọn agbẹ, ọpọ ẹmi lo si ti ba ija naa lọ ṣaaju asiko yii.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
Agbébọn jí èèyàn mẹ́ta ní Osun, bèèrè mílíọ̀nù márùn-ún náírà owó ìtúsílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn agbebọn kan ti ji ẹniyan mẹta gbe ni ilu Iwo ti o wa ni ijọba ibilẹ Iwo ni ipinlẹ Osun.
Ti Wọn si ti beere fun miliọnu marun naira idasilẹ wọn.
Awọn agbebon na ni won ṣiṣẹ ijinigbe naa lọjọ eti to koja yii, oruko awọn ti wọn jigbe gẹgẹ bi ọlọpa ipinlẹ Osun ti so ni Hamzat Ibrahim, Deere Ibrahim ati okunrin eni odun mejidinlogoji (38) ti won ko tii da oruko e.
A gbo pe wọn ji wọn gbe ni inu oko wọn to wa ni agbegbe Ologun nijoba ibile iwo.
Okan lara awon ode ni ipinle naa nigba to n ba awon onkoroyin soro ni Osogbo so pe, “Fulani ni awon ti won ji gbe, oko ni won wa nigba ti awon ajinigbe naa de.” Ode na so pe awon ajinigbe naa ti kan si awon molebi ti won si beere fun milliọnu marun naira.
Nigba ti o n fidi isẹlẹ naa mulẹ, agbenusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Iyaafin Yemisi Opalola, sọ pe Hamidat Ibraheem kan lo fi isẹlẹ naa to ile ise ọlọpaa ni ipinlẹ naa.
O ni, “Awon agbebon naa ji Hamzat Ibrahim, Deere Ibrahim ati okunrin eni odun mejidinlogoji (38) gbe.
Yemisi ni awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ Ọlọpa ati awọn ode ati awọn ile-iṣẹ to risi aabo agbegbe miiran n ṣajọ igbo lati dola ẹmi awọn ti wọn jigbe naa.















