Betty Akeredolu: Ẹbí Bunmi Ademosun wọ́ aya gómìnà lọ ìwájú ọ̀gá ọlọ́pàá torí fọ́nrán ìdúnkookò rẹ̀ sí ọmọ wọn
Bí aburú bá ṣe ọmọ wa, aya Akeredolu ni kí ọlọ́pàá mú - Ẹbí Bunmi Ademosun kìlọ̀

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Awọn ẹbi oluranlọwọ pataki fun Gomina ipinlẹ Ondo, Bunmi Ademosun, ti kọwe si Ọga agba ọlọpa Usman Baba lori idunkooko aya gomina ipinlẹ Ondo.
Bakan naa ni wọn tun kọwe si ajọ to risi eto aabo labẹle DSS, lati fi panpẹ ijọba mu iyawo Gomina ipinlẹ Ondo Betty Anyawu Akeredolu, ti aburu baa ṣe Bunmi Ademosun.
Bẹẹ ba gbagbe, ninu fọnran ohun kan to n lọ kaakiri ayelujara, ni iyawo Akeredolu ti fi ẹsun kan oluranlọwọ pataki fun ọkọ rẹ, Bunmi Ademosu, pe o n gbe agbo wa fun ọkọ oun.
Aya Akeredolu naa wa kilọ fun obinrin ọhun pe ko dẹyin lẹyin ọkọ oun, ko si fi opin si awọn agbo ọhun to ni pasitọ lo gbe fun oun.
Arabinrin Akeredolu ṣalaye pe iṣegun oyinbo nikan ni awọn gbẹkẹle, eyi ti igbgbọ wa pe yoo mu Aketi lara da.
Ìdílé Elemo tí ìlú Akure kìlọ fún Ìyàwó Akeredolu
Adari idile Elemo Adedipe ti ilu Akure, ti Olubunmi ti wa, bẹnu atẹ lu iyawo Gomina ati idunkooko rẹ si ọmọ wọn.
O wa kilọ fun pe aburu ko gbọdọ ṣe ọmọ wọn, Bunmi Ademosun.
Alagba Olajide, tii se ọkan laara awọn adari idile Adedipe, ninu atẹjade to fi ransẹ si awọn ẹka aabo ati ile iṣe ọlọpa ni, gbogbo idile Elemo ti ilu Akure n kilọ fun iyawo Gomina ipinlẹ Ondo, lati maṣe fọwọ kan Bunmi ati awọn nkan ini rẹ.
Ninu atẹjade naa ni wọn ti tọka si ẹsẹ Bibeli, iwe owe, ori kọkanlelogun, ẹsẹ Kẹsan ati ori karundinlọgbon, ẹsẹ karun pẹlu ẹsẹ kẹrinlelogun to sọ pe;
"O san lati maa gbe ni kọrọ ori orule ju lati ṣe ajọpin ile pẹlu aya onija.
O san lati jokoo ni aginju pẹlu onija obinrin ati oṣonu lọ.
Mu eniyan buburu kuro niwaju ọba a o si fìdi itẹ rẹ mule nipasẹ ododo.
O san lati gbe ni ibi igun kan lori orule ju lati ba aya onija gbe ile pọ".
Idile Elemo ni o se oun laanu pe Gomina Akeredolu koju iṣoro ainisinmi ninu ile pẹlu aisan to de ba agọ ara rẹ lasiko yii.
O ni awọn darapọ mọ awọn ọmọ ipinlẹ Ondo lati gbadura alafia pipe fun Gomina Akeredolu.

Oríṣun àwòrán, Other
Ijọba ipinlẹ Ọndo ti bọ sita lati ṣalaye lori ipo ilera gomina ipinlẹ naa, Rotimi Akeredolu.
Igbesẹ naa waye lẹyin ti iroyin n lọ kaakiri pe ori idubulẹ aisan ni gomina wa.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun gomina, Richard Olatunde fi ṣọwọ si BBC lọjọ Iṣẹgun, o ni eniyan ẹlẹran ara ni Gomina Akeredolu, to ni ailera, amọ to ti gba itọju, ti ara rẹ si ti n pada bọ sipo.
Ọjọ Aje ni fọnran ohun kan jade sori ayelujara, eyi ti ọpọ gbagbọ pe ohùn naa jẹ ti iyawo Akeredolu, Betty Akeredolu.
Ninu fọnran naa ni onitọhun ti n sọ pe ara Akeredolu ko yá.
Awọn nkan to wa ninu fọnran naa mu ki ọkan ọpọlọpọ lọ soke nitori ilera gomina.
Yatọ si ti ilera, obinrin to sọrọ ninu fọnran naa tun fi ẹsun kan obinrin mi, pe o n lo aisan ọkọ oun fun anfaani ara rẹ.
Bakan naa lo tun sọ pe awọn kan n gbimọ ninu iṣakoso Akeredolu, lati fi obinrin naa jẹ igbakeji gomina, ti ohunkohun ba fi ṣẹlẹ si gomina.
BBC Yoruba ko ri aridaju tabi le fi idi orisun fọnran naa mulẹijọba paapaa ko si mẹnuba awọn ẹsun naa ninu atẹjade to fi sita.
Awọn nkan ti 'iyawo Aketi' sọ ninu fọnran
Ninu fọnran to n lọ kaakiri ayelujara, obinrin kan to pe ara rẹ ni iyawo Akeredolu fi ẹsun kan pe obinrin kan, Bunmi Ademosu, to jẹ oluranlọwọ pataki fun gomina, n gbe agbo wa fun ọkọ oun.
Ẹni to sọrọ ninu fọnran naa kilọ fun obinrin ọhun pe ko dẹyin lẹyin ọkọ oun, ko si fi opin si awọn agbo ọhun to ni pasitọ lo gbe fun oun.
‘Arabinrin Akeredolu’ ṣalaye pe iṣegun oyinbo nikan ni awọn gbẹkẹle, yoo si mu Aketi lara da.
Ninu fọnran naa bakan naa lo tun ti fi ẹsun kan pe obinrin ọhun n gbiyanju lati di igbakeji gomina lọna èèrú.
O ni igbakeji ọkọ oun, Lucky Aiyedatiwa (igbakeji Akeredolu) ni yoo gba ipo, ti ohunkohun ba fi ṣẹlẹ si Aketi, gẹgẹ bi ilana ofin.
Awọn nkan miran to wa ninu atẹjade ijọba ipinlẹ Ondo
Agbẹnusọ fun gomina, Richard Olatunde sọ pe botilẹ jẹ pe ara gomina ko tii mókun daadaa, o ṣi n ṣe iṣẹ ti ilu gbe le e lọwọ.
“Kii ṣe aisan to le gba ẹmi, lo n ba gomina ja, eyi to le mu ki ọtẹ o bẹrẹ ninu iṣejọba rẹ.
“Koda, gomina lo dari ipade igbimọ alaṣẹ titi di aago mẹrin irọlẹ Ọjọru to kọja, ọjọ kọkanla, oṣu Kinni, 2023, lẹyin to ti kọkọ ṣe ipade igbimọ to wa fun eto aabo nibi ti wọn ti jiroro lori rogbodiyan to n waye niluu Ikare-akoko.”
Atẹjade naa tun sọ pe Gomina Akeredolu lo ṣiwaju awọn gomina ilẹ Yoruba, ati awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC miran, fun ipolongo ibo aarẹ ẹgbẹ naa to waye niluu Akure lọjọ keje, oṣu Kinni, ọdun 2023.
O ni bi gomina ṣe n ṣiṣẹ, naa lo n waaye fun isinmi.












