Àdó olóró gbẹ̀mí àwọn olùjọ́sìn mẹ́wàá nínú ilé ìjọsìn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kere tan eeyan mẹwaa ti padanu ẹmi wọn ti eeyan mokandinlogoji miran farapa lọjọ Aiku.
Eyi waye ninu ikọlu ado oloro to waye nile ijọsin kan ni ila-oorun orilẹ-ede Democratic Republic of Congo.
Agbẹnusọ ikọ ologun, Congo Antony Mualushayi sọ pe iṣekupani naa ṣẹlẹ ni ile ijọsin Pentecostal kan to wa lagbegbe Kasindi, ni ariwa Kivu, ilu kan to paala pẹlu Uganda.
Iṣẹlẹ naa pa o kere tan eniyan mẹwaa, nigba ti awọn mokandinlogoji gbọgbẹ.
O fikun pe o ṣeeṣe ki awon to gbemi mi po ju akọsilẹ ijọba lọ.
Kini Ijoba DRC Congo n sọ?
Ṣugbọn agbẹnusọ fun ile iṣẹ ologun ti Uganda ni DRC, Bilal Katamba, sọ pe ni irọlẹ ọjọ Aiku pe eniyan mẹrindinlogun lọ bá iṣẹlẹ naa lo
Ati pe eeyan ogun ni o fara gbọgbẹ ninu ijamba naa.
Eka ijọba to wa fun ibaraẹnisọrọ ti DRC sọ lori ẹrọ ayelujara ni o han gbangba pe ikọlu naa waye nipasẹ ẹgbẹ́ Allied Democratic Forces (ADF) - ẹka akatakiti ẹsin Islam.
Alakoso ijọba orilẹ-ede DRC koro oju si ikọlu naa, ti ajọ agbaye to n ri si ipetu si aawọ si ṣapejuwe ikọlu naa bi ikolu ẹru ati ẹgan
Lọdun 2021, orilẹede Amẹrika ninu atẹjade ni ẹgbẹ ADF “jẹ ẹgbẹ alakatakiti to ni atilẹyin ile okeere ”
awọn ẹgbẹ ọmọ ogun naa n ṣiṣẹ ni Ariwa Kivu ati agbegbe Ituri lorilẹede DRC.












