Kí ni pàtàkì Chatham House àti pé kí ló ń gbé àwọn olóṣèlú Naijiria lọ síbẹ̀?

Chatham House

Oríṣun àwòrán, BBC/CHATHAM HOUSE/TWITTER

Ọsẹ diẹ lo ku bayii ki eto idibo gbogbogbo waye ni Naijiria, ajọ to n ri si eto idibo, INEC si ti sọ pe oun ko ni sun idibo naa siwaju.

Lọwọ yii, eto ipolongo ibo ti n lọ lọwọ, nibi ti awọn oludibo, paapaa sipo Aarẹ ti n sọ awọn ohun ti wọn fẹ ṣe fun awọn araalu.

Lara awọn ibi ti awọn oloṣelu naa ti n lọ polongo ibo wọn ni ile kan ti wọn n pe ‘Chatham House’ niluu London.

Awọn oloṣelu to ti lọ si Chatham House

Lọdun 2018 ni oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar lọ si Chatham House naa, iyẹn ṣaaju idibo ọdun 2019.

Ninu ọdun 2022, oludije ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu naa ti lọ si Chatham House, nibi to ti sọrọ nipa erongba rẹ fun Naijiria.

Ẹwẹ, oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi naa yoo faranhan niwaju awọn eeyan ni Chatham House yii bakan naa lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kini, ọdun 2023.

Wayi o, ibeere ti ọpọ araalu n bere ni pe ‘ki ni pataki Chatham House yii ati pe ki n eredi ti awọn oloṣelu nlanla ṣe n lọ sibẹ?’

Ki lo n gbe awọn oloṣelu Naijiria lọ si Chatham House?

Samuel Ihensikhen, to jẹ agbẹjọro sọrọ lori pataki Chatham House.

O ni “Lootọ ni pe ofin Naijiria lori ọrọ eto idibo ko faye gba awọn eeyan ilẹ okeere lati dibo amọ gbogbo agbaye yoo mọ nipa awọn eto ti ẹnikẹni to ba lọ sibẹ ni fun araalu.”

Agbẹjọro naa ni Chatham House jẹ ibi ti awọn oloṣelu ti maa n so awọn alakalẹ wọn faraalu ki awọn eeyan ilẹ okeere le mọ nipa rẹ.

Ihensikhen fikun pe awọn oloṣelu fẹran lati maa lọ sibẹ nitori iyi ati apọnle to rọ mọ.

O pari ọrọ rẹ pe “Awọn eniyan nla lo n lọ si Chatham House, lilọ sibẹ si maa n fikun iyi irufẹ ẹni bẹẹ lagbo oṣelu.

Ki ni Chatham House gan?

Orukọ mii ti Chatham House n jẹ ni ‘Royal Institute of International Affairs.’

Ilu London ni olu ọọfisi ajọ naa wa nilẹ Gẹẹsi.

Chatham House jẹ ibi ti wọn ti maa n sọrọ nipa bi ilu yoo ṣe toro ti yoo si ni itẹsiwaju.

Gbogbo ọrọ to maa n jade nibẹ lo kimi, to si maa n gba iyi kaakiri agbaye.