Àwọn afurasí agbésùnmọ̀mí jí àádọ́ta obìnrin gbé ní Burkina Faso

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko din ni aadọta obinrin, ti awọn afurasi agbesunmọmi ji gbe ni Ariwa orilẹ-ede Burkina Faso.
Awọn olugbe nilu Arbinda sọ pe ọna meji ni wọn ti ji awọn obinrin naa gbe, lasiko ti wọn n ṣa ewé ati eso ninu igbo.
Eyi ko ṣẹyin aisi ounjẹ to to niluu naa nitori ikọlu awọn agbesunmọmi.
Diẹ lara awọn obinrin na lo ri aaye salọ.
Botilẹ jẹ pe Ọjọbọ ati ọjọ Ẹti to kọja ni awọn ijinigbe naa ti waye, iroyin nipa wọn ṣẹṣẹ jade sita ni, nitori pe pupọ ninu agbegbe naa ni awọn agbesunmọmi Islam ti di pa.
Olugbe ilu naa kan sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe awọn obinrin naa ko ara wọn jọ lati ṣa ewe ati eso ninu igbo, nitori pe ko si ounjẹ kankan mọ fun jijẹ.
“Ọjọbọ ni wọn kuro nile, ṣugbọn wọn o pada sile titi di irọlẹ.
“A kọkọ ro pe kẹẹkẹ akẹru ti wọn gbe lọ bajẹ si oju ọna ni. Ṣugbọn awọn mẹta to ri aaye salọ pada sile lati sọ nkan to ṣẹlẹ.”
Ilu Arbinda ni iṣẹ ọwọ awọn agbesunmọmi naa n pa lara julọ ni ẹkùn olooru lorilẹ-ede naa.
Gbogbo ọna to wọle si ilu naa, ati wti to jade, ni awọn agbesunmọmi di pa. Eyi si mu ki ebi pọ nitori pe agidi ni ounjẹ fi n wọle sibẹ.
Ni oṣu to kọja, awọn oluwọde yabo awọn ibudo ti wọn n ko ounjẹ si, lati ko ounjẹ ati awọn nkan eelo mii.
O ti pe ọdun mẹwaa ti awọn agbesunmọmi ti n gbogun ti Burkina Faso, to si ti le eeyan bi miliọnu meji kuro nile wọn.
Awọn ologun ditẹ gba ijọba ninu oṣu Kinni, ọdun to kọja, pẹlu ileri pe awọn yoo fi opin si ikọlu awọn agbesunmọmi.
Ṣugbọn ikọlu ko tii dinku titi di asiko yii.












