‘’Ọwó agbófinró tẹ Ọba méjì lórí ìjínigbé tó wáyé ní ojú irin Edo’’

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ijọba ipinlẹ Edo ti kede pe awọn ti fi panpẹ ọba mu awọn ọba alaye meji ti wọn fẹsun kan pe o lọwọ ninu ijinigbe to waye ni papakọ oju irin ni ipinlẹ Edo.

Ijọba Edo ni awọn meje miran pẹlu awọn ọba alade meji ti awọn mu lori iṣẹlẹ ijinigbe naa.

Iṣẹlẹ naa waye ni Ọjọ Satide, Ọjọ Keje, Oṣu Kini, ọdun 2023, nibi ti awọn agbebọn mẹfa ti yabo ibudokọ oju irin to wa ni ilu Igueben, nipinlẹ Edo.

Eero mejilelọgbọn ati oṣiṣẹ ibudokọ naa meji, ni iroyin kọkọ sọ pe wọn jigbe lasiko ti awọn eeyan naa n duro de ọkọ ti yoo gbe wọn lọ si ipinlẹ Delta.

Amọ lẹyin naa ni ijọba tun pada kede pe ogun eeyan ni wọn jibe.

Laipẹ ni wọn kede pe eeyan mẹjọ gba itusilẹ ni ibẹrẹ ọsẹ to kọja, meji miran si tun gba ominira lọjọ Ẹti bakan naa.

 Bakan naa ni ijọ̀ba tun kede eniyan mejila miran tun ti gba itura to si ku eniyan meji sibẹ.

‘’Inu wa dun lati kede pe eniyan meje ati awon adari abule meji ni owo ti tẹ’’

Kọmiṣọnna fun eto iroyin, Chris Nehikhare lo kede fun awọn akọroyin pe igbiyanju nlọ lọwọ lori iwadii iṣẹlẹ ijinigbe oju irin naa.

Nehiklare ni awọn layọ lati kede pe ọwọ sinkun ofin ti mu eniyan meje ati adari abule meji ti wọn niiṣe pẹlu ijinigbe naa.

Nibayii, ijọba fikun un pe eniyan meji lo ṣi wa ni panpẹ awọn ajinigbe lẹyin ti wọn doola ẹmi awọn to ku.

Wọn wa rọ awọn araalu lati maa kiyesi ara ati pe ki wọn fi to ijọba leti ti wọn ba ri ohun ti ko yẹ.

Méjìlá nínú èèrò rélùweè tí wọ́n jígbé ní Edo tún gba òmìnira

Ọkọ reluwe ti wọn kọlu

Oríṣun àwòrán, nrc

Eero ọkọ mejila ninu awọn ti wọn jigbe ni ibudokọ ọkọ reluwe ni ipinlẹ Edo l’ọsẹ to kọja, tun ti gba itusilẹ.

Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki, lo kede bẹẹ fun awọn akọroyin lọjọ Aiku, ni ileewosan Police Cottage niluu Benin, nibi ti pupọ ninu awọn eeyan naa ti n gba itọju.

Gomina Obaseki sọ pe apapọ awọn ileeṣẹ alaabo lo doola awọn eeyan naa.

“A ni anfaani lati tọpinpin wọn, ti a si ri mejila ninu eeyan mẹrinla to ku si ahamọ wọn gba, lai farapa.”

Eeyan mejila ti wọn ṣẹṣẹ doola yii, ti mu ki iye awọn to ku sibẹ jẹ meji.

Obaseki ni o ṣeni laanu pe ajọ to n mojuto irinajo ọkọ oju’rin, ko kẹkọọ lara ikọlu ti awọn agbebọn ṣe si ọkọ kan ni ipinlẹ Kaduna lọdun 2022, nibi ti wọn ti pa ọpọ arinrinajo, ti ọpọlọpọ si tun di eero ahamọ ajinigbe.

Ọjọ Satide, ọjọ keje, oṣu Kinni, ọdun 2023, ni iroyin sọ pe agbebọn mẹfa yabo ibudokọ oju irin to wa ni ilu Igueben, nipinlẹ Edo,.

Eero mejilelọgbọn ati oṣiṣẹ ibudokọ naa meji, ni iroyin kọkọ sọ pe wọn jigbe lasiko ti awọn eeyan naa n duro de ọkọ ti yoo gbe wọn lọ si ipinlẹ Delta.

Ṣugbọn ijọba tun pada kede pe ogún eeyan ni.

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Edo kede pe eeyan mẹjọ gba itusilẹ ni ibẹrẹ ọsẹ to kọja, meji miran si tun gba ominira lọjọ Ẹti bakan naa.