Ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí 'ìbúgbàmù' tó dún níbi ìpolongo ìbò APC ní Rivers

Awọn to farapa nibi iṣẹlẹ naa

Oríṣun àwòrán, ALLWELL ENE

Ko din ni eeyan marun-un ti iroyin sọ pe o farapa, ti obinrin kan si fi ara pa pupọ mii lasiko ti ‘ibugbamu’ kan waye nibi ipolongo ibo gomina ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Rivers.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ APC nipinlẹ naa, Darlington Nwauju sọ fun BBC Pidgin pe ni nkan bi aago kan ọsan Ọjọbọ ni iṣẹlẹ naa waye, ni gbagede Ojukwu, ni agbegbe Rumuwoji, niluu Port Harcourt.

Nwauju ṣalaye pe ‘ibugbamu’ ọhun waye ṣaaju ki oludije APC fun ipo gomina nipinlẹ Rivers, Tonye Cole, to o de si gbagede ipolongo.

“Eyi ko ṣẹyin awọn ipolongo ojule si ojule to kọkọ n ṣe, ni oju ọna to lọ si ibi ipolongo nla naa.”

Ṣugbọn o, ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ibugbamu kọ lo waye, amọ ija laarin awọn eeyan kan to wa ni gbagede naa.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ fun BBC pe, ìró ariwo nla ti awọn gbọ́, lo mu ki wọn o sa kuro nibi ipolongo ibo naa.

Ọlọpaa sọ pe ‘ibugbamu’ kọ lo waye

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Rivers, SP Grace Iringe-Koko fi sita, o ṣalaye pe APC san ẹgbẹrun lọna igba Naira fun alaga ẹgbẹ awọn olugbe ni adugbo naa, fun lilo gbagede wọn.

O ni ṣugbọn awọn oloye ẹgbẹ ati ọmọ ẹgbẹ to wa ni igun ti ẹ nikan ni alaga pin owo fun.

“Igun keji ko ri gba lara owo naa, eyi to mu ki wọn o kọ̀ jalẹ pe APC ko ni i lo gbagede naa fun ipolongo rẹ, ayaafi ti awọn naa ba gba ipin ti wọn lara owo.

“Nkan to fa wahala niyẹn.”

SP Iringe-Koko sọ pe wahala to waye kii ṣe laarin APC ati ẹgbẹ oṣelu miran, ati pe eeyan meji pere lo farapa.

Bakan naa lo tun ṣọ pe alamojuto ileeṣẹ ọlọpaa ni agbegbe Port Harcourt, OC SIB, ati DPO ileeṣẹ ọlọpaa ni Mile One, tete fi opin si rogbodiyan naa, ti ipolongo ibo gomina APC si waye lai si wahala kankan.

Amọ ṣa, o tun sọ pe kọmisanna ọlọpaa ti paṣẹ pe ki iwadii waye lori iroyin to sọ pe ibugbamu lo waye.