Yoruba Nation, IPOB kò ní rí imú mí tí mo bá di Ààrẹ- Kola Abiola

Oríṣun àwòrán, others
Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu PRP, People's Redemption Party, Kola Abiola tí ṣeleri pe oun ko ni fi aye gba awọn ẹgbẹ to n pe fun ipinya Orilẹede Naijiria.
Abiola sọ eleyi nigba kopa ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ South West Development Stakeholders niluu Ibadan.
O ni igbesẹ awọn to n pe ipinya lorilẹede Naijiria ni ko ba ofin mu rara, to fi ara pẹ didalẹ Orilẹede.
"N ko ni fi aye gba iruru igbesẹ eyi to le se akoba fun isọkan Naijiria,
ti oun ijoba yoo si gbarukudi tí wọn ti wọn ba setan lati fọwọsowọpọ fun isọkan Naijiria."
Nigba to n sọrọ lori idi to se fẹ dije labẹ ẹgbẹ oselu PRP, Kola Abiola ni fun oun, ẹgbẹ naa lo rọrun julọ lati dije.
“Ẹgbẹ PRP nikan ni eeyan ti le lo ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan naira dije sile asoju-sofin, miliọnu kan abọ nairalati dije sipo gomina ati ẹgbẹrun lọna aadọta naira sile asofin ipinlẹ.
O ni eyi ni yoo mu ko rọrun fun awọn ọdọ lai le kopa ninu oselu, ti wọn yoo si tọ wara to n san ni Najiria wo.















