Ilé ìtura Premier Hotel da àwọn òṣìṣẹ́ sílẹ̀ bó ṣe kógbá wọlé báyìí

Oríṣun àwòrán, others
Iwadii tí fidi rẹ mulẹ pe Ile ìtura Premier Hotel niluu ibadan tí kogba wọle.
Ile ìtura ọhun ni o jẹ dukia Western Hotels Limited, ẹka Oodua Investment lo ti nko gba wọle lati ọjọ kejidinlọgbọn, osu kejila lọdun 2022.
Gẹgẹ bii ileeṣẹ iroyin The Nigerian Tribune ṣe gbe e jade lowurọ òní.
Ile ìtura naa ni ko fun awọn eeyan ni iṣẹ mọ, to si ti di ahoro, ti awọn ẹsọ ibẹ si n sọ fun awọn eeyan to wa si ile ìtura pe awọn ti kogba wọle.
Kini awọn alaṣẹ Premier Hotel so?
Alamojuto Odua Investment Limited, Mr Raji Adewale fi idi ọrọ naa mulẹ pe ile ìtura naa kan kogba wọle fun igba diẹ ni lati fun wọn ni anfani lati ṣe atunṣe si ayika ile ìtura ati ile itura naa.
O ni : "Pẹlu ilana wa lati pe ile ìtura igbalode, a n ṣe atunṣe si ile ìtura Premier Hotel lati sọ ọ di ile ìtura òní irawọ marun un.
"A gbe igbesẹ yii pẹlu gbìnmọ lati oke okun, ti awọn olubadowopọ si fọwọ si.
“A fẹ ṣe afikun sì awọn iye yara ti a ni ati awọn nnkan miiran.
A ro ìlera awọn osisẹ ni a fi ní pe ki awọn eeyan lara wọn lọ rọọkun nile.
A ni lati fun wọn lowo lori igbesẹ naa."













