Wọ́n ti sìnkú Bolanle Raheem tí ọlọ́pàá kan yìnbọn pa lọ́jọ́ Kérésìmesì ní Eko

Won ti sinku Bolanle Raheem ti ọlọpaa kan pa toyuntoyun ni Eko.
Oni ọjọ́ kẹtadinlogun, oṣu kinni, ọdun 2023 ni wọn ṣeto isinku arabinrin Bolanle Raheem.
Lọjọ Keresimesi ni ọlọpaa kan ti orukọ rẹ n jẹ DSP Drambi Vandi yinbọn pa Agbẹjọro Bolanle ni agbegbe Ajah.
Awọn ọlọpaa mẹta lo wa nibẹ nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ pẹlu ẹbi Bolanle.

Oríṣun àwòrán, Raheem Bolanle
Mi ò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn – Ọlọ́pàá tó yìnbọn pa Bolanle Raheem
Ọlọpaa ti wọn fẹsun kan pe o yinbọn pa Bolanle Raheem, to jẹ agbẹjọro lọjọ ọdun Keresimesi to kọja, DSP Drambi Vandi ti sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ipaniyan.
Ọjọ Aje ni Vandi foju bale ẹjọ giga to wa ni Tafawa Balewa Square nilu Eko lori ẹsun kan, to jẹ ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an.
Igbẹjọ naa, to yẹ ko bẹrẹ laago mẹsan an aarọ ni wọn sun siwaju nitori agbẹjọro afurasi ọhun ko tete dele ẹjọ.
Nigba ti wọn pe ẹjọ naa, agbẹjoro agba ipinlẹ Eko, Moyo Onigbanjo, SAN, sọ fun ile ẹjọ naa pe wọn sọ fun oun pe agbẹjọro olujẹjọ ko tii de.
Eyii to mu ki wọn da igbẹjọ naa duro titi to fi wọ ile ẹjọ.
Lara awọn to peju sibi igbẹjọ naa ni Aarẹ ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni Naijiria, NBA, Yakubu Maikyau, alaga ajọ NBA nipinlẹ Eko, Ikechukwu Uwanna, atawọn eeyan miran.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ ọdun Keresimesi ti ọdun 2022 ni iroyin gbode pe Vandi ti yinbọn pa oloogbe naa niwaju ọkọ atawọn mọlẹbi rẹ mii lagbegbe Ajah, niluu Eko.
Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo bu ẹnu atẹ lu ikọlu ọhun.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
Ìgbẹ́jọ́ lórí ikú Bolanle Raheem yóò bẹ̀rẹ̀ padà lónìí

Oríṣun àwòrán, others
Ileẹjọ giga ipinlẹ Eko yoo bẹrẹ gbigbọ ẹjọ afurasi ọlọpaa, Drambi Vandi to ṣekupa arabìnrin agbẹjọro Ọmọbolanle Raheem lọjọ ọdun Keresimesi ni agbegbe Ajah nipinlẹ Eko.
Ninu atẹjade kan ti ọfiisi Agbẹjọro agba fun ipinlẹ Eko buwolu pẹlu Kọmisonna fun ọrọ idajọ ododo, Moyosola Onigbanjo fi sita ni won ti sọ eyi.
Wọn ni Igbẹjọ Vandi to ṣekupa Ọmọbìnrin Agbẹjọro Ọmọbolanle Raheem lọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2022 ni yoo bẹrẹ lọjọ Aje:
Oni, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kinni,l ọdun 2023 niwaju Onidajọ Harrison ni ile ẹjọ giga nipinlẹ Eko ni TBS.
Drambi Vandi tí kọkọ yọju si ileẹjọ Magistrate ni Yaba ni ọgbọnjọ, oṣu kejila, ọdun 2022, ọjọ kejì lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa kede pe awọn ni ko lọ rọọkun nile fun igba diẹ.
Ki ní o ṣẹlẹ ṣáájú?
Wayi o, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nilẹ wa, Olumuyiwa Adejobi ti salaye pe ọga agba ọlọpaa kankan ko ni asẹ lati yọ osisẹ ọlọpaa kankan nisẹ.
Adejọbi fesi bẹẹ nigba to n dahun ibeere araalu kan to ni se lo yẹ ki wọn le osisẹ ọlọpaa to pa Bolanle Raheem lẹnu isẹ patapata ni.
Ninu alaye rẹ, Adejobi ni ajọ to wa fun akoso ileesẹ ọlọpaa lorilẹede yii, eyiun Police Service Commission (PSC) nikan lo ni agbara lati kede pe ki wọn le ọlọpaa kan lẹnu isẹ.
O fikun pe bi wọn se gba gbogbo agbara ati ẹtọ to ni gẹgẹ biii ọlọpaa, ti wọn si ni ko lọ rọọkun nile dabi ẹni pe wọn le lẹnu isẹ ni.
Adejobi wa fi ọwọ gbaya fawọn araalu pe ki wọn mase mikan, ko si giri nitori ọlọpaa naa yoo koju igbẹjọ to yẹ bayii.
"O di dandan ko foju wina ofin, ẹ ma mikan,asiko yii ni yoo koju igbẹjọ to yẹ bayii."












