Àwọn méͅta tó ti kópa 'Papa Ajasco' rèé nínú eré...

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ọpọlọpọ eniyan ni ko mọ pe kii ṣe eniyan kan lo n ko ipa Papa Ajasco ninu ere ori ẹrọ tẹlifisọn ti ọpọ ero mọ si Papa Ajasco.

Arakunrin Wale Adenuga to ni ileeṣẹ Papa Ajasco and Company lo n dari ere apanilẹrin naa ẹlẹyii ti wọn ma n ṣe afihan rẹ ni ori Waptv, AIT ati NTA.

Bio tilẹ jẹpẹ ọpọ ero n woye pe enikan lo n ṣe ere apanilẹrin Papa Ajasco naa, amọ o ti tọ eniyan meͅta to ti ko ipa Papa Ajasco ninu ere Papa Ajasco naa.

Peter Fatomilola

Aworan

Oríṣun àwòrán, @Others

Awọn ti a mọ to ti kopa ninu ninu ere adeͅrinposͅonu Papa Ajasco ni Peter Fatomilola, Femi Ogunrombi ati Abiodun AyoPeter Fatomilola ni ẹni akọkọ to kọpa ninu fiimu Papa Ajasco

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti ọgba ojẹ oṣere tiata, Peter Fatomilola ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin Punch lo ti kede pe oun ni

Eͅni àkóͅkóͅ tó kóͅkóͅ sͅe ere Baba Ajasco ninu ere ni baba Peter Fatomiloͅla ni oͅdun 1984.

Oruko ere naa nigba naa loͅhun ni ‘Ikébe Super.’

Abiodun Ayoyinka

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Abiodun Ayoyinka ti oͅͅpoͅͅ eniyan moͅ sì Papa Ajasko lo ti bẹrẹ sí ni kopa naa lati oͅdun 1996 titi di asiko yii.

Arakunrin Abiodun Ayoyinka to jeͅ eͅni oͅgoͅta oͅdun lo kuro ni ileesͅeͅ ‘Wale Adenuga production’ lo kuro nibeͅ laarin oͅdun kan.

Oͅdun 2007 loͅ pada si ipò rẹ gẹgẹ bi Papa Ajasco tó sì n sͅe titi di asiko yii.

Lara awoͅn ti woͅn jọͅ n kopa ninu ere Papa Ajasco ni Mama Ajasco to jeͅ iyawo Papa Ajasco, Bobo Ajasco to jeͅ oͅmoͅ woͅn to fi moͅ Boy Alinco, Miss Pepeiye, Pa James ati Pa Jimoh.

Titi di asiko, Papa Ajasco wa lara awoͅn ere ori teͅlifisan ti awọn eniyan wo julọ ni orile-eͅde to to mejila ni ileͅ adunlawoͅ.

Femi Ogunrombi

Papa Ajasco

Oríṣun àwòrán, WALE ADENUGA PRODUCTIONS LTD

Laarin oͅdun 2005 sí 2006 ni arakunrin Femi Ogunrombi kopa geͅgeͅ bi Papa Ajasco .

Asiko naa lo roͅpo arakunrin Abiodun Ayoyinka to ti ni kopa ninu ere naa lati oͅdun 1996.

Arakunrin Femi Ogunrombi ti oͅpoͅ moͅ si Papa Ajasco keͅkoͅ imoͅ orin ati ere tiata jade ni fasiti Oͅbafeͅmi Awolowo University ti Ile-Ifeͅ, ni ipinleͅ Osun.

Papa Ajasco moͅ nipa orin, onkoͅrin ni, oͅmoͅwe ni, to si n dari ere fiimu, to tun n koͅ awoͅn eniyan ni orin.

Yatoͅ si pe o koͅ awoͅn osͅere joͅ, iyeͅn National Troupe of Nigeria ati adari ileese Wap Tv, bakan naa lo tun sͅisͅeͅ peͅlu ileesͅeͅ orin, Tenstring Music Institute ati awoͅn miran.

Adéͅrìnpósͅónú Papa Ajasco ti jáde láyé

Iroyin to n teͅwa loͅwoͅ ni yajo-yajo ni pe adeͅrinposͅonu, Femi Ogunrombi ti gbogbo eniyan moͅ si Papa Ajasco ti jade laye.

Papa Ajasco lo jeͅ ilumoͅoͅka onifiimu ati elere itage nitori ipa to ko ninu ere Papa Ajasco ti ileesͅeͅ reͅ gbe jade.

Iroyin ni aleͅ oͅjoͅ Satide ni Ogunrombi jade laye.

Wale Adenuga Productions

Oríṣun àwòrán, Wale Adenuga Productions

Atẹjade kan lati oju opo ileeṣẹ to n ṣagbatẹru ere itage Papa Ajaco, Wale Adenuga Productions, WAP, lo fidi iroyin naa mulẹ.

Ninu atẹjade naa loju opo Facebook ati Instagram rẹ, WAP sọ pe ibanujẹ nla ni ipapoda Femi Ogunrombi jẹ fun awọn.

Femi Ogunrombi lo ko ipa Papa Ajasco laarin ọdun 2005 si 2006.

‘’A n sͅe idaro reͅ o, eͅni ireͅ, o daaroͅ Uncle Femi, o daaroͅ''

Ni oͅju opo ikansiraeͅni Facebook ni oniroyin ati olukoni ileeͅkoͅ Fasiti, Dr Shaibu Husseni ti kede pe Papa Ajasco ti jade laye.

Loju opo Facebook oͅhun lo ti ni awoͅn to sunmoͅ Papa Ajasco peͅki peͅ ti ti fi idi reͅ muleͅ pe akoͅni onimoͅ naa ti jade laye.

O kede pe Arakunrin Femi Ogunrombi, ti awoͅn eniyan ma n pe ni Uncle Ogurombo ti jade laye.

‘’A n sͅe idaro reͅ o, eͅni ireͅ, o daaroͅ Uncle Femi, o daaroͅ.’’

Tani Papa Ajasco?

Arakunrin Femi Ogunrombi ti oͅpoͅ moͅ si Papa Ajasco keͅkoͅ imoͅ orin ati ere tiata jade ni fasiti Oͅbafeͅmi Awolowo University ti Ile-Ifeͅ, ni ipinleͅ Osun.

Papa Ajasco moͅ nipa orin, onkoͅrin ni, oͅmoͅwe ni, to si n dari ere fiimu, to tun n koͅ awoͅn eniyan ni orin.

Yatoͅ si pe o koͅ awoͅn osͅere joͅ, iyeͅn National Troupe of Nigeria ati adari ileese Wap Tv, bakan naa lo tun sͅisͅeͅ peͅlu ileesͅeͅ orin, Tenstring Music Institute ati awoͅn miran.