Google Map: Ànfààní wo ló wà nínú lílo ẹ̀rọ̀ ajuwe ọnà pẹ̀l'óhùn Nàìjíríà?

Oríṣun àwòrán, TWITTER@GOOGLEAFRICA
Ohun yẹn niyen! Ile iṣẹ Google ti bẹrẹ si ni lo ohun Naijiria lati juwe ọna lawọn opopona ilẹ naa.
Google bẹ̀rẹ̀ sí lo ohùn Nàìjíríà lórí ẹ̀rọ̀ ajúwe ọ̀nà
Ikede yii jẹyo gẹgẹ bi ile iṣẹ naa ṣe fi awọn ilu mẹrin miran kun eleyi to ti wa nilẹ nibi ti awọn eeyan yoo ti ma lo ẹrọ ajuwe ọna.
Saaju asiko yii, ohun oyinbo lo ma n juwe ọna fawọn ọmọ Naijiria lori ẹrọ naa ti a si maa mu inira ba awọn ti ko ba gbo ohun ti oyinbo n sọ.
- Ọ̀rúnmìlà ni ó kọ́kọ́ lo 'Google' láàgbáyé-Ọ̀ọ̀ni Ìlẹ̀ ifẹ̀
- 'Ẹ má gbọ́kàn lé ewé o, ẹ má gbọ́kàn lé oṣo tàbí àjẹ, Ọlọrun nìkan ni “Oniduro wa!'
- Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni mo ti ń bá Adẹ́rùpọkọ̀ ṣe eré tíátà - Tope Alabi
- Wo nkan tó yẹ́ kí o mọ̀ nípa gbajúmọ̀ oníwàásù 'Lórí irọ́'
- Adeboye, Ayodele, Enenche sọ àṣọtẹ́lẹ̀ fún 2023
- Ìdí tó fi yẹ kí o máa mú ẹmu ògidì
- Àǹfàní dé fún ọ láti lo internet lọ́fẹ́
Ramesh Nagarajan to jẹ oludari ọja tita nileeṣẹ naa sọ fun BBC pe ohun Naijiria tawọn fi si inu ẹrọ ajuweọna naa ko yatọ si ti ọmọ Naijiria.
O ṣalaye pe ohun yii yoo si ma pe awọn orukọ adugbo lede wọn gangan eyi ti awọn Naijiria yoo gbọ́.

Oríṣun àwòrán, TWITTER@GOOGLEAFRICA
''Bi eeyan ba fẹ jẹ anfaani lilo ohun Naijiria yii lori ẹrọ, yoo kan lọ yii kuro lede Gẹẹsi si ede Gẹẹsi ti Naijiria ni.
Diẹ lara awọn aworan ibi ayẹyẹ ti Google ti ṣe ifilọlẹ yii ree ladugbo Lekki nilu Eko.

Oríṣun àwòrán, Google
Lọpọ igba ni ohun oyinbo a maa ṣi orukọ adugbo Naijiria pe ti ẹlomiran ko si ni mọ pato ohun ti o n sọ.
Ninu awọn ilu ti Google pẹka ẹrọ ajuweọna yii de lati ri Abuja, Benin, Enugu ati Ibadan.

Oríṣun àwòrán, Google












