Tope Alabi yà mí lẹ́nu gan o pé "Oniduro mi" kìí ṣe orin tó yẹ kí ọlọ́run fún mi - Tolu Adelegan
"Mo sọ fun awọn to n pe mi lati America ati London pe emi o ki n fi agidi wa ogo o".
BBC Yoruba lọ sile Olorin ẹmi to gba imisi to si tun kọkọ kọ orin "Oniduro Mi", Toluwalase Adelegan to fi ilu Akure ṣe ibugbe ti a si bere ọrọ lati tu iṣu de isalẹ koko lori ọrọ ti gbajugbaja olorin, Tope Alabi sọ lori itage ijọ kan to tin ṣe iṣẹ iranṣẹ orin pe ko tọ si olorin naa ko pe Ọlọrun ni Oniduro.
"Sister Tope Alabi ya mi lẹnu gan o pe o le sọ pe orin Oniduro Mi kii ṣe orin to yẹ ki Ọlọrun fun eeyan".
Adelegan ni oke lawọn ti maa n wo Tope Alabi pe Ọlọrun lo n fun un ni orin titi rẹ to si wa bọ si gbangba to n sọ pe ko yẹ ki Ọlọrun fun ẹlomiran ni orin.
"Awọn eeyan wa n pe lati Londo, America pe ki n lọ wa nkan ṣe si nkan mi, mo si ni emi o ki n fi agidi wa ogo o, Ọlọrun nikan ni ogo mi ati "Oniduro temi o".
Adelegan ni bo tilẹ jẹ pe Tope Alabi ti sọ ọ ni gbangba pe Ọlọrun kii ṣe Oniduro tirẹ to sile ni Oniduro si ibomiran ṣugbọn Oniduro toun ni.
Lori bi awọn eeyan tilẹ ṣe n ro pe olorin kan ti oun naa ti n di gbajugbaja, Adeyinka Alaseyori lo ni orin naa torii pe o kọ ọ jade, Adelegan ni kii ṣe Alaseyori lo ni orin yẹn, Ọlọrun lo fun oun ti oun si kọ si ori Facebook nigba naa pe Alaseyori kọ lo ni i amọ " Oluwa ni pe asiko ko tii to ṣugbọn nigba to di ana, mo gadura titi di bi ago kan kọja, Oluwa sọ fun mi pe ki n gbe igbesẹ tori naa gbogbo ẹyin fans mi ẹ fọkan balẹ".

