Tope Alabi vs Alaseyori: Mike Bamiloye fèsì sí ìtọrọ àforíjì tí Tope Alabi ṣe nítorí orin Oniduro Mi

Oríṣun àwòrán, Alaseyori, Bamiloye, Tope Alabi
Lẹyin ti iroyin bẹrẹ si ni jade lori ọrọ Tope Alabi lọrọ mii tun jade.
Orọ naa ni pe gbajugbaja agba olorin ẹmi, Tope Alabi to sọrọ si ọdọ olorin ẹmi, Yinka Alaseyori pe ko tọ fun un lati pe Ọlrun ni Oniduro ninu orin "Oniduro Mi to kọ, eekan oṣere Kristẹni.
Mike Bamiloye ti kọ ọrọ bíi afiwe Episteli.
Bamiloye dupẹ lọwọ Tope Alabi pe o ṣe ohun to tọ pẹlu awọn aforiji to fi sita o si gbadura fun un pe Eṣu yoo maa ri itiju lori aye rẹ titi lae ni.
O fi ọrọ to rọra ṣẹlẹ ranpẹ amọ to di ranto laarin ọsẹ kan atu ọjọ diẹ gẹgẹ bi ara awọn ogun to maa n suyọ ninu aye ati iṣẹ iranṣẹ eeyan eyi to si gbadura fun un pe yoo maa bori.
Si Ajihinrere YINKA ALASEYORI,
"O ṣeun pe o fara balẹ laarin iji ti eṣu gbe dide lati tu aarin iṣẹ iranṣẹ ti ko tilẹ tii gbooro tan fun isọji igba ikẹyin, ki Ọlọrun ko bunkun fun ọ ko si bu si ami ororo rẹ lati kọrin sii fun ogo rẹ".
- Ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ kí àláfíà jọba lórí orin "Oniduro Mi", ìyá ni Tope Alabi jẹ́ sí mi - Adeyinka Alaṣeyori
- Ẹ wo àwọn gbajúmọ̀ ìlú tó sọ̀rọ̀ tako èrò Tope Alabi nípa orin "Oniduro Mi"
- Tope Alabi fẹ́ tọ́ Olórin "Oniduro mi e ṣe" sọ́nà, bí ọ̀rọ̀ ṣe laná nìyìí
- Alaseyori kọ́ ló ni orin "Oniduro Mi", àmọ́ ìdí tí mi ò ṣe bá a jà pé ó jí orin mi kọ nìyìí - Tolu Adelegan
Si Ajihinrere TOPE ALABI,
"Ọlọ́run ti bukun rẹ pẹlu irufẹ ati ara ọtọ ẹbun orin too diidi jogun latọdọ Ọlọrun a si dupẹ pe o ṣe ọ ni olohun gbooro ninu ọgba ajara orin ẹmi".
Bamiloye ni oun mọ pe Ọlọrun ti yi ohunkohun to wu ti Eṣu fẹ da lara pẹlu iji ọhun pada lati pe akiyesi rẹ si ọdọ rẹ sii.
"Nibayii, afikun ọpọ ọrọ orin akọtun yoo tun wa latọrun wa lati bukun ijọ latara rẹ.
Ni ti Yinka Alaseyori, o ni oun gbagbọ pe Ọlọrun lo nkan ti Eṣu gbero lati ru iyalẹnu pada sori Eṣu. "Eṣu fẹ fi wọ ẹ wa silẹ ni amọ Ọlrun fi ru ẹ soke ni".
O ni laarin ọsẹ kan pere Ọlọrun jẹ ki orukọ rẹ gba agbaye kan ti awọn si bẹrẹ si ni wa orin rẹ ti wọn bẹrẹ si ni tẹle ọ lori Instagram ati Facebook. "Koda emi gan, mo lọ wa ẹ mo gbọ orin rẹ mo si ri i pe o rilẹ ti pẹ ti o ti n kọrin".
"Sugbọn ṣe mo tilẹ le mọ bi kii ṣe ti iji ti Ọlrun gba laye?
- Ṣé lóòtọ́ ni ilẹ̀ America ti bẹ̀rẹ̀ 'visa lottery padà fún àwọn ọmọ Naijiria? Wo àlàyé níbí
- Ìdí rèé tí a fí sọ fún àwọn ọmọ wa nípa bí wọ́n ṣe fí ipá bá ìya wọn lọ̀pọ̀ - Timi Dakolo
- Olùwọ́de EndSARS bímọ tuntun nínú ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tó ti lo oṣù mẹ́jọ ní àhámọ́
- Àwọn ọlọ́pàá máa ń yọ Baba Ijesha jáde látimọ́lé lálaalẹ́ - Princess
- Rahmon ń múra láti lọ rí ìyàwó àti ìbèjì tó bí ní US ni wọ́n bá pa á níbi ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ ní Iwo road
Oju opo Instagram rẹ to di tit pa, o gba aaye rẹ pada laarin ọsẹ kan ti o gba ọpọ ni ọpọlọpọ ọdun lati ri gba".
"Ọ̀SẸ̀ KAN PÉRÉ!
Aanu la n pe iyẹ."
Ṣugbọn o gba Alaseyori nimọran lati bu iyi fun Ọlrun pẹlu igbega ara ọtọ yii. Ko sin Ọlọrun sii ninu iwa irẹlẹ tinutinu rẹ. O si gbadura pe ko ma ṣi oreofe yii lo ati pe ko ba awọn akọrin ọrun kọrin nikẹyin.

















