Janet Jackson's Yoruba song: Tony Ade ti wọ́n bí sí Amẹ́ríkà ti fẹ́ padà wá Nàìjíríà, ìdí tó fi fẹ́ darí wálé rèé
"Emi ni mo ṣẹdaa orin akọwọle ti a ṣe ninu orin Janet Jackson, 'Made for Now' to sọ pe "asiko ọpẹ Janet de".
Idi ti Anthony fi ni awọn bẹrẹ ilu ati orin naa pẹlu "asiko ọpẹ Janeti de" lori gbajugbaja eto Jimmy Fallon Show ni pe ninu akọsilẹ, o ti to ọdun marun gbako ti Janet Jackson to jẹ gbajugbaja olorin ọmọ Amẹrika ti kọ orin lori itage tabi ṣe awo orin kankan jade leyi ti gbogbo agbaye mọ ọ si.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn oun aṣa ilẹ Afrika ati Yoruba to mu lo ninu fidio naa di ọrọ ti gbogbo ọmọ Naijiria tẹ sori igba ayelujara bayii.
Orin naa lo jẹ fidio orin akọkọ ti yoo gbe jade lati bi ọdun mẹta.

Oríṣun àwòrán, GT Afrodrum Ensemble/Instagram
Aarin fidio naa to ṣe pẹlu ọkunrin olorin Amẹrika t'orukọ rẹ n jẹ Daddy Yankee, ni wọn ti ṣe afihan ẹgbẹ onilu ọmọ Yoruba kan, GT Afrodrum Ensemble. Awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti wọn bi si orilẹede Amẹrika ṣugbọn ti wọn ko gbagbe orisun wọn ni awọn kọ bi wọn ṣe n lu Gangan, Omele, Bata, Iya Ilu, Dundun ati Ṣẹkẹrẹ ni ilu oyinbo.
Aburo ilumọọka olorin Michael Jackson yii ri ilu ati orin ti ẹgbẹ onilu Tony Ade ṣe nibi kan pẹlu gbogbo ohun elo orin bii bata, iya ilu, omele ati bẹẹ bẹẹ lọ lo wu u lori to si bẹrẹ si ni gfbe iṣẹ fun wọn to wa aye fun orin ati ilu Yoruba ninu orin oyinbo ti awọn oyinbo mọ ọ si.
Idi ti arakunrin yii ti wọn bi oun ati baba rẹ si oke okun ṣe fẹ pada wa tẹdọ si Naijiria lẹyin ọpọlọpọ ilu to ti lu fi ṣiṣẹ ni New York ya ni lẹnu. Alaye rẹ ree fun BBC Yoruba.

