Baba Ijesha Saga: Àwọn ọlọ́pàá máa ń yọ Baba Ijesha jáde látimọ́lé lálaalẹ́ - Princess

Oríṣun àwòrán, Princess
Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló ń reti ki Damilola Adekoya tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Princess comedian sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìsẹ̀lẹ̀ tuntun lórí ẹjọ́ Baba Ijesha.
Láipẹ́ yìí ni ẹbi Baba Ijesha kan ke gbàjarè nilé ẹjọ pé ìyà ti Baba Ijesha n jẹ látimọ́lé ti pọ̀ jù lórí ẹ̀sẹ̀ tí kò mọwọ́.
Ọmọbinrin náà fi kun pé, nítori Baba Ijesha kọ̀ lati fẹ Princess ni ó ṣe ko báa.
Ṣùgbọ́n ninu ìtàkurọ̀sọ kan ti Damilola Adekoya ṣe Esther Aboderin (ESABOD) lo ti ṣàlàyé pé ko si ìyà kankan ti wọn fi n jẹ Baba Ijesha látìmọ́lé.
Ó ni ọ̀rọ̀ tí kò ni ìtumọ̀ rárá ni ọmọbinrin náà ń sọ nítorí ọ̀nà wo ni ó fi mọ̀ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wáyé, ṣé àwọn méjèjì ni Baba Ijesha ń bá sùn papọ̀ ní?
Princess ni ọ̀rọ̀ ti kò mú ọpọlọ dání ni ọ̀rọ̀ ọmọbinrin náà ń sọ, àti wípé, ẹni tí wọ́n ń tórí rẹ̀ sọ́rọ̀ gan fúnra rẹ̀ ń bẹ̀bẹ̀, àwọn ń pariwo kiri.
Princess fẹ̀sùn kan pé tí àwọn ọgá ọlọ́pàá bá ti lọ ilé bi aago mẹ́sàn alẹ́, àwọn ọlọ́pàá má n mú Baba Ijesa jáde láti pààrọ aṣọ, ti ó sì máa n ṣe bi ó ṣe wù ú.
Ó ní bí wọ́n ṣe n ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún tó òun kò bínú, "ṣùgbọ́n mo wòó pé, ibi ti ènìyàn kò sí Ọlọ́rùn wà níbẹ̀.
"Bí Baba Ijesha ṣe wà ní àháma ló n rán àwọn eǹìyàn sí mi láti bẹ̀bẹ̀, èyí tí Idowu Philips ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Iya Rainbow wà lára wọn.
" Nǹkan tí wọn kọ́kọ́ sọ ni pé Baba Ijesha ní kí maa bẹ̀ ẹ́, olóòre mi ni, mo fẹ́ kí ẹ bá mi bẹ Princess, alaanu mi ló jẹ́ mo dẹ̀ ti ṣẹ̀ ẹ́, kó dárí jì mí.
Princess ni òun sọ fún Iya Rainbow, pé kí wọ́n jọ pé àgbalagbà ni wọn òun kò sì fẹ̀ ṣẹ̀ nítorí ò ń bọ̀wọ̀ fún un.
Gbájúgbajà òṣèré náà fi kun pé, òun sọ fún iya Rainbow pé ó ni láti sọ nnkan tó ṣe, sùgbọ́n nígbà tí òun yóò fi parí alàyé pẹ̀lú Iya náà fẹ́ dákú ni.
"Nígbà ti mo ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fún Shokoti àti Olaiya Igwe, Olaiya ń gbọ̀n ni, àti pé ó ni àwọn ọ̀rọ̀ kan tí kò ṣee sọ síta lórí afẹ́fẹ́, ṣùgbọ́n ó pọn dandan kí n sọ fún wọn.

















