Alberto Sánchez Gómez: Bí ọkùnrin kan ṣe dèrò ẹ̀wọ̀n ọdún 15 lẹ́yìn tó pa ìya rẹ̀ tó sì tún sè é sí ọbẹ̀ jẹ

Ọlọpaa ati ọdaran naa

Oríṣun àwòrán, Spanish police

Arakunrin kan lati ilẹ Spain ti ri ẹwọn ọdun marundinlogun he lẹyin to pa iya rẹ to si tun se e jẹ.

Ọdun 2019 ni ọwọ ọlọpaa tẹ arakunrin Alberto Sánchez Gómez, lẹyin ti wọn ri ẹya ara ni agbegbe ile iya rẹ, ti wọn si tun ba awọn ẹya ara kan ninu ike.

Ileẹjọ ko lati gba ọrọ Sanchez gbọ pe niṣe lo ni arun ọpọlọ lasiko to wu iwa buruku bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Baba Ijesha Rape Case: Yomi Fabiyi ní òun nìkàn lòun rí ara òun tó dúró tí Baba Ijesha

Nibayii, ọdun marundinlogun ni yoo lo ni ọgba ẹwọn fun ẹsun ipaniyan pẹlu oṣu marun un miran fun ṣiṣẹ ara oku basubasu.

Bakan naa ni wọn ni ko fun iya rẹ ni ibatan rẹ ni iye owo to to €60,000 ($73,000, £52,000) gẹgẹ bi iye owo itanran.

Oṣu Keji, ọdun to kọja ni ileeṣẹ ọlọpaa jawọ ile Sanches ni agbegbe Madrid, lẹyin ti ọrẹ rẹ kan kegbare nipa alaafia iya Sanches, iyẹn María Soledad Gómez,ti o ti le ni ọgọta ọdun.

Lasiko igbẹjọ naa ni wọn sọ fun ileẹ̣jọ wi pe niṣe ni Sanchez to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn yii ọrun iya rẹ pa.

Lẹyin naa ni ọmọkunrin naa ge ẹya ara rẹ yalayala, ti o si se e jẹ fun ọsẹ meji, to si fifun aja rẹ naa.

Ileeṣẹ iroyin ni orilẹede Spain ni awọn to mọ arakunrin Sanches daadaa ni ọpọlọpọ igba lo ti ba iya rẹ ja, ti ọlọpaa si tii mọ ile rẹ pe ko gbọdọ de ọdọ iya rẹ mọ.

Àkọlé fídíò, Ṣé ìrìnàjò nínú ọkọ̀ Reluwé Ibadan-Lagos-Ogun tuntun bá aráàlù lára mu? Èsì rèé