Wo bí àbẹ̀wò Ààrẹ Muhammadu Buhari sí Borno ṣe lọ

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe àbẹ̀wò si ipinlẹ Borno, to si ba awọn ọmọ ogun to wa loju ija nibẹ sọrọ.
Oṣu Keji, ọdun 2020 ni Aarẹ lọ si ipinlẹ naa kẹhin, nibi ti awọn eniyan ti pariwo "Ba Mayi, ba mayi" ( ao ṣe, ao ṣe mọ) le lori lasiko to n jade ni aafin Emir ìlú Maiduguri.
Ọjọbọ ni Buhari ṣe àbẹ̀wò ọlọjọ kan, nibi to ti gúnlẹ̀ si ibudo awọn ọmọ ogun ofurufu to wa niluu Maiduguri ni nkan bi aago mẹwa owurọ.
Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum ati awọn Ọga Agba lẹ́nu isẹ ijọba lo si wa nibẹ lati gbalejo rẹ.
Lasiko àbẹ̀wò naa ni Aarẹ ti ba awọn ọmọ ogun sọrọ ni olu ibudo Operation Hadin Kai, ati ọ̀wọ́ keji ileesẹ ologun Naijiria to wa ni Malari Cantonment, Maiduguri.
Ninu ọrọ si awọn ọmọ ogun, Aarẹ sọ pe oun ki wọn fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe lati ri i pe Naijiria ko ṣubú si ọwọ àwọn ọta rẹ.

Bakan naa lo ni oun daro iku àwọn ọmọ ogun to ti ku si oju ija igbogun ti igbesunmọmi.
O ni ijọba oun ti n ṣe atunse awọn irin'ṣẹ ologun to ti ba jẹ, to si tun ti ra awọn tuntun mii to, eyi to dé si Naijiria laipẹ yii.
O sọ pe akitiyan wọn lo mu ki alaafia jọba ni Ìwọ̀ Òòrùn Ariwa Naijiria, pẹlu bi wọn ṣe kapa àwọn agbesunmọmi ninu igbo Sambisa, Timbuktu Triangle ati agbegbe Lake Chad.
Yatọ si eyi, Aarẹ sọ pe ijọba ti n gbe igbesẹ lati mu ki awọn eeyan agbegbe naa pada sipo.
- Gani Adams kọ lẹ́tà sí àjọ UN, AU, US lórí ààbò tó mẹ́hẹ àti ìpànìyàn darandaran
- Ṣé Princess lè sọ fáráyé iye ìgbà tó ti bọ́ aṣọ sí ìhòhò níwájú Baba Ijẹsha? -Mọlẹbi baba Ijẹsha gbarata
- Nǹkan tí a mọ̀ nípa ìlera Asiwaju Ahmed Tinubu
- Ayédèrú òṣìṣẹ́ ìjọba ni Baba Ijesha fà kalẹ́ ló jẹ́ kó ṣì wà láhámọ́ - Ọlọ́pàá
Bakan naa ni Aarẹ Buhari tun ṣe ifilọlẹ àwọn iṣẹ́ akanse bi ẹgbẹrun mẹrin ile ti ijọba apapọ kọ si Maiduguri, ati awọn àkànṣe iṣẹ diẹ ti ijọba ipinlẹ naa ṣe.
Ninu atẹjade kan to ti kọkọ fi sita, ni ijọba ipinlẹ Borno ti sọ pe aarẹ yoo ṣe ifilọlẹ abala akọkọ ile ẹgbẹrun mẹwa ti ijọba apapọ gbọ bukaata rẹ fún awọn ti ogun Boko Haram sọ di alainilelori ati atipo.
Gomina Zulum sọ pe kikọ àwọn ile naa lo jẹ iru rẹ to tobi julọ ninu awọn ti ijọba apapọ ṣe si awọn ipinlẹ ni Naijiria.
- Ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ kí àláfíà jọba lórí orin "Oniduro Mi", ìyá ni Tope Alabi jẹ́ sí mi - Adeyinka Alaṣeyori
- Ojúbọ irúmọlẹ̀ tó jẹ́ ibùdó ìdìbò àti ìbùdó 740 ayédèrú míì gba ìwọ́gilé INEC
- Ìjọba Saudi dájọ́ ikú fún ọ̀dọ́ kan lórí ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ láti kékéré, ìdí rèé
- Mo rí òkú TB Joshua tó yọ sí mi lẹ́yìn ikú rẹ̀ - Jaiye Kuti














