Kenneth Kaunda: Àárẹ àkọ́kọ́ ní Zambia jáde láyé lẹ́ni ọdún 97

Kenneth Kaunda, Aarẹ akọkọ ni orilẹ-ede Zambia ti jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọrun.
Yatọ si pe oun ni Aarẹ akọkọ ni Zambia, o jẹ ọkan lara awọn olori nilẹ Africa to ku saye lara awọn to kọjú ija si awọn oyinbo amunisin.
Ọjọ Aje ni wọn gbe Kaunda lọ sileewosan àwọn ologun to wa ni olu ilu orilẹ-ede naa, Lusaka, nitori aisan otutu aya, pneumonia to n se e.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho ní agbébọn tí kò bá kúrò nínú igbó Yorùbá láti ọjọ́ Aje rugi oyin
- Iyabo Ojo bẹ̀rẹ̀ ìjà rọ̀fọ̀rọ́fọ̀ pẹ̀lú máníjà rẹ̀ tẹ́lẹ̀ lórí ẹ̀sùn olè jíjà
- Wo ikọ̀ aláàbò tuntun tí yóò gba iṣẹ́ ọlọ́pàá SARS ṣe l'Eko
- N5M ni a pàdánù lásìkò tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo lé wa kùró ní Sabo - Àwọn oníbárà
- Àwọn agbébọn ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ míì gbé lọ ní Kebbi
- Àjinigbé pa ọmọ méjì wọ́n ji méjì gbé lọ tí wọ́n jẹ́ ọmọ òbí kan ni Ondo
- Ṣé Princess lè sọ fáráyé iye ìgbà tó ti bọ́ aṣọ sí ìhòhò níwájú Baba Ijẹsha? -Mọlẹbi baba Ijẹsha gbarata
Awọn amugbalẹgbẹ rẹ sọ pe ko ni aarun Covid-19.
Ni nkan bi ọdun 1950, pataki ni Kaunda ko ninu ija ominira fun orilẹ-ede Northern Rhodesia (Namibia) kuro lọwọ ijọba Gẹẹsi.
O si di aarẹ lẹyin ti wọn gba ominira lọdun 1964. Ọpọlọpọ ọdún si lo fi dari orilẹ-ede naa lábẹ́ asia ẹgbẹ oṣelu United National Independence Party (UNIP).
O fi ipo silẹ lọdun 1991 lẹyin to fidi rẹmi ninu idibo gbogbogboo.
Ọmọ rẹ ọkùnrin, Kambarage, to kede iku rẹ loju opo Facebook sọ pe "ẹ jẹ ki a gbadura fún".
Bakan naa ni aarẹ orilẹ-ede naa, Edgar Lungu sọ pe orilẹ-ede oun n ṣọ̀fọ̀ "akọni ilẹ Africa tootọ".

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kọ si oju opo Facebook rẹ pe pẹlu ibanujẹ ni oun fi gba iroyin iku rẹ.
"Mo gbadura ni orúkọ gbogbo eniyan orilẹ-ede yii, ati ara mi pe ki ẹbi Kaunda ri itunu gba, bi a ṣe n daro aarẹ akọkọ ati akọni ilẹ Africa tootọ."
Kaunda- ti ọpọ mọ si KK- jẹ ọkan lara awọn to ṣe atilẹyin fun ija ominira àwọn aláwọ̀ dudu ni South Africa.
O tun satilẹyin fun wọn ni Mozambique, to ti di Zimbabwe bayii. Lẹyin ọpọlọpọ ọdún, Kaunda gbájúmọ́ igbogun ti HIV, lẹyin ti aarun Aids pa ìkan lara awọn ọmọ rẹ òkunrin, Masuzyo.












