Lagos police: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Eko bẹ̀rẹ̀ ìdánilẹ́kọọ̀ọ́ fún ikọ̀ ATRS tí yòó gba iṣẹ́ ọlọ́ọ̀pá SARS ṣe

Awọn ọlọpaa duro wamu

Oríṣun àwòrán, lagos police command

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti gbe ikọ tuntun kalẹ ti yoo maa gbogun ti idigunjale loju popo ni ipinlẹ Eko.

Orukọ ikọ naa ni Anti Traffic Robbery Squad ti yoo maa gbogun ti idigunjale loju popo paapaa lasiko ti sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ba wa.

Kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Hakeem Odumoṣu ti paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa ikọ naa bẹrẹ idanilẹkọ ati igbaradi.

Kọmiṣọna ọlọpaa Odumoṣu ni laarin oṣu kẹta si asiko yii, ko din ni eeyan mẹtadinlaadoje ti ọwọ ti ba gẹgẹ bi afurasi adigunjale inu sunkẹrẹ-fakẹrẹ nipinlẹ Eko.

O fikun pe ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti dide ija si awọn ole to n gba tọwọ oninkan ninu sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ.

Àkọlé fídíò, Baba Ijesha Rape Case: Yomi Fabiyi ní òun nìkàn lòun rí ara òun tó dúró tí Baba Ijesha

Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Olumuyiwa Adejọbi fi sita, o ni kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Eko ti fi aṣẹ sii pe ki idanilẹkọ oloorekoore o maa waye fun awọm ọlọpaa ni ipinlẹ naa.

O ni eyi jẹ ara ọna ati lee jẹ ki wọn wa ni igbaradi fun gbogbo ipenija abo to ba n waye nipinlẹ naa.