Kebbi Students kidnapping: Àwọn agbébọn ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ míì gbé lọ ní Kebbi

Aga ileewe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Kebbi sọ pe awọn agbebọn kan ti ji awọn ọmọ ile ẹkọ kan gbe lọ.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, awọn agbebọn naa ya bo ile ẹkọ ọhun to wa niluu Yawuri ti wọn si ji awọn akẹkọọ gbe lọ lẹyin ti wọn ti kọkọ kọju ija si awọn agbofinro.

Agbẹnusọ kan fun ijọba ipinlẹ naa ṣalaye fun BBC pe awọn ti bẹrẹ si n ka awọn akẹkọọ to ku ki wọn le mọ iye akẹkọọ ti wọn ji gbe lọ ni pato.

A n se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ. Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.

Àkọlé fídíò, Baba Ijesha Rape Case: Yomi Fabiyi ní òun nìkàn lòun rí ara òun tó dúró tí Baba Ijesha