Oyo beggars: Agbègbè tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo kó wa lọ báyìí kò tẹ́ wa lọ́rùn - Àwọn oníbárà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn onibaara to wa lagegbe Sabo, niluu Ibadan ti ijọba ipinlẹ Oyo ko kuro nibi ti wọn wa tẹlẹ ti sọ pe igbesẹ naa ti jẹ ki awọn padanu owo ti iye rẹ tí ko din ni miliọinu marun un naira.
Lara awọn ti wọn ko kuro ni Sabo ni a ti ri afọju, arọ atawọn mii to n tọrọ baara nibẹ.
Awọn eeyan naa sọ pe bi ijọba ipinlẹ Oyo ṣe le wọn kuro nibi ti wọn wa ni pajawiri lo jẹ ki awọn padanu owo naa.
Nigba ti ọkan lara awọn eeyan naa, to tun jẹ olori awọn afọju, Ibrahim Muhammad, n ba awọn akọroyin sọrọ, o ni ijọba Oyo ko sọ fun awọn ṣaaju pe wọn n gbe igbesẹ lati le awọn kuro nibi ti wọn wa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, "Wọn kan dede wa sọdọ wa ni, ti wọn si sọ fun wa pe ki a fi Sabo silẹ."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Bo tilẹ a bẹ wọn titi ki wọn fun wa ni akoko diẹ lati palẹmọ, ṣugbọn awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn ran niṣẹ ọhun kọ jalẹ."
"Niwọn igba to jẹ pe aṣẹ ijọba ni wọn tẹle, ko si nnkankan ti a le ṣe. Ka ma fa ọrọ gun, iye owo ti a padanu ko le din miliọnu marun un si mẹfa."
Muhammad ṣalaye pe ijọba ipinlẹ Oyo fi ẹtọ awọn dun wọn gẹgẹ bii ọmọ Naijiria nitori wọn ko ta awọn lolobo tẹlẹ wọn n bọ wa le awọn onibaara naa kuro ni Sabo.
Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Oyo ti kọkọ kede pe awọn yoo ko awọn onibaara kuro laarin igboro si ibi ti wọn ṣeto fun wọn lagbege Akinyele.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ gomina Seyi Makinde, Taiwo Adisa fi ṣowọ si awọn akọroyin, o ni awọn ti bẹrẹ igbesẹ ọhun lati nnkan bii oṣu melokan sẹyin.
Adisa fi kun awọn yoo ṣe abẹwo si agbegbe naa pẹlu awọn adari ẹgbẹ Arẹwa, to fi mọ awọn aṣoju awọn onibaara nipinlẹ Oyo.
- Ṣé Princess lè sọ fáráyé iye ìgbà tó ti bọ́ aṣọ sí ìhòhò níwájú Baba Ijẹsha? -Mọlẹbi baba Ijẹsha gbarata
- Nǹkan tí a mọ̀ nípa ìlera Asiwaju Ahmed Tinubu
- Ayédèrú òṣìṣẹ́ ìjọba ni Baba Ijesha fà kalẹ́ ló jẹ́ kó ṣì wà láhámọ́ - Ọlọ́pàá
- Ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ kí àláfíà jọba lórí orin "Oniduro Mi", ìyá ni Tope Alabi jẹ́ sí mi - Adeyinka Alaṣeyori
- Ojúbọ irúmọlẹ̀ tó jẹ́ ibùdó ìdìbò àti ìbùdó 740 ayédèrú míì gba ìwọ́gilé INEC
Ẹwẹ, awọn onibara naa sọ pe ijọba ko bun awọn gbọ tẹlẹ, ati pe ibi ti ijọba Oyo ṣeto fu wọn ni Akinyele bayii ko tẹ awọn lọrun.
Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, awọn araalu kan ti lọ ja ṣoọbu awọn, wọn si tun ti ji awọn dukia ti awọn fi silẹ nigba ti ijọba Oyo ni ki wọn kẹru wọn tipa-tikuku.
- Ìjọba Saudi dájọ́ ikú fún ọ̀dọ́ kan lórí ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ láti kékéré, ìdí rèé
- Mo rí òkú TB Joshua tó yọ sí mi lẹ́yìn ikú rẹ̀ - Jaiye Kuti
- Wòlíì Genesis fèsì lórí ọ̀rọ̀ Tope Alabi nípa orin 'Oniduromi'
- Iyabo Ojo tún sọ òkò ọ̀rọ̀ sáwọn òṣèré tíátà nínú fídíò tuntun tó gbé síta
- A ó sọ ibùdókọ̀ ojú irin ìlú Ibadan di gbàgede káràkátà láìpẹ́ - Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo















