Ibadan train station: A kò lágbára láti yí àkókò tí ọkọ̀ reluwé ń gbéra kúrò nílùú Ibadan - Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Ijọba ipinlẹ Oyo ti sọ pe awọn ti n ṣeto lati sọ agbegbe Moniya di gbagede karakata niluu Ibadan lẹyin ti Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe ifilọleẹ papakọ ọkọ oju iri nibẹ.

Kọmiṣọna fun iṣẹ ode ati eto irinna ni ipinlẹ naa, Ọjọgbọn Dahud Kehinde Shangodoyin lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.

Shangodoyin sọ pe ijọba ipinlẹ Oyo ti gbero bi awọn yoo ṣe ko awọn ọkọ kan si agbege naa, eyii ti yoo maa ko awọn ero lati Moniya ti ibudokọ oju irin naa wa lọ si aarin igboro.

O ṣalaye pe ijọba ipinlẹ Oyo ti n gbero bi awọn yoo ṣe sọ agbegbe naa di gbagede karakata, ninu eyii ti awọn araalu naa yoo ti maa ṣowo-jere, yatọ si pe ijọba n pa owo wọle nibẹ.

O ni "Ti ẹ ba de awọn orilẹ-ede nla nla kaakiri agbaye, e o ri awọn gbagede karatakata to sun mọ ibudokọ oju irin, iru rẹ ni ijọba Seyi Makinde fẹ ṣe siluu Ibadan."

"To jẹ pe ti eeyan ba de ibudokọ naa tan, yoo ri oniruru ọkọ ti yoo gbe lọ si ibikibi to ba n lọ, yala ọkọ aladani ni o tabi ti ijọba."

Àkọlé fídíò, 'Ọwọ́ mi ti ń jẹ́rà ká tó mọ̀ pé àfi kí wọ́n tún gé e bí mo bá ṣì fẹ́ máa ṣe iṣẹ́ awakọ̀ lọ'

Ọjọgbọn naa ṣalaye pe ti awọn ba ti bẹrẹ awọn akanbṣẹ iṣẹ naa, gbogbo awọn nnkan meremere to yẹ ko wa ni ibudokọ oju irin ni yoo wa ni Moniya.

Yatọ si awọn ọkọ akero, o ni awọn tun yoo tun kọ ibudoko ti awọn awọn arinrinajo yoo ni anfaani lati maa gbe ọkọ wọn si ki wọn to pada de lati irinajo wọn, ti aabo to peye yoo si wa lori irufẹ ọkọ bẹẹ, ṣugbọn o ni awọn araalu yoo ni lati ni suuru fun igba diẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "Gomina ti ṣeleri fun awọn eeyan to wa ni agbegbe naa pe wọn yoo ri iyatọ laipẹ yii nitori ijọba yoo sọ agbegbe ọhun di gbagede karakata ti gbogbo nnkan amayedẹrun ni yoo si wa nibẹ."

Nigaba to n sọrọ lori awọn akoko ti ọkọ oju irin reluwee yoo maa gbera kuro niluu Ibadan ati akoko ti yoo maa pada de, Shangodoyin sọ pe awọn ko lagbara lati yi awọn akoko naa pada.

Ṣaaju ni awọn eeyan kan ti kọkọ n sọ pe akoko ti ọkọ oju irin naa maa n gbera ko pe awọn, ṣugbọn o ni awọn ko lagbara lori awọn akoko naa nitori ko si ni ikawọ awọn.

Àkọlé fídíò, 'Sister Tope Alabi yà mí lẹ́nu gan o pé "Oniduro mi" kìí ṣe orin tó yẹ kí ọlọ́run fún mi'

Shangodoyin pari ọrọ rẹ pe awọn yoo dari awọn ọkọ ti yoo maa ko ero lati papakọ oju irin naa lọ saarin ilu laipẹ.

Ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹfa, ọdun yii ni Aarẹ Muhammadu Buhari ṣi ibudokọ ọkọ oju irin naa

Àkọlé fídíò, 'Walahi kìí ṣe irọ́ pé Fulani ń dá àwọn èèyàn lọ́nà nílẹ̀ Yorùbá, ìrírí mi rèé'
Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are