Twitter ban in nigeria: Kò bá òfin mu bí ìjọba Naijiria ṣe gbẹ́sẹ̀lé Twitter - Ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ́

Oríṣun àwòrán, ANC 24/7
Awọn ẹgbẹ ajafẹtọ bii aadọrin ti ke si ijọba apapọ lati yi igbesẹ rẹ pada lori bo ṣe fofin de lilo ẹrọ Twitter ni Naijiria.
Wọn tun ke si ijọba apapọ lati ma ṣe gbe ẹnikẹni ninu awọn to tapa si ofin naa lọ sile ẹjọ.
Ninu atẹjade kan ti awọn eeyan naa buwọlu, ti wọn si fi ṣọwọ si awọn akọroyin, wọn ni igbesẹ ti ijọba apapọ gbe ko ba ofin mu.
Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ "Inu wa bajẹ gidigidi bi ijọba Naijiria ṣe n tẹ ẹtọ awọn araalu loju mọlẹ, paapaa ominira lati ṣorọ bo ṣe wu wọn."
"A fẹ sọ ni gbangba pe a ko fọwọ si bi ijọba apapọ ṣe fofin de oju opo Twiter ni Naijria, eyii ti ko gba awọn eeyan laaye lati sọ erongba wọn lori ayelujara."
Ẹgbẹ naa tun bu ẹnu ẹtẹ lu aṣẹ ajọ to n ri si ọrọ igbohunsafẹfẹ ni Naijiria, NBC, to sọ pe ki gbogbo awọn ileeṣe iroyin yọ ara wọn kuro loju opo Twitter.
Wọn ni "A rọ ijọba Naijiria lati yi aṣẹ rẹ pada lori ofin to fi de Twitter nitori aṣẹ naa ko ba ofin mu, to fi mọ igbeṣẹ lati fi panpẹ ofin mu gbogbo awọn to n tapa si aṣẹ ọhun."
Ẹgbẹ naa tun ni ki ijọba yi aṣẹ rẹ pada lori bo ṣe ni ki awọn ileeṣẹ iroyin yọ ara wọn kuro loju opo Twitter.
Lẹyin naa ni wọn rọ ijọba Naijiria lati ronupiwada lori iwa familete ki n tutọ to n wu, paapaa bo ṣe kan awọn araalu ati ẹtọ wọn labẹ ofin.
Wọn tun ke si ajọ iṣọkan agbaye, UN, ati ajọ iṣọkan ilẹ Afrika, AU, lati bu ẹnu ẹtẹ lu aṣẹ ijọba Naijiria lori Twitter.
Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, oju opo ikansiraẹni lori ayelujara ti ran ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lọwọ lati mọ ohun to n lọ kaakiri agbaye, eyii to tun gba wọn laaye lati jẹ ki ijọba mọ ibi to ku si ninu ojuṣe rẹ.
Lara awọn ẹgbẹ ajafẹtọ to buwọlu atẹjade naa ni ẹka Amnesty International ni Naijiria, Global Rights, Nigeria Mourns, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
- Wo oríadé méje tí ẹ̀ṣùn ìwà ìjínigbé ṣí mọ́ lórí
- Wọ́n gbé Bobrisky dìgbà-dìgbà padà sílé ìwòsàn lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ ìdí
- Àsìkò tó fún Buhari láti kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ - Ìgbìmọ̀ Àgbààgbà Yorùbá
- Ṣé lóòtọ́ ni pé ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú ṣèèsì ju àdó olóró síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan?
- Ọká fóó! Oníṣègùn tó gba 250M owó ẹbọ lọ́wọ́ aláìsàn kó sọ́wọ́ EFCC















