Kidnapping in Nigeria: Wo oríadé méje tó kúrò nípò torí ẹ̀ṣùn ìwà ìjínigbé

Awọn oriade ti wọn fi ẹsun kan pe o lọwọ ninu iwa ijinigbe lagbegbe wọn

Oríṣun àwòrán, Facebook

Wahala ipenija aabo to de ba tolori tẹlẹmu lorileede Naijiria ko yọ ẹkun kankan silẹ.

Lawọn ipinlẹ kọọkan, n se ni awọn ijọba n gbogun ti awọn ti wọn ba n lẹdi apo pọ pẹlu awọn ajinigbe naa.

Ọrọ yii le to bẹẹ gẹ debi pe awọn eeyan n naka aleebu si awọn oriade kọọkan, paapaa ni apa Ariwa Naijiria, pe wọn n ba àwọn ajinigbe ṣe papọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni ipinlẹ Zamfara ati Katsina, ẹsun ijinigbe peleke lodọ awọn oriade, tijọba Zamfara si pàṣẹ pe kí ọba kan to jẹ Oriade onipo gíga, lọ rọọkun nile lọsẹ to kọja nitori pe o ni ohun ṣe pẹlu awọn ajínigbe.

Wonyii si ni orúkọ awọn oriade ti akọsilẹ fi ẹsun kan pe wọn mọ nipa ijinigbe ni apa Ariwa Naijiria:

Sarkin Zurmi

Emir ilu Zurmi Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Zurmi Atiku Abubakar/Facebook

Emir ilu Zurmi Atiku Abubakar ni Oriade ti wọn fẹsun kan pe o mọ nipa ijinigbe to n waye lagbegbe rẹ, tí ìjọba si ni ko lọ rọọkun nile na.

Ṣaaju ni Gomina Bello Matawalle ṣe agbekalẹ igbimọ iwadii kan, ti wọn si fẹnu ko pe ọba yii mọ nipa ijinigbe to n waye labẹ rẹ.

Igbakeji Gomina Ibrahim Wakkala lo dari igbimọ naa, ti wọn si pasẹ pe ki Oloye Bunun Kanwa, Bello Suleiman máa ṣe akoso ilu.

Àṣẹ lọ rọọkun nile yii ko sẹyin bi awọn ajinigbe ṣe kọlù abule Kadara nibi ti o kere tan, eeyan ọgọrun padanu ẹmi wọn.

Sarkin Dansadau

Emir ilu Dansadau, Hussaini Umar

Oríṣun àwòrán, Emir Dansadau, Hussaini Umar/Facebook

Emir ilu Dansadau, Hussaini Umar naa wa lara awọn oriade ti wọn pàṣẹ ko lo rọọkun nile ni Zamfara.

Ni ọjọ kini oṣu Kẹfa, Gomina Bello Matawalle ni ko kuro lori apere fún ìgbà die, lori ẹsùn pe o n bawọn janduku agbébọn ṣe.

Dansadau Nasiru Muhammad Sarkin Kudu lo gba ipo rẹ lati máa ṣe akoso ilu.

Gomina Matawalle tun gbe igbimọ kalẹ, ti ọgá àgbà ọlọpaa to ṣiṣẹ feyinti, Mohammad Ibrahim Tsafe dari rẹ.

Igbimọ naa si lo wadii ẹsun ti wọn fi kan oriade ọhun.

Sarkin Maru

Emir Maru, Abubakar Chika

Oríṣun àwòrán, Emir Maru, Abubakar Chika/Facebook

Sarkin Maru ni Oriade akọkọ ti ijọba Zamfara yóò yọ kuro lori oye.

Ni oṣù Kẹjọ ọdun 2019, Matawalle yọ Emir Maru, Abubakar Chika lori ẹsun pe o dalẹ awọn araalu nipa lilẹdi apo pọ pẹlu awọn janduku ajinigbe lati ji awọn araalu gbe.

Agbẹnusọ Oriade yii ni, ko si nkan tó jọ bẹẹ, to sì tàkò ẹsun ọhun.

Yatọ sí àwọn Oriade ta ka silẹ yii tun wọn yọ awọn baalẹ kọọkan náà lori ẹsun pe wọn mọ nipa ijinigbe l'agbegbe wọn.

Ninu wọn la ti ri :

Baalẹ abule Kanoma:

Olori Ilu Kanoma ni ijoba ibilẹ Maru ni ipinlẹ Zamfara, Alhaji Lawal Ahmad náà gba aṣẹ lọ rọọkun nile lori ẹsun pe o mọ nipa ijinigbe.

Iwadii ti igbimọ tijọba gbe kalẹ lori ẹsun ijinigbe ti wọn fi kan baalẹ naa, ṣe ṣafihan pe Lawal Ahmad ati Emir Maru, Abubakar Chika n dijọ lẹdi apo pọ gba owo ìdóòlà fun awọn ajinigbe.

Nasarawa Mailayi

Oloye Nasarawa Mailayi, ti orukọ rẹ n je Bello Kiyawa ati Emir ilu Zurmi, ni won ni ko lọ sinmi nile lori ẹsun pe wọn n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ajinigbe.

ìjọba ni Emir yii n lẹdi apo pọ pẹlu awọn ajinigbe janduku to buru julọ lagbegbe naa.

Ilu Zurmi wa leti ibode pẹlu Katsina, ti awọn agbébọn ajimaalu sì máa n da wọn láàmú níbẹ.

Àkọlé fídíò, 'Sister Tope Alabi yà mí lẹ́nu gan o pé "Oniduro mi" kìí ṣe orin tó yẹ kí ọlọ́run fún mi'

Seriki Yakin Kanwa ati Marafa Bakura:

Losu kinnin ọdun 2020, ijọba ipinlẹ Zamfara fi ofin de awọn Seriki meji nijọba ibilẹ Bakura ati Zurmi.

Ijọba ni ki Alhaji Bello Garba Kanwa, tii se Seriki abule Kanwa ati Alhaji Muhammad Bello Yusuf, tii se Marafa abule Bakura.

Gẹgẹ bi ijọba ipinlẹZamfara ti wi, o ni oun ni kawọn olori mejeeji lọ rọọkun nile na nitori ẹsun aigbọran ati atako taarata sawọn eto ti ijọba gbe kalẹ.

Awọn ẹsun miran tijọba tun fi kan wọn ni dida si ọrọ oselu, ẹsun ikowojẹ, iwa ajẹbanu ati sise owo ilu basubasu.