EFCC arrests Juju priest: EFCC fi ṣìkún òfin mú Oníṣegùn tó lu aláìsàn ní jìbìtì

Oríṣun àwòrán, officialefcc
Ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ni Naijiria, EFCC, ti fi ṣikun ofin mu oniṣegun kan, Abayomi Kamaldeen Alaka, ti ọpọ eeyan mọ si Awiṣẹ.
EFCC fẹsun kan Awiṣẹ pe oun ni baba isalẹ awọn onijibiti ti wọn n fi ojubọ kan to wa niluu Ashipa, lẹba Abokuta lu awọn eeyan ni jibiti.
Ọwọ tẹ Awiṣẹ lẹyin ti awọn eeyan kan fi ọrọ rẹ sun EFCC pe o lu obirin kan, Bright Juliet, ni jibiti owo ti iye rẹ to igba miliọnu naira atabọ.
- Alaseyori kọ́ ló ni orin "Oniduro Mi", àmọ́ ìdí tí mi ò ṣe bá a jà pé ó jí orin mi kọ nìyìí - Tolu Adelegan
- Kò sí olùfẹ̀hónúhàn kankan ní àhámọ́ ọlọ́paà nítorí ìwọ́dé June 12 - Frank Mba
- Sunday Igboho kan sárá sáwọn ọmọ Yorùbá tó wọ́de lọ́jọ́ Sátidé, ṣùgbọ́n kò sọ ìdí tí kò fi jáde
- Agbára bọ́ lọ́wọ́ Benjamin Netanyahu, Naftali Bennett di olótú ìjọba tuntun ní Israel
- Tope Alabi fẹ́ tọ́ Olórin "Oniduro mi e ṣe" sọ́nà, bí ọ̀rọ̀ ṣe laná nìyìí
Wọn ni Awiṣẹ fi ọna ẹburu gba owo naa lọwọ Juliet lẹyin to parọ fun yoo gbe ẹbọ kan ati bọ lọwọ aisan kan to n yọ ọ lẹnu.
Gẹgẹ bii atẹjade ti EFCC fi lede loju opo Instagram wọn, obinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Akinola Bukola Augustina, ti awọn eeyan mọ si Iya Osun lo mu Juliet lọ si ọdọ Awiṣẹ nitori aisan to n ṣe.

Oríṣun àwòrán, officialefcc
Iroyin ni Augustina lo kọkọ ṣeleri fun Juliet pe oun yoo wo aisan rẹ san to ba le san miliọnu mẹrindilogun naira, ṣugbọn lẹyin ti ara rẹ ko da lo mu lọ si ọdọ awọn miran ti wọn jọ n lu jibiti, ki ọrọ to kan Awiṣẹ.
Lara awọn ti EFCC mu lori ẹsun jibiti naa ni Sani Mohammed, to maa n ṣẹ owo ilẹ okeere ati Akinola Bukola Augustina lagbegba Egbeda ati Abule Egba nipinlẹ Eko.

Oríṣun àwòrán, officialefcc
Augustina yii lo mu awọn ọtẹlẹmuyẹ EFCC lọ si ọdọ Awiṣẹ ki ọwọ to tẹ oun naa.
Lara awọn dukia ti EFCC gbeṣẹle lọwọ awọn afurasi naa ni ilẹ nla kan to wa ni Ashipa, niluu Abeokuta eyii ti Awiṣẹ fi n lo gẹgẹ bii ojubọ rẹ.
Bẹẹ naa ni EFCC tun gbẹsẹle ile epo ati ọpọlọpọ awọn ile miran lagbegbe Ikorodu ati Magodo niluu Eko.

















