Olusegun Obasanjo: Àwa ìgbìmọ̀ tó ń wá ire Nàíjíríà ṣèpàdé, àbọ̀ ń bọ̀ láìpẹ́

Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, other

Ọrọ ti jade nipa ipade ti awọn alẹnulọrọ nilẹ yii, ti wọn pe ara wọn ni igbimọ majẹobajẹ to n wa ire Naijiria (Committee for the Goodness of Nigeria) CGN se lọjọbọ.

Awọn eeyan naa, tawọn to jẹ asaaju Naijiria tẹlẹ wa lara wọn, lo se ipade nilu Abuja lati fori ikooko sọdun lori eto aabo Naijiria ati ọna abayọ si.

Lara awọn to peju sibi ipade naa ni Oloye Olusegun Obasanjo, Sultan tilu Sokoto, Muhammad Sa'ad Abubakar, John Cardinal John Onayekan ati Abdulsalami Abubakar.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lọjọbọ lẹyin ipade wọn naa ni agbaagba yii kede pe awọn ko ni ohunkohun sọ nipa ohun ti wọn jiroro le lori nibi ipade naa.

Amọ lọjọ Ẹti, ni oloye Olusegun Obasanjo sọ fawọn akọroyin nilu Abuja pe igbimọ naa ti gbe abọ ipade rẹ sinu iwe, ti yoo si fi ransẹ si aarẹ Muhammadu Buhari.

Àkọlé fídíò, Igangan Attacks: Àkójọpọ̀ àbọ̀ BBC Yorùbá rèé nípa ìṣẹ̀lẹ̀ òfò ẹ̀mí àti dúkìá tó wáyé

O ni ohun ti ipade awọn da lori ni ọna lati wa ojutu sawọn isoro to n ba Naijiria finra bii eto aabo to mẹhẹ, ọrọ aje to dagun, igbaye-gbadun araalu ati ilọsiwaju Naijiria.

"Awa olori tẹlẹ ni Naijiria, Awọn adajọ agba tẹlẹ, ati awọn oludamọran nipa eto aabo tẹlẹ la wa ninu igbimọ to n wa ire Naijiria.

Bakan naa lawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ osisẹ, olukọ ni fasiti, awọn ẹgbẹ obinrin atawọn eeyan miran wa ninu wa amọ Jonathan, Anyaoku ati Wole Soyinka ko le ba wa pe.

Aarẹ Buhari fesi si iwe wa ta kọ pe a fẹ se ipade naa, to si fesi pada pe ka lọ se, ti abọ ipade naa si jẹ oun logun.

Àkọlé fídíò, Ogbomoso: Ẹ kálọ sí Ajilete láti mọ àwọn ibùdó tó mú kí ìlú náà yàtọ̀

A ba ara wa sọ okodoro ọrọ nibẹ nipa bi ọrọ aje ati eto aabo Naijiria se dori kodo, ta si gba pe ọpọ ọrọ la n sọ lai gbe igbesẹ gidi lati ọjọ yii wa."

Obasanjo ni awọn ko ni fi abajade ipade naa sita titi digba ti awọn ba kọkọ fi abọ ipade naa ransẹ si aarẹ Buhari.

"Amọ a ti pinnu lati mu ayipada ba ohun to n waye tẹlẹ nipa nini igbẹkẹle ninu ara wa, ka si maa gbe igbesẹ tọ ọrọ ta ba sọ.

Laipẹ lẹ si gbọ nipa awọn igbesẹ wa lori abajade ipade ta se."

Lara awọn eeyan miran to tun bawọ̀n peju sibi ipade naa ni Ooni ile Ifẹ́, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Etsu ti Nupe, Tunde Fasawe ati Audu Ogbeh.

Amin iyasọtọ kan

Ẹ̀yin tẹ̀ ń pè fún ìyapa Nàíjíríà, òmùgọ̀ pátápátá ni yín - Obasanjo

Olusegun Obasanjo

Aarẹ ana ni Naijiria, Oloye Olusegun Obasanjo ti kesi awsn eeyan to n beere fun iyapa Naijiria lati jami lori ero naa, ki wọn si sisẹ pọ fun isọkan orilẹede yii.

Obasanjo ni ohun to dara gbaa ni ki awọn ẹya to wa ni Naijiria wa ni ọkan soso laisi iyapa, nitori iwa omugọ gbaa ni fun orilẹede yii ko pin yẹlẹyẹlẹ.

Oloye Obasanjo woye ọrọ yii nibi apejẹ lati yan alaga tuntun, Kehinde Isijola fun ẹgbẹ awọn wọnlẹ-wọnlẹ ni Naijiria, ẹka ti ipinlẹ Ogun.

Ibudo iyawe-kawe Oloye Olusegun Obasanjo si ni ayẹyẹ naa ti waye lọjọru.

Aarẹ ana ni Naijiria naa wa gbe imọran kalẹ pe iyi wa ninu ki orilẹede Naijiria wa ni ẹyọ kan soso ju ki ẹya kọọkan da duro lọtọọtọ lọ.

"Ohun ti ko dara rara ni ki Naijiria pin yẹlẹyẹlẹ lasiko yii ti ilẹ Afirika n tiraka lati fidi mulẹ lẹka oselu, ọrọ aje ati igbaye-gbadun ọmọniyan.

Àkọlé fídíò, Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Emi jẹ ẹnikan to nigbagbọ pupọ ninu isọkan Naijiria ti yoo wa ni ọkan soso ni gbogbo ọna, nibi ti ori ọmọ ilẹ yii kọọkan yoo ti wu pe oun ni ipin ninu orilẹede yii."

Obasanjo wa fi orilẹede Pakistan, Yugoslavia ati Sudan se apẹrẹ awọn orilẹede to pin yẹlẹyẹlẹ, amọ ti wọn ko tii ri ojutu sawọn isoro to n ba wọn finra.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O wa salaye pe awa ọmọ Naijiria lo yẹ ka di ẹbi wahala ta n koju lorilẹede yii ru ara wa, dipo ka maa da Ọlọrun lẹbi.

Àkọlé fídíò, Aremu: Eré ìtàn nípa ìbí, àti jéèyàn pẹ̀lú ìpèníjà Olusegun Aremu Obasanjo