Igangan Attacks: Mailafia ní ó yẹ kí Buhari ṣàbẹ̀wò sí Igangan torí ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn

Eruku ifẹhonuhan to n lọ lori isẹlẹ isekupani to waye nilu Igangan nipinlẹ Oyo ko tii rodo, lọ ree mumi.
Lọtẹ yii gbajumọ kan lapa oke ọya ni Naijiria, to tun ti figba kan jẹ igbakeji gomina banki apapọ ilẹ wa, Ọmọwe Obadiah Mailafia lo sọ ero rẹ.
Lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ lori isẹlẹ isekupani naa nilu Ibadan, Mailafia ni ẹbi awọn osisẹ agbofinro nipinlẹ Oyo ni isẹlẹ ipaniyan to waye ni Igangan jẹ.
O ni awọn ileesẹ agbofinro labẹ ijọba apapọ ati tipinlẹ lo kuna lati pese aabo to peye ti isẹlẹ ipaniyan naa fi waye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi fẹ́ sàmí June 12 lọ́la, tí ariwo fi gbalẹ̀
- Agbébọn pa akẹ́kọ̀ọ̀ kan, jí ọ̀pọ̀ míràn gbé lọ ní Poly Kaduna
- Ẹyìn ọ̀dọ́ Nàìjíríà, tẹ́ bá ríṣẹ́ ṣe, ọwọ́ ara yín lẹ fi ṣe ara yín - Buhari
- Wo ọ̀rọ̀ tí ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ní Nàìjíríà sọ lórí ìfẹ̀hónúhàn June 12
- Ìrora iṣẹ́ abẹ ìdí tí mo ṣe pọ̀jù, mò ń kú lọ, mo fẹ́ padà sí bí mo ṣe wà tẹ́lẹ̀ - Bobrisky
- Wo àwọn orílẹ̀èdè mẹ́rin l‘Afrika tó ṣetán láti ra iná ìjọba láti Naijiria
- Bí mó bá fojú kan Baba Wande lórí ìtàgé, ṣe ní ẹ̀rù máa ń bà mí - Tafa Oloyede
- Àwọn tí a jọ ń se ìjọba ní Nàìjíríà sisẹ́ gba ipò wọn lábẹ́ ìjọba mi ni- Aarẹ Buhari
- Ẹ̀yin òṣèré tíátà, kò sí iṣẹ́ ọ̀fẹ́ mọ́, ẹ sanwó iṣẹ́ tẹ bá gbé fún mi - Funmi Awelewa
- Ẹyìn ọ̀dọ́ Nàìjíríà ẹ tún ìwà yín ṣẹ tí ẹ bá fẹ́ kí ìṣòro àìríṣẹ́ dòpin
O ni irufẹ ipenija eto aabo to n koju awọn eeyan ipinlẹ Oyo ko tọ si wọn rara.
"O yẹ ki aarẹ Muhammadu Buhari lọ se abẹwo silu Igangan, ko si ba awọn eeyan ibẹ kẹdun lori isẹlẹ isekupani naa nitori oun lawọn araalu dibo yan.
Ọkan wa ko si balẹ pe a le fi ara da iru iwa ipaniyan bayii nitori inu n bi wa, ti ọkan wa si bajẹ lori ipaniyan to waye ni Igangan.
Ọkan lara ojuse ijọba ni ofin ilẹ wa la kalẹ pe ko pese eto aabo to peye fun araalu ati eto igbayegbadun wọn.
Amọ ti ijọba Buhari ko ba se eyi, awọn ọdọ yoo gbakoso, bẹẹ si ni Sunday Igboho atawọn ọmọlẹyin rẹ n duro lati pese aabo to peye fun ara ilu.
Iyoku wa ku sọwọ aarẹ, bi ijọba ko ba ran araalu lọwọ, awọn araalu yoo dide lati ran ara wọn lọwọ."

Àṣìta ìbọn pa ọkùnrin kan ní Ilesa níbi táwọn afurasí ẹlẹgbẹ́ òkùnkùn ti fìjà pẹ̀ta

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti sọ pe iwadii n lọ lati fọwọ ofin mu awọn afurasi ẹlẹgbẹ okunkun meji ti ṣokunfa aṣita ibọn to pa ọkunrin kan, ThankGod Olorunwa ni ilu Ilesa, ipinlẹ Osun.
Awọn ẹgbẹ okunkun meji ti ọkunrin kan ti wọn n pe ni Solo ati Bode atawọn akẹgbẹ wọn lati Iwara ni ijọba ibilẹ ila orun Atakunmosa lo fija pẹta ti ibọn fi lọ ba Olorunwa nibi to wa.
Ọmọ ọdun mejidinlọgbọn ni Olorunwa i ṣe ko to fara gbọta aṣita ibọn awọn ẹlẹgbẹ okunkun ni Ilesa.
- Sunday Igboho ní òun ṣetán láti dira fáwọn ọ̀dọ́ Ibarapa fún ìpèsè ààbò aráàlú
- Kàyééfì! Ìyàwó bímọ mẹ́wàá lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ọkọ kò níṣẹ́ lọ́wọ́
- Iléesẹ́ Twitter ti ń bá ìjọba Nàìjíríà sọ̀rọ̀ papọ̀- Alhaji Lai Mohammed
- Igbó wúlò fún ìwòsàn ara àmọ́ ẹ kọ́ iléeṣẹ́ tó le è fi ṣe òògùn - Ẹgbẹ́ Dókítà
- Sé Nàìjíríà yóò gba lílo igbó láàyè?
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola ṣalaye ninu atẹjade to fi sita wọn ti gbe oku ọkunrin naa si ile iwosan Wesley Guild ni Ilesa.
Opalola ni awọn afurasi ẹlẹgbẹ okunkun naa yoo foju ba ileẹjọ ti ọwọ ba ti tẹ wọn.
Awọn ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ṣalaye pe Olorunwa lọ ra ounjẹ to fẹ jẹ laarọ ni ọta ibọn tawọn ẹlẹgbẹ okunkun naa yin mọ ara wọn lọ ṣeeṣi ba a.
Ohun ti a tun gbọ ni pe ija laarin ẹlẹgbẹ okunkun Eye ati Afe to ti kọkọ ṣẹlẹ lọjọ Iṣẹgun lo tẹsiwaju ni Ilesa ni Ọjọru.
















