Bobrisky: Ẹyin mi ti lọ, inú ń dùn mí, ìrora yìí pọ̀ jù

Oríṣun àwòrán, Instagram/Bobrisky
Yoruba bọ, wọn ni oju ẹni maa la, a ri iyọnu, tita, riro si la n kọ ila, to ba jinna tan, yoo si di oge.
Bayii gan an lọrọ ṣe ri pẹlu gbajugbaja ọkunrin to maa n mura bii abo, Idris Okunneye, ti ọpọ eeyan mọ si Bobrisky, lori isẹ abẹ to ṣe lati mu ki idi rẹ tobi, ko si duro daadaa nilẹ.
Laipẹ yii si la mu iroyin wa fun yin pe Bobrisky fẹ lọ se ise abẹ idi saaju ọjọ ibi rẹ to si ni oun fẹ maa se idi bala-bala ko to di igba naa.
Nibayii to ti se ise abẹ idi naa nilu Santo Domingo ni lorilẹede Dominican Republic, Bobrisky ti wa n kerora pe iṣẹ abẹ naa ko rọrun rara.
Koda o ni oun ro pe oun ti fẹ ku ni nibi ti iṣẹ abẹ naa dun oun de, ti inu si n kan oun pẹlu.
- Àyà mi ń já, ẹ̀rù ń bà mí torí iṣẹ́ abẹ ìdí tí mo fẹ́ ṣe - Bobrisky
- Àwọn òṣèré tó ti bàjẹ́ láti ilé, ló kó ìbàjẹ́ wọ agbo tiata débi a'ṣọ ìhòòhò - Dele Odule
- Ẹ má jẹ́ kí ayélujára tàn yín jẹ́, mẹ̀kúnnù lọ̀pọ̀ àwa òṣèré tíátà - Iyabo Ojo
- Kàyééfì! Ìyàwó bímọ mẹ́wàá lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ọkọ kò níṣẹ́ lọ́wọ́
- Sunday Igboho ní òun ṣetán láti dira fáwọn ọ̀dọ́ Ibarapa fún ìpèsè ààbò aráàlú
- Orí mi wú pé àkòkò ìjọba mi ní àṣeyọrí reluwé ń wáyé - Buhari
- Wo ilúbìnrin tí wọn ti ń ní ìbálòpọ̀, bímọ̀ láì ní ọkọ
- Ẹ̀yin tẹ̀ ń pè fún ìyapa Nàíjíríà, òmùgọ̀ pátápátá ni yín - Obasanjo
Bobrisky sọrọ loju opo Snapchat rẹ pe irora ti oun jẹ lasiko iṣẹ abẹ ọhun ko ṣe maa fi ẹnu sọ.
''Ikun mi n dun mi gan an, bakan naa ni ẹyin n ro mi goro go.
Awọn eeyan ti wọn ba ti ṣe iru iṣẹ abẹ bẹẹ ri lo le sọ bi irora to wa nibẹ ṣe pọ to.

Oríṣun àwòrán, Bobrisky/Snapchat
Mo fẹ ki gbogbo irora naa lọ, ki n si pada si igbe aye ti mo n gbe tẹlẹ, ki n to lọ ṣiṣẹ abẹ idi,'' Bobrisky ṣalaye.
Isẹ abẹ yii ti wọn n pe ni 360 Liposuction, ni wọn ti maa n bu ọra kuro ni awọn ẹya ara kan, bii itan, ikun tabi isalẹ ẹyin.
Awọn ọra yii ni wọn yoo si ko lọ sinu idi, lati jẹ ko tobi si.

Oríṣun àwòrán, Bobrisky/Snapchat
Awọn ọra naa bakan naa, ni yoo tun jẹ ki irisi idi tun yatọ lai jẹ pe wọn ri ohunkohun sinu rẹ.
Bobrisky ti sọ tẹlẹ pe oun gbọdọ ṣe iṣẹ abẹ yii lai fọta pe.
''Mo gbọdọ se ni, maa wọ inu yara isẹ abẹ lọ, ki n si jade pẹlu ara to rẹwa.
Ọjọ Kọkanlelọgbọn osu Kẹjọ ni ọjọ ibi mi, mo si fẹ ki irisi mi jẹ oju ni gbese lọjọ naa,'' Bobrisky lo sọ bẹẹ.
Bobrisky fikun ọrọ rẹ pe lati ọdun diẹ sẹyin loun ti n ro lati se isẹ abẹ naa, ki oun to wa pinnu bayii lati ṣee.

Oríṣun àwòrán, Bobrisky/Instagram















