Gosiame Sithole: Ìyàwó bímọ mẹ́wàá lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lẹ́yìn tó ti bí ìbejì tẹ́lẹ̀

Gosiame Thamara Sithole

Oríṣun àwòrán, AFRICAN NEWS AGENCY(ANA)

Iṣẹ Eledumare, awa maridi nio, nitori ko si ẹda kan to ye.

Obìnrin kan lorilẹede South Afrika ma ni Eledua fi ọmọ mẹwaa ta lọrẹ ẹ lẹẹkan ṣoṣo.

Gẹgẹ bí iwe iroyin Daily Mail ṣe sọ, Goaiame Thamara Sithole to jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn ti kọkọ bi ibeji tẹlẹ.

Ṣugbọn ni báyìí ọkunrin meje ati obinrin mẹta lawọn ọmọ ti Eledumare ṣẹṣẹ fi ta idile rẹ lọrẹ.

Ọkọ obinrin naa, Tebogo Tsotetsi sọ fáwọn akọroyin pe iṣẹ abẹ ni wọn fi gbẹbi awọn ọmọ naa nile iwosan kan niluu Pretoria lọjọ Aje.

Pabambari rẹ ni pe Tsotetsi ko niiṣe kan lọwọ.

O ni lootọọ ni inu oun dun amọ ominu ṣi n kọ oun bakan naa.

Arabinrin Sithole ṣalaye pe awọn ko loyun lọna Igbalode IVF tabi ọna mii.

Ṣugbọn awọn dokita sọ pe ọna Igbalode IVF at'awọn ọna mii lo le mu ki ọmọ pọ to bayẹn lẹẹkan ṣoṣo.

Tsotetsi to jẹ ọkọ arabinrin naa lo kọkọ sọ fáwọn akọroyin nipa ibi awọn ọmọ mẹwaa ọhún.

Sithole ni awọn dokita kọkọ sọ foun pe ọmọ mẹfa lo wa ninu oun, nigba to ya, ayẹwo scan fihan pe mẹjọ ni.

O ni nigba ti wọn n gbẹbi foun lọwọ ni wọn ri pe mẹwaa láwọn ọmọ to wa ninu oun.