Igangan Attacks: Makinde ní òun ṣetán báyìí láti ró àwọn ọdẹ ìbílẹ̀ àtàwọn míí lágbára

Oríṣun àwòrán, Taiwo Adisa
Lẹyin ọjọ mẹta ti ikọlu waye ni Igangan ni ijọba ibilẹ Ibarapa, Gomina Seyi Makinde ti ṣabẹwo si agbegbe naa.
Abẹwo yii jẹ eleyi ti pupọ araalu ti n reti pe yoo waye, paapa pẹlu iru ijamba to mu ọpọ ẹmi ati dukia lọ ni agbegbe naa.
L'ọjọ Iṣẹgun ti Gomina Ṣeyi Makinde de ilu naa, o kede pe oun yoo sa gbogbo ipa lati daabo bo awọn olugbe ipinlẹ naa.
- Orílẹ̀-ède 174 káàkiri àgbáyé ní ìwọ́de Yoruba Nation yóò tí wáyé ní June 12- Ẹgbẹ́ Yoruba One Voice
- Sunday Igboho ṣàbẹ̀wò sí Igangan lẹ́yìn ìkọlù, àmọ́...
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ní ìkọlù ń bọ̀ sáwọn iléèwé ní Ibarapa tí òbí fi ń kó ọmọ níléẹ̀kọ́?
- Ẹ̀yin Fulani, ẹ yàgò fún ilẹ̀ Yorùbá lásìkò yìí- Iba Gani Adams
- Rògbòdìyàn míì bẹ́ sílẹ̀ láàrin Yorùbá àti Bòròró ní Saki, ẹ̀mí bọ́, dúkìá ṣòfò
O fi alaye kun pe ijọba yoo ṣe ohun gbogbo lati dena iru iṣẹlẹ to waye nilu Igangan ati ni awọn agbegbe mii, lọjọ iwaju.

Oríṣun àwòrán, Taiwo Adisa
Lasiko abẹwo yii, Makinde kan si mọlẹbi awọn eeyan to fi ara gba nibi iṣẹlẹ to waye l'opin ọsẹ to kọja naa.
O ni ijọba yoo ro awọn eleto aabo ibilẹ ni agbara, ki iṣoro eto aabo le di ohun igbagbe nilẹ Ibarapa.
Gomina Makinde nikan kọ lo da ṣe abẹwo yii lọ si agbegbe Ibarapa.

Oríṣun àwòrán, Taiwo Adisa
Lara awọn to kọwọrin pẹlu rẹ ni awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ọyọ, to fi mọ adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Hon. Adebo Ogundoyin, ẹni to bẹnu atẹ lu ofo ẹmi ati dukia lagbegbe naa.O fi kun ọrọ rẹ pe ijọba ti ṣe awari awọn igun to ku diẹ kaato, gẹgẹ bo ṣe n ke si awọn eeyan lati fun ijọba rẹ ni anfani lati mu ki ohun gbogbo tuba, ki o si tuṣẹ bo se wa tẹlẹri, lai si ibẹru.

Oríṣun àwòrán, Taiwo Adisa
Makinde rọ awọn eeyan pe ki wọn ma ṣe idajọ lọwọ ara wọn, dipo bẹẹ, o ni ijọba oun ni ki wọn ba lejọ.



















