Igangan Attacks: Ẹ̀yin olóṣèlú, ẹ má fi ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn Igangan dá ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà sílẹ̀- YWG

Awọn dukia ti agbebọn dana sun ni Ibarapa

Oríṣun àwòrán, Monsuru Aderoju

Ẹgbẹ ọmọ Yoruba, Yoruba Welfare Group (YWG) ti ṣe ìkìlọ fáwọn oloselu.

YWG ni pe ki wọn maa lo iṣẹlẹ ipaniyan to waye niluu Igangan mawọn Yoruba kọlu awọn ẹya miran.

Bi ẹgbẹ YWG ti kẹdun pẹlú àwọn èèyàn Igangan, bẹẹ naa lo rọ awọn oloṣelu lati wa ojutu si iṣẹlẹ laabi ọhun ki wọn sì yago fun ohun to le fa ìjà.

Aarẹ ẹgbẹ YWG lo sọrọ yii nigba to ṣabẹwo sí Asigangan ilu Igangan lati bawọn araalu naa kẹdun.

Ohun ti aarẹ YWG ni lọkan lọrọ tí Ọjọgbọn Banji Akintoye sọ lẹyin ikọlu ọjọ Aiku niluu Igangan pe ijọba apapọ at'awọn Fulani bẹrẹ ogun tako ilẹ Yoruba.

O ni ọrọ naa ri bakan nigba ti Ọjọgbọn Akintoye ti ko ti ṣabẹwo s'ilu Igangan le sọ pe awọn Fulani lo gbimọ pọ kọlu Igangan lọjọ Aiku.

Àkọlé fídíò, Tunde Gbadamosi: Kìí ṣe Tinubu ní ipò ààrẹ̀ tọ́ sí, ìgbà wo ní ìtan ajá ń kan lèmọ́mù?

"Ọjọgbọn Akintoye ni lati dẹkun fifi ẹmi awọn Yoruba tafala.

Eto abo to múná dóko ni Yoruba nilo bayii ju ọrọ oṣelu lọ.

Asiko ti to fun wa nilẹ Yoruba lati fori kori lori ọna ti le gba wa ojutu si eto abo to mẹhẹ.

O nilo lati ronu ju ohun tawọn ẹṣọ Amotekun le ṣe lọ lori eto abo bayii," aarẹ YWG lo sọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, 'A rí wàhálà táwọn èèyàn ń kojú nilẹ̀ẹ̀ Yorùbá la ṣe fi "Amotekun" fi ọkàn wọn balẹ̀'

O rọ gbogbo awọn ọmọ Yoruba atata lati fọwọ so wọpọ gbogun ti iṣẹlẹ ijinigbe ati ipaniyan yatọ sí kí wọn kan maa pariwo lori ayelujara lasan.

Ninu ọrọ tiẹ, Asigangan ilu Igangan, Oba AbdulAzeez Adeoye tawọn afurasi Fulani ọhún dana sun aafin rẹ naa kepe Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo lati ṣeranwọ fáwọn tó ṣofo dukia wọn ninu ikọlu to waye.

Àkọlé fídíò, Snail Slim Soap: Wo ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú lílo ọ̀ṣẹ tí wọn fi omi ìgbín ṣe láti fọ ojú?

Ìpànìyàn ní Igangan ń tọ́ Yorùbá níjà, Amotekun alájùmọ̀ṣe ní yóò yanjú rẹ̀ - Akeredolu

Akeredolu àtàwọn Gómìnà Yorùbá fòntẹ̀ lu Amọtẹkun alájùmọ̀ṣe

Awọn Gomina ẹkun iwọ oorun Guusu Naijiria paṣẹ pe ki ikọ Amọtẹkun lẹkun naa bẹrẹ iṣẹ ajọṣepọ.

Aṣẹ tuntun yii ko si sẹyin ikọlu to waye sawọn araalu Igangan ni ijọba ibilẹ Ibarapa ni ipinlẹ Oyo lọjọ Abamẹta.

Ninu akọtun ikọlu naa, awọn ọlọpaa sọ pe eeyan mọkanla lo kagbako iku ojiji lọwọ awọn afurasi agbebọn.

Bẹẹ naa ni wọn dana sun aafin Ọba, awọn ọkọ araalu to fi mọ ile epo kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gomina Rotimi Akeredolu, tii se alaga ẹgbẹ awọn Gomina iwọ oorun Guusu Naijiria lo kede ipinu awọn Gomina naa.

O sọ pe awọn adari ikọ Amọtẹkun ni Oyo, Ondo, Ogun, Osun ati Ekiti lawọn ti sọ fun pe ki wọn fikunlukun, lọna ti wọn yoo fi jijọ ṣiṣẹ pọ.

O wa ṣapejuwe ikọlu to waye ni Igangan gẹgẹ bi ohun to buru jai, to si n tọwọ bọ ni loju lati le wa ija.

Akeredolu tun ke si gbogbo awọn ọmọ Naijiria lati panupọ bẹnu atẹ lu iru iwa yii, eyi to ni o jẹ ikọlu si iwa ọmọluabi ati ibagbepọ alaafia.

''A o ni sinmi titi ti a fi mu ileri wa ṣẹ. O di dandan ki gbogbo awa taa nifẹ alaafia ati ominira koju iwa ẹhanna yi.''

O tẹsiwaju pe ''Ni tiwa, a ti pinu lati daabobo awọn eeyan wa, dukia wọn ati gbogbo ọna jijẹ-mimu wọn lọwọ awọn to n gbogun ti wọn labẹle ati lẹyin odi. Lori eyi, a ko ni yẹ, a ko ni gbọ''

Amotekun

Oríṣun àwòrán, @Amotekun

Lọjọ Kẹsan oṣu Kini ọdun 2020 ni wọn ṣe ifilọlẹ ikọ alaabo Amọtẹkun.

Wọn ṣe agbekalẹ ikọ yii lati koju ipenija aabo to n koju awọn ipinlẹ Yoruba to wa ni ẹkun iwọ oorun Guusu Naijiria.

Lara ojuṣe ikọ yi ni ki wọn koju iwa ọdaran lati ọwọ awọn ọdaran darandaran to n sapamọ sinu igbo lati ṣe ikọlu si araalu.

Awọn ijọba ipinlẹ ti ṣaaju pawọpọ ko ọkọ ati awọn nkan eelo miran jọ fun ikọ naa, ṣugbọn ko pẹ sigba ti wọn bẹrẹ ni Minisita feto idajọ Naijiria, Abubakar Malami ni ikọ naa ko bofin mu.

Àkọlé fídíò, Tunde Gbadamosi: Kìí ṣe Tinubu ní ipò ààrẹ̀ tọ́ sí, ìgbà wo ní ìtan ajá ń kan lèmọ́mù?

O sọ pe ko si agbarijọpọ ipinlẹ Naijiria kankan to laṣẹ lati ṣe idasilẹ ikọ alaabo ti wọn yatọ si ti ijọba apapọ.

Amọ bayi ti ipenija aabo ti wa fẹju kọja ti tẹlẹ, ohun tara ilu yoo maa beere ni igba ti Amọtẹkun yoo gbera sọ lati le pese aabo to peye fawọn.