Rev Stephen Akinola: Ọmọ bíbí ìlú Igboho níí ṣe àmọ́ tó fi Portharcourt ṣe ibùjókòó

Oríṣun àwòrán, Redemption Ministry
Ọrọ iku ọwọọwọ yii ti wa n toju su awọn eeyan lorilẹede Naijiria nitori bi awọn ọmọde ati agba se n ku.
Ni afẹmọjumọ ọjọ Satide si ọjọ Aiku, ni gbajumọ wolii kan, TB Joshua ki aye pe o digbose, amọ ki ilẹ ọjọ Aiku to su, ni iroyin miran tun gba ilẹ kan pe ojisẹ Ọlọrun miran tun ti jade laye.
Oluwarẹ ni Alufa Stephen Akinola ti ileesẹ iransẹ Redemption Ministry lagbaye, ti ibujoko rẹ wa nilu Portharcourt.
- Ẹ wo àwọn Pásítọ̀ jàǹkàn-jànkàn tí ikú wọn tí mí orílẹ̀èdè Naijiria
- Wo ojú táwọn Pásítọ̀ fi wo T.B Joshua nígbà ayé rẹ̀, tó fa awuyewuye
- Ìtàn ayé TB Joshua tó lo ọdún kan àti oṣù mẹ́ta nínú ìyà rẹ̀
- Ìdí rèé tí ń kò fi ní ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí mi ní June 12 - TB Joshua sàsọtẹ́lẹ̀
- Wòlíì TB Joshua sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ lọ́jọ́ Satide tó kú - Ìjọ SCOAN
Eto alẹ Suya (Suya Night) ati iji onina (Wind Of Fire) si ni gbogbo eeyan fi mọ ojisẹ Ọlọrun naa.
Idaji ọjọ Aiku, ni tooto asiko ti Wolii TB Joshua jade laye, naa ni Alufa Akinola naa mi kanlẹ nile iwosan kan nilu Abuja.
Gẹgẹ bi ọkan lara ojisẹ Ọlọrun ninu ijọ naa ti fidi rẹ mulẹ fun BBC, gbogbo awọn alufa ijọ naa ni wọn ti kede iku gbajumọ ojisẹ Ọlọrun fun.
Igbe aye Alufa Stephen Akiola:
O fikun pe wọn ti gbe oku oloogbe lọ sibudo igbokusi.
Ọmọ bibi ilu Igboho nipinlẹ Oyo ni Alufa Stephen Akinola, amọ ẹkun ariwa orilẹede Ghana ni wsn bi si.
Alufa Samuel Akinola naa ni baba to bi lọmọ, to si ni aburo mẹsan amọ oun ni abikẹyin awọn obi rẹ.
Amọ wọn padanu baba wọn nigba ti Stephen wa ni ọmọ ọdun mẹtala.
Ile ẹkọ alakọbẹrẹ to wa nilu Damago lẹkun ariwa orilẹede Ghana ni Stephen ti bẹrẹ ẹkọ alakọbẹrẹ nigba to pe ọmọ ọdun mẹrin.
Ọdun 1963 lo setan nile ẹkọ mọda, to si lọ sile ẹkọ girama nilu Tamale. Eyi to pari lọdun 1970.
Ọdun 1971 lo pada de sorilẹede Naijiria, to si n se isẹ olukọ nile ẹkọ alakọbẹrẹ onitẹbọmi to wa nilu Igboho.
Amọ o tẹsiwaju lẹnu ẹkọ rẹ lẹyin to sisẹ ọdun meji, to si lọ sile ẹkọ gbogbonse Poly ni Yaba, lẹyin naa lo wa bẹrẹ isẹ iransẹ.



















