TB Joshua dead: Ikú TB Joshua, Ọmọ Pasitọ Enoch Adeboye, Dare àti àwọn Pásítọ̀ jàǹkàn-jànkàn tí ikú wọn tí mí orílẹ̀èdè Naijiria

Oríṣun àwòrán, Others
Iyalẹnu ati ibanujẹ ọkan ni awọn eniyan fi gbọ iroyin iku gbajugbaja Woli TB Joshua to ni ile ijọsin Synagogue Church of All Nations [SCOAN] to wa ni ilu Eko ni orilẹede Naijiria.
Pasitọ naa jẹ gbajugbaja kaakiri agbaye ti awọn eniyan si ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi ẹni to o ma n fi fun ni ni ọpọ igba.
Pasitọ naa to ku ni ẹni ọdun mẹtadinlọgọta lo mu jinni-jinni ba gbogbo awọn eniyan lagbaye paapaa awọn orilẹede ni iwọ guusu Naijiria.
Iroyin iku pasitọ naa lo n waye lẹyin oṣu kan ti Dare Adeboye to jẹ ọmọ baba Enoch Adeboye, iyẹn adari ijọ Redeem Christian Church of God lagbaye jade laye.
Akojọpọ awọn pasitọ ti iku wọn ti mi orilẹede Naijiria ni aipẹ yii ree.
Iku TB Joshua

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPEI
Ileesẹ iransẹ TB Joshua ti kede pe oludasilẹ ijọ naa ati agba wolii lorilẹede Naijiria, Temitope Balogun Joshua ti dagbere faye.
Gẹgẹ bi ikede kan ti ileesẹ iransẹ naa ati ijọ Church Of ALl Nations fisita loju opo Facebook rẹ, ana ọjọ Satide, ọjọ karun osu Kẹfa ọdun 2021 ni agba wolii naa mi kanlẹ.
Wolii Joshua, to dele aye ni ọjọ Kejila osu Kẹfa ọdun 1963, lo lo ọdun mejidinlọgọta loke eepẹ, ki ọlọjọ to de.
Wolii Joshua sọrọ lọjọ Satide lasiko ipade to se pẹlu awọn alabasisẹpọ rẹ fun ileesẹ mohunmaworan ijọ rẹ, Emmanuel TV, to si dabi ẹnipe o n sọ asọtẹlẹ nipa iku rẹ.
Ọgọọrọ eniyan ti o pejọ pọ si ijọ rẹ ni Ọjọ Isinmi, Ọjọ Kẹfa, Oṣu Kẹfa lati ṣe ikẹdun iku akọni naa to re ọrun aremabọ.
Iku Dare Adeboye to jẹ ọmọ Pasitọ Enoch Adeboye

Oríṣun àwòrán, Leke Adeboye
Apapọ ẹgbẹ awọn ọmọ Pasitọ ni ijọ Redeemed Christian Church of God lo fi kede sita pe Oluwadamilare Temitayo Adeboye ti jade laye.
Awọn ọdọ ijọ RCCG ni pẹlu ọkan wuwo ni awọn fi kede ipapoda ọmọ wọn, ẹgbọn wa, ọkọ ati baba wọn, Oluwadamilare Temitayo Adeboye to lọ ba Ọlọrun ni ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹrin oṣu karun ọdun 2021".
Atẹjade naa ka wipe igbe aye rẹ jẹ igbe aye rere gẹgẹ bo ṣe sin Ọlọrun lai kaarẹ, to n fun ni. to si n dari lai si ifoya.
"Bo tilẹ jẹ pe iroyin yii fi wa gidi gan, a duro lori Jesu Kristi ninu ẹni ti a ni idaniloju pe a o pade nibi ti ko si inira".
Ẹni ọdun mejilelọgoji ni Pasitọ Damilare Adeboye ki o to jẹ kuro laye.
Iku Emmanuel Abina, ọmọ Olùdarí ìjọ GOFAMINT, Elijah Abina to jade laye.

Oríṣun àwòrán, Instagram/gofamint
Pasitọ Elijah Abina, to jẹ adari ijọ Gospel Faith Mission International, GOFAMINT, ti padanu ọmọ rẹ ọkunrin, Emmanuel Folorunso.
Iroyin iku ọmọ Pasitọ Abina jade lẹyin ọjọ diẹ ti ọmọkunrin Pasitọ agba ijọ Redeem, Enoch Adeboye naa jade laye.
Iroyin sọ pe ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2021, ni Emmanuel Abina ku nilu Eko.
Eyi to jẹ ọjọ kẹjọ ṣaaju iku ọmọ Adeboye.
Iku Pasitọ Ibidun Ighodalo ti ijọ Trinity House Church

Oríṣun àwòrán, Others
Ariwo ati ibanujẹ gbode lorilẹede Naijiria nigba ti iroyin iku pasitọ Ibidun Ighodalo to jẹ́ ọbinrin tó rẹ̀wà jùlọ nígbàkan rí, tó sì tún jẹ́ ìyàwó adarí àti olùdásílẹ̀ ìjọ Trinity House tan jade.
Ibidunni Ighodalo náà kú ní ìdájí Ọjọ́ àìkú, Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Kẹfa, ọdun 2020 ní ìlú Port Harcourt, nípìnlẹ̀ Rivers nibi to ti lọ ṣèrànwọ́ kíkọ́ ibudó ti wọn yóò ti maa tójú àwọn aláàrùn Covid-19 nibẹ.
Nurudeen Lawal to jẹ adarí Elizabeth R ti Pasitọ Ibidun jẹ oludasilẹ fun, sọ wi pe àwọn kò mọ ǹkan to ṣe ku paa nítori lẹ́yìn ti àwọn pari iṣẹ́ ní olúkúlùkù wọ yàrá rẹ̀ lọ láti sù, sùgbọ́n nígbà ti ilẹ̀ mọ́ ni ni kò jí mọ.
Ibídùn fí ọkọ àti ìbejì rẹ̀ silẹ̀ sáyé lọ.
Kayode Badru to ku si ile ijọsin Celestial Church of Christ ni Eko

Oríṣun àwòrán, Instagram/Celestialonline
Ariwo he lo jade lori ẹrọ ayelujara lẹyin ti ọdọmọde olowo ati oniṣowo ni ipinlẹ Eko, Kayode Badru ku iku ojiji ni ile ijọsin Celestial Church of Christ ni ilu Eko.
Iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni Ọjọ Aje, Ọjọ Kẹta, Osu Karun un, lasiko to n ṣe eto adura ninu ile ijọsin naa.
Ọkan gboogi ninu awọn agba ni ile ijọsin ti iṣẹlẹ naa ti waye, Imolẹmitan Ojo ni Badru ṣẹ̀ṣẹ de lati Dubai wa si Naijiria lati wa ṣe ayẹyẹ to ti wa pin nkan fun awọn eniyan.
Imọlẹmitan ni ọpẹ́ ní Kayode Badru ń ṣe pẹ̀lú imọlẹ meje ti o fi n ṣe ọpẹ naa ki o to di wi pe nkan yiwọ.
O ni: ''Funrara Kayode Badru lo tan imọlẹ meje to fẹ fi ṣe ọpẹ ni Ọsan Ọjọ Aje naa, ti o fi dupẹ lọwọ Ọlọrun
''Lẹyin naa ni wọn gba imọlẹ meje naa ni ọwọ rẹ, ti wọn si sunmọ kuro ni ọdọ rẹ, ki Woli Ebony to gbadura fun un to si wọn 'perfume' si i lara amọ ko pọju bi o ṣe yẹ lọ''
''Ti ina fi jo Kayode ni ara ko ju iṣẹju aaya ọgbọn, ti ko si to iṣẹju kan ti awọn eniyan to wa nibẹ fi sare digbadigba lọ bu omi ti wọn si pa ina naa''.
Arakunrin Imọlẹmitan tun ṣalaye fun BBC ''nii Ọjọọru ti mo pada lọ si ile iwosan lo wo o, Kayode Badru sọ fun mi pe oun jẹun, o jẹ amala to si mu olomiọsan, amọ Ọjọbọ ni wọn sọ fun mi pe o ti jade laye''.
Iku ajíhìnrere àgbáyé Reinhard Bonnke

Oríṣun àwòrán, Facebook/Reinhard Bonnke
Iku doro, iku ṣeka, iku ti mu gbajugba ajiyinrere agbaye, Reinhard Bonnke lọ lẹni ọdun mọkandinlọgọrin.
Ninu atẹjade kan ti iyawo rẹ, Annie Bonnke buwọ lu loju opo Facebook rẹ ni wọn ti kede iku ojiṣẹ Ọlọrun yii.
Wọn sọ ninu atẹjade naa pe pẹlu alaafia ni Ọgbẹni Bonnke fi pada lọ ba Ẹlẹdaa rẹ ni ọrun.
Fun ọgọta ọdun sẹyin, Bonnke ṣiṣẹ ajihinrere kaakiri agbaye papaa julọ nilẹ Afirika, o ṣe eto isọji kaakiri awọn orilẹ-ede, ti awọn ọmọlẹyin Kristi ni orilẹede Naijiria si gba tirẹ.












