T.B Joshua: ...Àwọn ọmọ ẹ̀yin ń sọ̀fọ̀, ìdá mẹ́ta àǹgẹ́lì Olorun dójútí Lucifa tó lọ- Pasito Chris Okotie

Okotie

Oríṣun àwòrán, Others

Ibinu nla lati oke wa ti mu anjonu to n jẹ́ Emmanuel lọ, bẹ́ẹ̀, awọn ọmọ lẹ́yin rẹ́ n sọ̀fọ̀ ipapoda abuku rẹ̀- Pasito Chris Okotie

Pasito Chris Okotie jẹ́ ọ̀kan lara awọn pasito ti won ti sọ̀rọ̀ sita lẹ́yin iku Wolii TB Joshua.

Okotie sọ̀rọ̀ yii lori ero ayelujara ni eyi ti wọ́n ni o wa fun oludasilẹ̀ ijọ Household of God International Ministries.

Ọ̀pọ̀ awon omo Naijiria, lo ti faraya lori ayelujara lori ọ̀rọ̀ Okotie naa.

Won n sọ pe ko kuku si ẹni ti ko ni ku.

Bẹ́ẹ̀, wọ́n ni ọ̀rọ̀ naa ti pọ̀ ju.

Àkọlé fídíò, Magaret Jimoh: Èrè díẹ̀ ti tó mi níbi oúnjẹ ti mò ń tà- Maggie Rice

Nitooto Chris Okotie ko darukọ kankan ju Emmanuel to fi kun srọ̀ rẹ̀ lọ Sugbọ́n awn eeyan n ni pe o jọ gate, ko jọ gate, o n fi ẹ̀sẹ̀ mejeji tiro ni ọ̀rọ̀ naa jọ.

Awọ́n to n sọ̀rọ̀ loriayelujara ni eyi ko seyin Wolii TB Joshua to ku yii to si je pe Emmanuel naa ni orukọ́ ile ise amohunmaworan re ti ijọ Synagogue Church of All Nations (SCOAN).

Alufa Chris Okotie

Oríṣun àwòrán, rev.chrisokotie/Instagram

Iranṣẹ esu ni TB Joshua to fẹ da ijọ Ọlọrun ni Naijiria ru - Pasitọ Chris Okotie

Ẹni akọkọ to kọkọ tako TB Joshjua ni Pasitọ Chris Okotie, ti ijọ Household of God, nigba to ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi iransẹ esu lagbaye, to fẹ da ijọ Ọlọrun ru ni Naijiria.

Okotie ti ko fi igba kan sọ ọrọ TB Joshua ni rere sọ wi pe, o n ṣiṣẹ pẹlu agbara ẹmi okunkun lati sọ agbara ijọ ni Naijiria di okunkun nitori ifẹ esu ni ohun ṣe.

Bakan naa ni Pasitọ naa ko fi ẹhọnu rẹ bo, nigba ti o ri fidio ti Pasitọ Chris Oyakhilome ati TB Joshua ti n gbadura fun arakunrin kan to rọ lapa rọ lẹsẹ.

Àkọlé fídíò, Tunde Gbadamosi: Kìí ṣe Tinubu ní ipò ààrẹ̀ tọ́ sí, ìgbà wo ní ìtan ajá ń kan lèmọ́mù?

Kí ló dé tí ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi àtàwọn Pásítọ̀ kò dárò ikú TB Joshua?

Gbajugbaja akọroyin, Dele Mọmọdu ti fesi lori iku oloogbe T.B Joshua

Dele Momodu ń bèèrè pé ṣe ẹgbẹ́ CAN àtàwọn pásítọ̀ ṣì ń bá olóògbé jà ni lẹ́yìn ikú rẹ̀?

Ṣugbọn yatọ si pe o daro iku wolii naa, ibeere to n beere ni pe ki lo de ti awọn ẹgbẹ ẹlẹsin Kristiẹni ko ti i sọ nkankan nipa iku rẹ.

Okotie

Oríṣun àwòrán, Others

Lati owurọ ọjọ Aiku ti iroyin iku Joshua ti jade, ni ọpọlọpọ eniyan kaakiri agbaye ti n daro rẹ, ti wọn si n sọ oriṣiriṣi nkan nipa rẹ.

Amọ, akiyesi fihan pe ko si ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi kankan bi Christian Association of Nigeria, CAN, Pentecostal Fellowship of Nigeria, to fi mọ awọn iranṣẹ Ọlọrun to gbajumọ, ko ti i sọ ohunkohun nipa akẹẹgbẹ wọn to lọ.

Ninu ọrọ kan to kọ si ori ayelujara Instagram rẹ, Momodu sọ pe "o ga o, pe ko ti i si ọrọ kankan nipa iku TB Joshua lati ọdọ awọn ọmọlẹyin Kristi.

Se wọn tun ṣi korira rẹ lẹyin to ku ni?".

"Ko nilo ibuwọlu ẹnikẹni... Gbogbo ọkan ni yoo ku."

Àkọlé fídíò, Magaret Jimoh: Èrè díẹ̀ ti tó mi níbi oúnjẹ ti mò ń tà- Maggie Rice

A ko le sọ idi ti awọn eeyan yii ko ti i sọ ọrọ tabi daro iku wolii naa, tabi iru ibaṣepọ to wa laarin TB Joshua ati ẹgbẹ awọn Kristiẹni nigba to fi wa laye.

Amọ awọn iroyin ti a ko le fidi rẹ mulẹ to n lọ ni pe awọn ẹgbẹ Kristiẹni ati awọn gbajugbaja iranṣẹ Ọlọrun kan ni Naijiria ti sọrọ ri pe, awọn ko le gba T.B Joshua laaye ninu ẹgbẹ awọn.

Bakan naa ni wọn ni awọn ko ni lọ si ṣọọṣi rẹ fun iṣẹ iranṣẹ "nitori pe kii ṣe ẹni igbala, bẹẹ ni orisun iṣẹ iyanu to n ṣe ko mọ ọ".

Àkọlé fídíò, Tunde Gbadamosi: Kìí ṣe Tinubu ní ipò ààrẹ̀ tọ́ sí, ìgbà wo ní ìtan ajá ń kan lèmọ́mù?

Ọpọ igba ni awuyewuye waye lori iṣẹ iranṣẹ rẹ.

Laipẹ yii ni ileeṣẹ ayelujara Youtube pa oju opo rẹ lọdọ wọn rẹ, nitori fidio kan ti Joshua ti sọ pe oun n wo awọn ọkunrin to n ni ibalopọ pẹlu ọkunrin ẹgbẹ wọn san.

Yatọ si eyi, awọn igba kan wa ti awuyewuye ti waye ri nipa rẹ nitori awọn asọtẹlẹ to sọ ti ko wa si imuṣẹ.

Bakan naa ni lọdun 2014, nigba ti ile kan wó ninu ọgba ile ijọsin Synagogue, to si pa eeyan to le ni ọgọrun.

Pupọ ninu awọn eeyan naa lo wa lati orilẹ-ede South Africa.

Amin iyasọtọ kan

Wo ojú táwọn Pásítọ̀ fi wo T.B Joshua nígbà ayé rẹ̀, tó fa awuyewuye

Yoruba ni ta ba ku laa dere, eeyan ko sunwọn laaye.

Pasitọ Ijọ Synagogue Church of All Nations, Wolii Temitope Balogun Joshua to dagbere faye ni ọpọ eeyan n kọrin re ki lẹyin iku rẹ pe oloore lọ.

Amọ ni ọpọ igba, ni ọrọ nipa agba wolii naa ti fa awuyewuye, ti wọn si n beere pe ṣe lootọ ni Woli naa jẹ iranṣẹ Ọlọrun?

Lati igba ti Woli TB Joshua ti bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bi eniyan Ọlọrun ni ọpọlọpọ eniyan ti ma n tẹle fun itusilẹ lọwọ ẹmi okunkun, igbala ẹmi wọn ati iṣẹ iyanu.

Kaakiri orilẹede agbaye si ni awọn eniyan ti maa n wa si ile ijọsin rẹ fun igbala ati iwosan, ti ọpọlọpọ ṣi n jẹri si pe agbara rẹ daju.

Amọ ọpọlọpọ awọn pasitọ miran lo ri Joshua nigba aye rẹ, gẹgẹ bi onirọ, to kan n fi orukọ Ọlọrun jẹun ati ẹlẹgbẹ okunkun to n lo agbara ẹmi okunkun ati awọn alawo lati fi ṣe iwosan.

Diẹ lara aero awọn ojisẹ Ọlọrun miran ree nipa TB Joshua lasiko to wa loke eepẹ.

Àkọlé fídíò, Blessing Olajide: Ẹ̀bí akẹ́kọ̀ọ́jáde fásitì Ilorin tí wọn pa ṣàlàyé ikú rẹ̀

Ohun ti Chris Okotie sọ nigba naa ni pe, o ṣeun ni aanu pe Chris Oyakilhome n ṣepọ pẹlu TB Joshua.

O si tẹnumọ pe ẹlẹgbẹ okunkun ni pasitọ naa, to si bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe n pe e ni ''Emmanuel'', orukọ ti wọn n pe Jesu Kristi, to jẹ adari gbogbo ijọ Kristẹni lagbaye.

TB Joshua kii ṣe ara wa, ẹlẹgb okunkun ni - Pentecostal Fellowship of Nigeria

PFN

Oríṣun àwòrán, PFN

Lasiko ti ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, Pentecostal Fellowship of Nigeria dahun si ija laarin TB Joshua ati Chris Okotie, ni wọn sọ wi pe TB Joshua kii ṣe ara awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria.

Bisọọbu Mike Okonkwo, to jẹ adari ẹgbẹ Pentecostal Fellowship of Nigeria nigba naa ni TB Joshua kan n farapẹ awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria ni, kii ṣe ara wọn rara.

O wa kilọ fun un pe ko ma pe ara rẹ ni ara ijọ Pentecostal lorilẹede Naijiria.

TB Joshua

Oríṣun àwòrán, Others

Ninu ọrọ tirẹ, Pasitọ ijọ Revival Assembly Church ni ipinlẹ Eko, Anselm Modubuku ni ko si otitọ ninu ọrọ ti TB Joshua sọ wi pe ati inu iya oun ni oun ti di atunbi, ti o si ti ṣi ọpọlọpọ onigbagbọ ni ọna iye.

Bakan naa ni pasitọ ijọ Word of Life Bible Church, Ayo Oritsejafor ni ilu Warri ni oun ko mọ oun ti awọn ara ilẹ Amẹrika ri lara TB Joshua, ti wọn fi n wọ tẹle nitori oun tikararẹ ko ni ẹni to mọ igba to fi aye rẹ fun Jesu, tabi ta ni pasitọ rẹ.

Eniyan Ọlọrun ni TB Joshua, kii ṣe eniyan lasan - Ọmọ Ijọ T.B Joshua

T.B Joshua death

Oríṣun àwòrán, fACEBOOK/T.B Joshua death

Ara ijọ Synagogue Church of All Nations, to ti tun jẹ ọrẹ timọ timọ si TB Joshua, Oye Ogunwale ni ahesọ ni gbogbo ọrọ ti awọn eniyan miran n sọ nipa rẹ, paapaa awọn pasitọ ni Naijiria.

Ogunwale ni eniyan Ọlọrun ni TB Joshua, ti ko si ni ohun ikọkọ tabi agbara okunkun kankan nitori oun ti mọ lati bi ọdun mẹwaa ṣẹyin.

O ni awọn to n sọrọ rẹ ni aida ni awọn ti ko ri iwosan gba nigba ti wọn lọ si ile ijọsin rẹ, amọ o fi n da awọn eniyan loju wi pe o kere tan, TB Joshua n wo awọn alaisan HIV/Aids bii mẹwaa san ni ọṣẹ kan.

Àkọlé fídíò, Snail Slim Soap: Wo ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú lílo ọ̀ṣẹ tí wọn fi omi ìgbín ṣe láti fọ ojú?

Ogunwale ni o ṣe ni laanu wi pe ọrọ TB Joshua dabi ti oloye Obafemi Awolowo, to jẹ wi pe lẹyin iku rẹ ni awọn eniyan ṣẹṣẹ rii gẹgẹ bi olori to dara.

O ni igbagbọ ni wọn fi n ri iwosan gba ni ọdọ TB Joshua, amọ ẹni ti ko ba ri idariji gba lati ọdọ Ọlọrun, ko le e ri iwosan gba lọdọ rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ, awọn miran fi ẹsun kan TB Joshua wi pe, ẹmi okunkun lo fi n ṣe iwosan fun awọn eniyan nitori ti wọn ba ri iwosan gba lẹṣẹkẹṣẹ, aisan naa yoo tun pada pa eniyan bẹẹ ni, laipẹ si ara wọn.