TB Joshua: Apostle Paul M.E ti kéde ikú àgbà wòlíì náà láti oṣù kan sẹ́yìn

Oríṣun àwòrán, TB Joshua Ministries
Gẹgẹ bi awọn alasẹ ijọ Synagogue Church of All Nations (SCOAN) se sọ lasiko ti wọn n kede iku oludasilẹ ijọ naa, Wolii TB Joshua, bẹẹ ni ọrọ iku rẹ ri.
Ijọ naa lo kede ni owurọ ọjọ Aiku pe Ọlọrun kii se nnkan, ko ma kọkọ fi han awọn wolii rẹ saaju.
Bakan naa ni ọrọ ri pẹlu Wolii kan, to ti kọkọ sọ asọtẹlẹ ni osu kan sẹyin pe Ọlarun ti setan lati mu Wolii Temitope Balogun Joshua lọ sile ayeraye.
- Dandan ni kí wọ́n ó sin òkú Joshua sí ìlú abínibí rẹ̀ - Zaki ìlú Arigidi-Akoko
- Ẹ wo àwọn Pásítọ̀ jàǹkàn-jànkàn tí ikú wọn tí mí orílẹ̀èdè Naijiria
- Ìdí rèé tí ń kò fi ní ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí mi ní June 12 - TB Joshua sàsọtẹ́lẹ̀
- Ìtàn ayé TB Joshua tó lo ọdún kan àti oṣù mẹ́ta nínú ìyà rẹ̀
- Wòlíì TB Joshua sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ lọ́jọ́ Satide tó kú - Ìjọ SCOAN
- Gbajúmọ̀ òjíṣẹ́ Ọlọ́run míràn tún jáde láyé tẹ̀lé TB Joshua
- Wo ojú táwọn Pásítọ̀ fi wo T.B Joshua nígbà ayé rẹ̀, tó fa awuyewuye
Ninu fidio kan to gba awọn oju opo ayelujara kan, ni ojisẹ Ọlọrun kan Apostle M.E Paul ti n sasọtẹlẹ pe oun ri awọn angẹli, ti wọn wa gbe wolii TB Joshua lọ kuro laye.
"Ọlọrun fi iran igba ikẹyin kan han mi, ẹ tẹti si mi, mo duro silẹ, a si gbe mi lọ si ọrun, ferese ọrun si silẹ fun mi, mo si duro lati boju wo isalẹ ilẹ nile aye.

Oríṣun àwòrán, Paul M.E Ministries
Mo ri awọn angẹli mẹfa ti a ran lati ọrun wa sile aye pe ki wọn lọ gbe wolii Joshua wa, ohun ti mo ri ni mo n sọ.
Awọn angẹli mẹta mu dani ni ọwọ ọtun ati mẹta ni ọwọ osi, ti wọn gbe wolii TB Joshua soke tente, to si mu ife ẹyẹ kan dani."
Wolii Paul ni oun wo ibi ti awọn wolii naa duro si, ti wọn si ya si apa ọtun, oun naa ba woju wo apa ọtun, amọ oun ko ri oju ẹni to joko sori itẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìkọlù Igangan tọ́ka si pé ogun ń bọ̀ ní Nàíjíríà láìpẹ́ - Gani Adams
- Ìpànìyàn ní Igangan ń tọ́ Yorùbá níjà, Amotekun alájùmọ̀ṣe ní yóò yanjú rẹ̀ - Akeredolu
- Ẹ̀rú Fulani ni Aregbesola, ara sì ló ń ta á torí àṣeyọrí ìjìjàgbara Yoruba nation - Ilana Omo Oodua
- Gbajúmọ̀ òjíṣẹ́ Ọlọ́run míràn tún jáde láyé tẹ̀lé TB Joshua
- Ẹ wo àwọn Pásítọ̀ jàǹkàn-jànkàn tí ikú wọn tí mí orílẹ̀èdè Naijiria
- Wo ojú táwọn Pásítọ̀ fi wo T.B Joshua nígbà ayé rẹ̀, tó fa awuyewuye
- Ẹ̀mí mẹ́sàn-án tún ṣòfò ní Igangan, agbébọn jo ilè, ọkọ àti ààfin Ọba
- Ìjọba, ẹ bá mi wá ẹni tó pa ọmọ mi jáde - Ẹ̀bí olóògbé gbarata
Bakan naa ni Apostle M.E Paul ni oun gbọ ohun Ọlọrun to n sọ fawọn angẹli naa pe ki wọn gba ife ẹyẹ naa lọwọ Wolii Joshua, ki wọn si mu wa fun oun.
Bakan naa lo ni ki wọn mu wolii naa lọ sibi to yẹ fun.
"Lọgan ni mo ri awọn agba angẹli to tun ju awọn ti isaaju lọ, ti wọn n duro sẹba itẹ Ọlọrun, wsn wa gba ife ẹyẹ naa lọwọ wolii TB Joshua, ti wọn si gbe lọ siwaju itẹ Ọlọrun.
O ni Oluwa ni ki awọn angẹli yii si gbe wolii si ibi to yẹ ko wa nitori o ti pari ire ije rẹ nile aye.



















