TB Joshua: Ìjọ COAN ní wòlíì ṣèpàdé lọ́jọ́ Sátidé, kó tó kú lọ́jọ́ náà

Wolii TB Joshua

Oríṣun àwòrán, TB Joshua Ministries/Facebook

Ileesẹ iransẹ TB Joshua ti kede pe oludasilẹ ijọ naa ati agba wolii lorilẹede Naijiria, Temitope Balogun Joshua ti dagbere faye.

Gẹgẹ bi ikede kan ti ileesẹ iransẹ naa ati ijọ Church Of ALl Nations fisita loju opo Facebook rẹ, ana ọjọ Satide, ọjọ karun osu Kẹfa ọdun 2021 ni agba wolii naa mi kanlẹ.

Wolii Joshua, to dele aye ni ọjọ Kejila osu Kẹfa ọdun 1963, lo lo ọdun mejidinlọgọta loke eepẹ, ki ọlọjọ to de.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ikede naa fidi rẹ mulẹ pe Ọlọrun kii se ohunkohun lai fi iran rẹ han awọn wolii rẹ saaju, to si tọkasi iwe mimọ Amosi, ori kẹta ẹsẹ keje.

Gẹgẹ bi ikede ijọ naa ti wi, Wolii Joshua sọrọ lọjọ Satide lasiko ipade to se pẹlu awọn alabasisẹpọ rẹ fun ileesẹ mohunmaworan ijọ rẹ, Emmanuel TV, to si dabi ẹnipe o n sọ asọtẹlẹ nipa iku rẹ.

Ikede iku wolii TB Joshua

Oríṣun àwòrán, TB Joshua Ministries/Facebook

"Ohun gbogbo ni akoko wa fun, akoko lati wa fun ipade adura wa, akoko lati pade sile lẹyin isin naa si wa pẹlu."

Ijọ naa ni o wu Ọlọrun lo mu iransẹ rẹ sọdọ, ifẹ rẹ si ni iku iransẹ rẹ naa jẹ, Wolii si lo akoko igbẹyin rẹ lati sisẹ sin Ọlọrun, ohun ti wọn bi saye fun ree, to gbe ile aye se, to si ku fun.

"Wolii fi ogun isisẹ sin ati ifaraẹnijin fun ijọba Ọlọrun silẹ fun iran to n bọ, a si mọ riri adura yin ni akoko yii."

Àkọlé fídíò, Snail Slim Soap: Wo ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú lílo ọ̀ṣẹ tí wọn fi omi ìgbín ṣe láti fọ ojú?

Ikede naa ni ọrọ ti wolii TB Joshua sọ kẹyin to fi mi kanlẹ ni pe "ẹ maa sọna, ẹ si maa gbadura."