VPN, FG suspends Twitter: Pásítọ̀ Enoch Adeboye sọ̀rọ̀ lórí bí ìjọba ṣe gbégilé ojú òpó Twitter

Adeboye

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Olori ijọ Redeem lagbaye, Pasitọ Enoch Adeboye ti sọrọ lori aṣẹ ijọba apapọ to gbegile oju opo Twitter ni Naijiria ati igbeṣẹ wọn lati fi iya jẹ ẹnikẹni to ba tapa si ofin naa.

Pasitọ Adeboye ni kii ṣe orilẹede Naijiria nikan ni ẹka ile ijọsin oun wa, nitori naa ijọba ko le e da awọn duro lati maṣe lo oju opo Twitter.

Ọrọ yii ko ṣẹyin ẹsun ti wọn fi kan Baba Adeboye wi pe oun tẹ oju ofin Naijiria mọlẹ nipa lilo oju opo Twitter lẹyin ti wọn gbegile ni Naijiria.

O ni lilo Twitter tẹlẹ ofin Aj Iṣọkan Agbaye, UN to fun awọn ọmọ eniyan laṣẹ lati fi ohun wọn lede ni gbogbo igba.

Bakan naa ni Baba Adeboye fihan pe awọn ni ẹgbẹgbẹrun miliọnu eniyan lagbaye ti wọn n tẹle wọn ni oju opo ikansiraẹni Twitter.

''Ijọ Redeemed Christian Church of God wa ni orilẹede aadọsan ni agbaye, ti lilo oju opo Twitter wa si tẹle aṣẹ Ajọ Iṣọkan Agbaye ni Article 19 ti UN universal declaration of Human Rights."

Minisita fun eto iroyin ni Naijiria , Lai Mohammed lo kede pe awọn ti fofin de oju opo ikansiraẹni Twitter ni Naijiria.

Adeboye

Oríṣun àwòrán, Twitter/Adeboye

Lai Mohammed ni ijọba ti paṣẹ fun ileeṣẹ ijọba to n sakoso eto iroyin ni Naijiria,NBC lati fofin de awọn oju opo kọọkan ni Naijiria.

Lati igba ti ijọba ti ti oju opo naa, ni ẹgbẹgbẹrun miliọnu ọmọ Naijiria ko ti laṣẹ si oju opo ikansiraẹni Twitter naa, ti wọn si n wa ọna miran lati le lo oju opo naa.

Ẹsun ti ijọba apapọ fi kan Twitter ni pe wọn n fari apa kan da ikan si pẹlu bi wọn ṣe yọ 'ọrọ ti aarẹ Buhari kọ si oju opo rẹ nitori o sọ wi pe awọn kan n kọ lẹta si ogun ni Naijiria.

Ìjọba àpapọ̀ kéde ìjìyà fún àwọn tó ṣì n lo Twitter ní Naijiria

Agbẹjọro Agba ni Naijiria to tun jẹ minisita fun eto idajọ, Abubakar Malami ti paṣẹ pe ki wọn o fi oju gbogbo awọn to ṣi n lo ayelujara ibaraẹnidọrẹ Twitter wina ofin.

Ọjọ Ẹti ni ijọba Naijiria kede pe oun ti fi ofin de Twitter ni Naijiria nitori pe awọn ọmọ Naijiria n lo o lati ma tako ijọba.

Eyi waye lẹyin ti awọn alaṣẹ Twitter, to jẹ ileeṣẹ ilẹ America, pa ọrọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari sọ nipa ogun Biafra to waye lọdun 1967.

Ami idanimọ Twitter ati Malami

Oríṣun àwòrán, others

Ninu atẹjade kan to tẹ BBC lọwọ, Malami paṣẹ fun Oludari ẹka to n gbe ọdaran lọ sile ẹjọ ni ileeṣẹ eto idajọ ti ijọba apapọ, lati bẹrẹ isẹ ni kiakia lori fifi ofin mu awọn to tako aṣẹ ijọba lori lilo Twitter ni Naijiria.

Ikede ifiyajẹni yii waye nitori bi awọn eeyan kan ṣi ṣe n lo Twitter pẹlu imọ ẹrọ ayelujara Virtual Private Network

Malami ni ki ẹka naa ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ to n mojuto ibaraẹnisọrọ, National Communication Commission, ileeṣẹ ijọba apapọ fun ibaraẹnisọrọ ati okoowo ori ayelujara, ati awọn ajọ mii lati ri pe wọn tete gbe awsn arufin lọ si ile ẹjọ.

Mọ̀ síi nípa VPN àti bí o ṣe lé lò ó láìsí ewu

Ki wa ni VPN?

VPN tumọ si virtual private network ti awọn to n lo ayelujara nilo lati lo yatọ si ti gbogboogbo ti wọn n pe ni public internet connection.

Gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ Kehinde Akinseli ṣe ṣalaye fun BBC, O ni laisi VPN ko si be eeyan ṣe tun fẹ wọn Twitter lai lo awọn ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ bii MTN, Etisalat, GLo ati awọn to ku.

O ni eyi tumọ si pe awọn eeyan Naijiria to n lo Twitter yoo dinku jọjọ.

Àkọlé fídíò, Magaret Jimoh: Èrè díẹ̀ ti tó mi níbi oúnjẹ ti mò ń tà- Maggie Rice

Bawo lo ṣe le ri VPN gba?

Akinseli Kehinde Kayode ṣalaye pe VPN yii ni yoo fun ọ laaye lati le de ori Twitter lati orilẹ-ede mii.

O ni eyi tun tumọ si pe ero Naijria ko ni pọ mọ lori Twitter.

O mẹnuba ewu ki awọn eeyan maa ja wọ inu ibi ifipamọ ẹni ninu lilo VPN ẹlomii.

Àkọlé fídíò, Adebayo Shittu: Èmi kò ṣẹ Abiola Ajimobi nígbà ayé ẹ, òun ló ṣe mi ṣùgbọ́n.....

Kehinde ni VPN da bii IP ti a jijọ n ṣapinlo ni ti ko wa fun ẹnikan ṣoṣo.

Ati pe nipa lilo VPN, oṣeeṣe ki awọn eeyan mii maa mọ ohun ti o n ṣe lori ẹrọ ayelujara rẹ.

Ati pe o rọrun ki awọn eeyan maa ṣe ẹ̀dà ohun ti o n ṣe lọwọlọwọ.

Lai Mohammed

Oríṣun àwòrán, Lai Mohammed

Ìjọba àpapọ̀ dá iléeṣẹ́ Twitter dúró lórílẹ̀èdè Nàìjíríà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀!

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti paṣẹ dida ileeṣẹ oju opo ikansiraẹni ayelujara Twitter duro ni Naijiria.

Minisita to n ri si iroyin ati aṣa, Lai Mohammed lo kede rẹ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Ẹti niluu Abuja.

Lai Mohammed ṣe apejuwe bi wọn ṣe n lo oju opo ikansiraẹni naa fun awọn ilo to lee da ibagbepọ alafia orilẹede Naijiria jẹ.

Bi ẹ ko ba gbagbe, l'Ọjọbọ ọsẹ yii kan naa ni ileeṣẹ Twitter yọ ọrọ ti aarẹ Buhari sọ to jọ mọ didunkoko mọ awọn ọmọ Naijria lori ọrọ abo kuro loju opo naa.

Amọ lọgan ni ijọba naa fesi ti wọn si fi ẹsun kan pe alagabagebe ni ileeṣẹ Twitter pẹ̀lú oniruuru apẹrẹ ọrọ ti ijọba wu jade.

Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa bí 'twitter' tíjọba dá dúró ní Nàijíríà yóò ṣe kan ọ

Saaju ni ijọba Naijiria ti da ileeṣẹ Twitter duro ni Naijiria lẹyin to yọ 'Tweet' Aarẹ Buhari kuro Ìdí rèé tí Twitter kò fi le gbé ìdájọ́ Trump lé Ààrẹ Buhari

Lẹyin naa ni ọpọ ọmọ Naijiria n woye pe ki lo n ṣẹlẹ bayii ti ero wọn si ṣotọọtọ Twitter kò dá sí ọ̀rọ̀ IPOB àti Nnamdi Kanu, bó ṣe wù wa la ṣe lè darí Nàìjíríà- Lai Mohammed

Bawo wa ni idaduro Twitter yii ṣe kan iwọ funra re?

Eyi lo mu ki BBC kan si akọṣẹmọṣẹ nipa lilo ẹro ayelujara, Akinseli Kehinde lori ohun ti yoo ṣẹlẹ bi ijọba Naijiria ṣe fofin de Twitter yii.

O ni ọna kan ṣoṣo ti erongba ijọba fi le wa si imuṣẹ lori ofin yii ni pe ki ijọba paṣẹ fun awọn Internet Service Providers to wa ni Naijiria lati yọ IP Address to n wa lati Naijiria lọ si oju òpó Twitter.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí

O ni eyi tumọ si pe ileeṣẹ bii MTN, GLO, Etisalat ati awọn to ku ko ni jẹ ki awon eniyan Naijiria de oju opo Twitter nipase ileeṣẹ erọ ibanisọro ti wọn mọ.

Akinseli ni eyi ja si pe MTN, GLO, Etisalat ati awon to ku ko ni jẹ ki awọn eniyan Naijiria le de oju opo Twitter lati ọdọ ti wọn bi o ṣe yẹ.

Akosemọṣẹ yii tun salaye pe ọna kan ṣoṣo miran ti eeyan tun fi le de oju opo Twitter ti ko ba lọ nipasẹ ISP ni nipa lilo VPN.

Foonu

Oríṣun àwòrán, Seyllou

Àkọlé fídíò, Adebayo Shittu: Èmi kò ṣẹ Abiola Ajimobi nígbà ayé ẹ, òun ló ṣe mi ṣùgbọ́n.....

Bakan naa, minisita ti paṣẹ pe ki ajọ to n bojuto igbohunsafẹfẹ ni Naijiria ki wọn bẹrẹ si ni fun awọn alagbata itakun ayelujara laṣẹ lati ṣiṣẹ.

Ẹwẹ, awọn Naijiria o jẹ ko balẹ tabi tutu rara ti wọn ti n fun ijọba apapọ lesi.

Ọpọlọpọ eeyan lo ni "Ẹ da ileeṣẹ Twitter duro, Twitter ọhun naa si lẹ lo lati fi ọrọ yii sita.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ni ti Usman @UIncorp, adura lo gbe ṣe fun aarẹ Buhari, Lai Mohammed ati orilẹede Naijiria lapapọ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Agada Stephen Michael @agadastephenmic ni Twitter kan naa ti wọn fi yi irọ mọ aarẹ ana, Goodluck Jonathan naa ni wọn tun wa ni o ni ero ibi si Naijiria.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Ẹwẹ, ko tii si ẹni to lee fi aridaju ohun ti itumọ igbesẹ yii jẹ gangan sitta. Ninu iwoye, wọn lee gbe igi di oju opo Twitter lori adirẹsi itakun agbaye Naijiria eyi to tumọ si pe oo nilo VPN koo to le lọ soju opo Twitter ṣugbọn ko sẹni to tii sọ eyi.

Laipẹ yii naa ni Twitter gbe olu ileeṣẹ wọn ni Afirika lọ si orilẹede Ghana.

Àkọlé fídíò, King Sunny Ade's son: Ohùn orin bàbá mi nìkan kọ ni l’Ọlọrun fún mi, ijó bíi kòkòrò ni ṣáá